Obìnrin tó gbàgbé ajá rẹ̀ sí pápákọ̀ òfúrufú fojú balé éjọ́

Oríṣun àwòrán, Las Vegas Metropolitan Police Department
Obinrin kan ti dero ile ẹjọ lori ẹsun "ikọsilẹ ẹranko" lẹyin to gbagbe aja rẹ si papakọ ofurufu kan nilẹ Amẹrika.
Ọlọpaa ni awọn ri aja ọmọ ọdun meji naa ti wọn so mọ baagi ni papakọ ofurufu Harry Reid to wa niluu Las Vegas.
Wọn ni awọn gbe aja ọhun lọ si ọọfisi ajọ kan to n daabo bo ẹranko, amọ ajọ naaa ni yoo maa tọju rẹ bayii lẹyin ti oluwa rẹ ko yọju.
Ajọ ti aja naa wa lọdọ rẹ bayii sọ pe oniruru eeyan lo ti n kọwe pe awọn fẹ lati gba aja naa lati maa tọju.
Awọn alaṣe ti fun aja naa ni orukọ tuntun "Jet Blue".
Fidio iṣẹlẹ naa ṣafihan bi afurasi ọhun ti wọn ko darukọ rẹ ṣe lọ sibi ti awọn arinrinajo ti n ra tikẹẹti ni papakọ ofurufu ti ko si mu aja naa dani lasiko to n fi ibẹ silẹ.
Ṣaaju ko to fi aja ọhun silẹ ni oṣiṣẹ papakọ ofurufu sọ fun pe ko ni awọn iwe ẹri to yẹ lati rinrinajo pẹlu aja naa, eyii to mu ki wọn sọ pe ko ni le fo pẹlu rẹ.
Lẹyin to fi aja naa silẹ lo gbiyanju lati ba tirẹ lọ amọ agbofinro papakọ ofurufu da duro.
Ileeṣẹ ọlọpaa Las Vegas sọ ninu atẹjade kan pe "Nigba ti wọn bere lọwoọ rẹ eredi to ṣe fi aja rẹ siẹ, o ṣalaye pe ileeṣẹ ọkọ ofurufu ko gba oun laaye lati rinrinajo pẹlu rẹ, o tun sọ pe aja naa ni ẹrọ ti oun le fi mọ ibi to wa ni gbogbo igba – eyii to n tumọ si pe oun le fi silẹ ni ibikibi to ba wu oun."
Wọn ni obinrin naa tun ba awọn ọlọpaa ṣe agidi lasiko ti wọn n gbiyanju lati fi ṣikun ofin mu.
Yatọ si pe yoo jẹjọ lori fifi aja rẹ silẹ lai bikita, yoo tun jẹjọ pe o ba ọlọpaa lo agidi nigba ti wọn fẹ mu.
Ileeṣẹ naa ti wa ke si awọn araalu ki wọn ma fi aja wọn silẹ ni papakọ ofurufu tabi awọn ibomii lai tọju rẹ.

























