Àwọn agbébọn ṣekúpa ó lé ní èèyàn 50, jí ọ̀pọ̀ obìnrin àti ọmọdé gbé lọ ni Zamafara

Aworan awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ isọkan ile Afrika ti koroju si ikọlu awọn agbebọn miiran ni apa ariwa orilẹede Naijiria, nipinlẹ Zamfara, nibi ti o le ni eeyan aadọta to padanu ẹmi wọn, ti wọn si tun ji ọpọ obinrin ati ọmọde gbe lọ.

Ninu atẹjade to jade sita lọjọ Aiku, alaga ajọ AU, Mahmoud Ali Youssouf, ni ikọlu yii jẹ eyi to tapa si ofin ẹtọ ọmọniyan, to si tun dunkoko mọ alaafia ni agbegbe naa.

Ikọlu naa waye ni ilu Dutsin Dan Ajiya ni ijọba ibilẹ Anka, to si jẹ pe irọlẹ ni awọn agbebọn naa yawọ ilu pẹlu ọkada to le ni ọgọrun, ti wọn si gbegi dena ọna ti awọn araalu le gba ṣalọ, ki wọn si sina bolẹ.

Ọpọ eeyan lo padanu ẹmi wọn lasiko ti wọn n gbiyanju lati ṣalọ, ti wọn si tun dana sun ile kaakiri ninu ilu naa.

Ileeṣẹ iroyin abẹle sọ pe awọn agbebọn yii wa ni ilu naa fun ọpọ wakati, bẹrẹ lati irọlẹ ọjọbọ wọ owurọ ọjọ Ẹti.

Awọn araalu ni awọn kesi awọn ẹsọ alabo lasiko ti awọn kẹfin awọn agbebọn naa ṣugbọn iranlọwọ kankan lo pada wa.

Ninu atẹjade AU, ajọ naa ni gbogbo iwa igbesunami pata lo n ṣekupa eeyan, paapa awọn obinrin ati ọmọde ,"

Youssouf ni ajọ naa duro digbi pẹlu ijọba orilẹede Naijiria ati awọn araalu, to si ransẹ ibanikẹdun si awọn idile ti ijamba naa ṣẹlẹ si.

Bakan naa lo pe fun itusilẹ awọn to wa ni igbekun awọn agbebọn ni kiakia to si rọ ijọba lati wa ọna ti yoo pese aabo fun araalu.

Ijọba orilẹede Naijiria ko ti sọ ohunkohun nipa ikọlu naa.

Zamfara jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ ni apa ariwa ti awọn agbebọn ti n kọlu awọn eeyan, ti wọn si tun jẹ ile fun awọn janduku.

Ọpọ igba ni awọn agbebọn yii ti kọlu ilu, ji dukia awọn araalu, dana sun ile wọn, ti wọn si tun ji ọpọ gbe lati fi gba owo.