Àwọn alákatakítí ẹ̀sìn kọlu ọjà tòmátò, ṣekúpa ọmọ Ghana méje

Ọja tomato

Oríṣun àwòrán, getty inages

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Minisita fun ọrọ abẹle ni Ghana, Mohammed Muntaka Mubarak ti fidi rẹ mulẹ pe awọn alakakiti ẹsin Islam ti sekupa awọn ọmọ Ghana ti wọn jẹ oniṣowo tomato meje ni Burkina Faso.

Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji yii ni awọn agbesunmọmi naa kọlu agbegbe kan ti awọn ologun wa nibi ti wọn ti ṣina ibọn bolẹ fun awọn ologun atawọn araalu.

Lati ọdun 2019 lawọn agbebọn naa ti n kọlu agbegbe Titao ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Ọpọ igba lawọn alakiti ẹsin naa ti orukọ wọn n jẹ Jama'a Nusrat ul-Islam wa-al-Muslim (JNIM) maa n sọ pe awọn lo wa nidi oniruru ikọlu.

Mohammed Muntaka Mubarak sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle Joy FM pe awọn ọdaran ọhun ko awọn oniṣowo naa ninu ọkọ wọn, ya awọn ọkunrin sọtọ kuro lara awọn obinrin ti wọn si bẹrẹ si n yinbọn lu wọn.

O fi kun pe "meje ninu awọn oniṣowo naa ni ara wọn ti jo kọja idamọ, eeyan mẹta mii farapa nigba ti obinrin kan wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun."

Alaga ẹgbẹ awọn oniṣowo ọhun, Eric Tuffour sọ pe ọpọ igba lawọn ọmọ ẹgbẹ oun maa n koju ikọlu agbebọn ti wọn ba fẹ lọ ra tomato ati alubọsa, amọ ikọlu yii le kenka.

O ṣalaye pe awakọ to wa wọn ti ara rẹ mọ inu ọkọ akẹru ti wọn wa amọ awọn agbesunmọmi naa dana sun ọkọ pẹlu awọn eeyan to wa ninu rẹ.

Muntaka Mubarak ni ijọba Burkina Faso ti n ṣiṣẹ takuntakn lati gba agbee ọhun pada lọwọ awọn alakakiti ẹsin naa.

O ni "Awọn alaṣẹ Burkina Faso ti sọ fun wa pe ti wọn ba ti sin oku awọn to ba iṣelẹ naa lọ tan, ileeṣẹ ọmọ ogun yoo daabo bo awọn obinrin yoku ki wọn le pada wale."

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ijọba Burkina Faso ko tii sọ nnkankan lori iṣẹlẹ naa amọ ẹgbẹ awọn to n ta tomato ni Ghana sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyii to ya agbado sẹnu awọn.

Ẹgbẹ ọhun sọ pe ti wọn ba ti mọ awọn eeyan pato ti ọrọ naa kan lawọn yoo to mọ igbesẹ to kan fun wọn lati gbe lori rẹ.

oko ati awọn nkan to n jona

Oríṣun àwòrán, "olympia de

Ogbeni Eric Tuffour salaye pe ṣeni awọn agbesunmọmi yii dana sun ọkunrin mẹsan an pẹlu awakọ ati obinrin mẹjọ nigba ti awa kọ naa ko tete ṣilẹkun ọkọ fun wọn.

Minista Ghana naa sọ pe ọpọ awọn eeyan ni wọn joan kọja didamọ yatọ si awọn ti wọn farapa ti wọn ṣi n gba itọju.