Ṣé lóòótọ́ ni ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ti yan Awujale tuntun pẹ̀lú Ifa?

AworanAwujalẹ ana, Ọba Sikiri Adetọna.

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Olori ile ọba Fusengbuwa nilu Ijẹbu Ode, ni ipinlẹ Ogun, AbdulateefOwoyẹmi ti rawọ ẹbẹ si gomina Dapọ Abiọdun lati gbẹsẹ kuro lori igbesẹ yiyan ọba Awujalẹ tuntun, ki awọ̀n afọbajẹ le pari iṣẹ wọn.

Oloye Owoyẹmi to rawọ̀ ẹbẹ yii lọjọ Aiku ṣalaye pe ọrọ naa ti fẹ ṣebi ẹni su awọn idile Fusengbuwa atawọn ọmọbibi ilẹ Ijẹbu nile loko, pẹlu bi ijọba ṣe gbẹsẹ le igbesẹ yiyan Awujalẹ tuntun lai dajọ si igba ti yoo bẹrẹ pada.

Ninu ọrọ to ba akọroyin iwe iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria sọ, Owoyẹmi ni lootọ gomina ipinlẹ naa, Dapọ Abiọdun n fi atilẹyin rẹ han, ṣugbọn ko yẹ ki idiwọ kankan wa fun yiyan Awujalẹ tuntun.

"Inu idile ọba atawọn ọmọbibi ilẹ Ijẹbu lọkunrin ati lobinrin yoo dun bi ijọba ba le jawọ ninu awọn idiwọ wọnyii."

Loṣu to kọja ni ijọba ipinlẹ Ogun ti gbẹsẹle ilana yiyan Awujalẹ tuntun nigba ti Kmiṣọna fun ọrọ oye jijẹ, Ganiyu Hamzat gbe atẹjade kan sita to ti ṣalaye pe ijọba ni lati gbẹsẹ le ilana naa nitori omilẹngbẹ iwe ifisun to waye lori rẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Bakan naa, lopin ọsẹ to kọja ni ijọba tun ni lati pana iroyin awuyewuye pe ijọba ti buwọlu orukọ Ademọrin Aliu Kuyẹ gẹgẹbi Awujalẹ tuntun.

Hamzat ṣalaye ninu atẹjade kan pe irọ nla leyi o, nitori pe ijọba ipinlẹ Ogun ṣi gbẹsẹ le ilana yiyan awujalẹ tuntun.

Kọmiṣọna naa ṣalaye pe pe oun ko lọwọ ninu iroyin yii tabi yan ẹnikẹni fun ipo ọba Awujalẹ.

O ni ilana ofin lo n sọ bi yiyan Awujalẹ yoo ṣe lọ si.

"Ẹnikẹni to ba n sọ kiri pe ijọba ti buwọlu ẹnikẹni nipasẹ Ifa tabi ilana kankan n pa irọ lasan ni, ki araalu si keti ọgbọin si iroyin bẹẹ."

Loṣu keje ọdun 2025 ni Awujalẹ ana, Ọba Sikiru Adetọna waja lẹyin to lo ọdun marundinlaadọrin lori apere awọn baba rẹ. Lati igba naa ni igbesẹ ati yan Awujalẹ tuntun ti n fa oniruuru awuyewuye.