Kollington Ayinla sọ ẹni tó dá orin Fuji sílẹ̀ gan an ní Nàiìjíríà

Oríṣun àwòrán, @AyindeBarrister/X
Agbaọjẹ olorin Fuji ni Naijiria, Alhaji Kollington Ayinla tun ti yanna na bi orin Fuji ṣe bẹrẹ lorilẹede Naijiria.
Ọpọ awuyewuye lo ti wa lori ẹni ti o bẹrẹ orin Fuji ni Naijira laarin oloogbe Sikiru Ayinde barrister ati Alhaji Kollington, Kebe n Kwara.
Amọ, Kollington fun ra rẹ naa ti fi kọ orin pe ''Edumare fiṣẹ yin wa gbogbo wa, lagbaja lo da Fuji silẹ, ọrọ awawi, tamẹdo lo da Fuji silẹ, Edumare fiṣẹ yin wa gbogbo wa.''
Alhaji Ayinla Kollington to je agba oje olorin Fuji tu kẹkẹ ọrọ silẹ nigba ti BBC Yoruba ṣe iforowanilenuwo fun un.
Baba kebe n kwara dahun ibeere nla to n fa ariyanjiyan lagboole Fuji lori eni to da ere Fuji sile.
O ni ere Fuji ti wa saaju ki oun ati Ayinde Barrister to bere orin kiko rara.
O ni oro apara lasan ni pe oun tabi Barrister ni awon jo da fuji sile.
Baba Alatika be gbogbo olorin Fuji lati jebure ki won fowo wonu.
O fi Olorun ati Anobi Muhomo be gbogbo olorin fuji ti won je kikida musulumi pe ki won dupe ti won.
Aajo aje ni eebu ti emi ati oloogbe Ayinde Barrister fi n bu ara ninu ariyanjiyan wa ninu orin fuji.
Koda aw'on Baba nla wa ninu ise orin gan an korin bu ara won ki onikaluku le ta oja tire.
Kollington ni ko le se ki ija ma wa laarin awon eniyan laye.
O gba imoran pe ti ija ba ti de ki onikaluku pari e ni alaafia fi le joba ni ile aye.
Kollington ṣalaye pe oun ko lero pe orin Fuji le di gbajugbaja orin bi o ti da lonii.
''Orin gidi ni orin Fuji, o ti kan kaakiri gbogbo agbaaye bayii, gbogbo eeyan ni Naijiria lo fẹ kọ orin Fuji bayii,'' Kollington lo sọ bẹẹ.
Alhaji Kollington fikun ọrọ rẹ pe ijinlẹ ede Yoruba lawọn maa n fi kọ orin Fuji ṣugbọn laye ode oni ''awọn ọmọ wa ti fi ede oyinbo si orin Fuji lati le jẹ ko jẹ itẹwọgba sii kaakiri agbaaye.


























