"Àwa òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ Rufus Giwa nìkan ni òṣìsẹ́ tó ṣì n gba ₦18,000 owó oṣù ní Naijiria"

Awọn oṣiṣẹ naa lasiko ifẹhonuhan wọn
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ìyà yí tó gẹ́, ẹ ṣàn owó oṣù tó kéré jù lọ fún wa - Àwọn òṣìṣẹ́ Rufus Giwa ké tantan l'ondo

Ki ni ọbọ fi ṣ'ori ti inaki o ṣe ni ariwo ti awọn oṣisẹ ile ẹkọ gbogboniṣe, Rufus Giwa, ilu Ọwọ RUGIPO fi sẹnu bi wọn ṣe bẹrẹ ifehonuhan ọlọjọ marun-un loni ọjọ Aje, lori ọrọ owo oṣu to kere julọ.

Awọn oṣisẹ naa pejọ si iwaju ẹnu ọna abawọle ile ẹkọ naa ni ilu Ọwọ nipinlẹ Ondo ti wọn si n kọ oniruru orin, pẹlu akọle pe iya yii to gẹ.

Wọn ni titi di asiko yii, awọn oṣisẹ naa si n gba ₦18,000 tako ₦70,000 ti ijọba apapọ buwọlu ni ọdun 2024.

Ni oṣu kẹrin ọdun 2019 ni ijọba apapọ labẹ iṣejọba Oloogbe Muhammadu Buhari gbe owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ kuro ni ₦18,000 lọ ₦30,000.

Labẹ iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu, o gbe owo naa lati ₦30,000 lọ ₦70,000 lọdun 2024.

Lati ọdun 2019, awọn oṣisẹ RUGIPO ni awọn si n gba ₦18,000 gẹgẹ bii owo oṣu to kere julọ lẹyin ayipada meji ọtọtọ latọwọ isejọba meji lorilẹede yi.

Kí ní àwọn osisẹ naa sọ?

Awọn oṣiṣẹ naa lasiko ifẹhonuhan wọn

Lasiko ifehonuhan yi ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ wọn, SSANUP, Saka-Olokungboye Nurudeen sọ pe pe o jẹ ohun ibanujẹ pe ijọba ipinlẹ Ondo labẹ isejọba Lucky Aiyedatiwa kọ iha ko kan mi si iṣoro ti wọn n koju.

Saka-Olokungboye ṣalaye pe gbogbo osisẹ ẹgbẹ naa ti gbe ọpọlọpọ igbese lori ọrọ ọhun amọ pabo ni gbogbo igbiyanju awọn ja si.

O ni wọn ṣe ipade pẹlu awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ati ijọba to si jẹ pe titi di asiko yi kaka ki ewe agbọn dẹ ṣe lo n le si.

O sọ pe awọn oṣisẹ Rufus Giwa nikan ni oṣisẹ to si n gba ₦18,000 gẹgẹ bi owo oṣu to kere julọ ni gbogbo Naijiria.

O seleri pe wọn yoo tẹsiwaju lati maa ṣ ifehonuhan naa titi ti ijọba yoo fi san owo oṣisẹ to kere julọ fun awọn.

Bakan naa akapo ẹgbẹ ọhun, arabinrin Awoyo Olaitan Florence sọ pe ijọba ipinlẹ Ondo ṣi n jẹ wọn ni owo oṣu mẹta.

O ṣalaye pe, ọpọlọpọ oṣisẹ wọn ni o wa ni idubulẹ aisan latari ai ri owo ile iwosan, bẹẹ ni ọpọ awọn onile ni ko ṣetan lati fun awọn oṣisẹ naa ni ile latari ai ri owo ile san.

O rawọ-ẹbẹ si ijọba lati san ₦70,000 to jẹ owo oṣu to kere julọ fun wọn ni ibamu pẹlu aṣẹ ijọba apapọ ki aye le rọrun fun awọn.