Àwọn Oníṣẹ̀ṣe ní kí INEC sún ọjọ́ ìdìbò Gómìnà Osun síwájú

Aworan aarẹ ẹgbẹ awọn oniṣeeṣe, Dokita Oluseyi Atanda

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

‎Awọn ẹlẹṣin ibilẹ ẹka ti ipinlẹ Ọṣun ti ke si ajọ eleto idibo INEC lati sun ọjọ idibo sipo gomina ipinlẹ Ọṣun siwaju.

‎Ninu atẹjade kan ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Dokita Oluṣeyi Atanda fi lede lo ti sọ pe, ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii, ti ajọ INEC mu fun ọjọ idibo si ipo gomina lo jẹ ọsẹ fun ọdun ọsun Osogbo.

‎Dokita Oluseyi tẹsiwaju pe, ọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Keje si ọjọ Keje oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni ayẹyẹ ọdun Ọṣun Oṣogbo, o si maa n to aago mẹfa asalẹ ki ayẹyẹ ọdun naa to pari lọjọ ti idibo yoo ku ọla.

‎O fikun pe, " ko ṣe e ṣe lati sun ayẹyẹ ọdun ọsun Oṣogbo fun ọjọ idibo rara. Nitori jimọ keji osu Kẹjọ ọdọọdun ni asekagba ọdun ọsun Osogbo.

"Ti ẹnikeni ba sun ọjọ ọsun Osogbo sẹyin tabi siwaju, ọ le mu ohun ti agbara ko ni ka wa. Nitori meji ti wọn ti ṣe bẹẹ ri, atubọtan rẹ ko da o si lagbara gidigidi lasiko igba naa."

‎Aarẹ ẹgbẹ naa sọ pe, àjọ eleto idibo INEC ki wọn kiesi awọn wahala ti o le mu wa ti wọn ba dibo ni akoko igba ọdun ọsun Osogbo.

‎O ni awọn janduku le lo anfaani awọn ero to maa n wa sibi ayẹyẹ ọdun naa lati da wahala silẹ saaju ọjọ idibo sipo gomina, eleyi si lewu pupọ.

‎Aarẹ Oluseyi, wa rọ ajọ eleto idibo INEC lati gba ọrọ naa ro, ki wọn si sun idibo naa siwaju

Lọdun to kọja ni alaga INEC tẹlẹ, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu kede pe ogunjọ, oṣu Kẹfa ati ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni eto idibo ipinlẹ Ekiti ati Osun yoo waye.