Kì í ṣe owó Baba Okoya nìkan ni mo ń ná - Raheem Okoya
Raheem Okoya, gbajumọ olorin ati oniṣowo, ẹni to tun jẹ ọmọ fun gbajumọ oniṣowo, Razaq Okoya ti jẹ kọ di mimọ pe lotilọ ni oun jẹ ọmọ olowo ṣugbọn ki n ṣe owo Baba oun nikan ni oun naa.
Okoya sọ eyi lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori bi o ṣe mu iṣẹ orin ati onkowo papọ, ti ki ọkan ko si di ọkan lọwọ.
Ẹni ọdun mejilelogun lo tun jẹ ọkan lara awọn ọga agba fun ileesẹ Eleganza.

Oríṣun àwòrán, BBC/Okoya
"Ko ki n ṣe pe owo alaga nikan ni mo n na, mo n siṣẹ, ti mo si fẹran owo gan an.
"Mo n gba owo oṣu mi, ti mo si ni awọn eeyan kan ti wọn fi owo sinu iṣẹ orin mi lati ṣe atilẹyin fun mi.
"Ki n ṣe pe wọn bi baba mi pẹlu owo, ti o si fẹ ki awa ọmọ naa siṣẹ fun owo ti wan naa."
Okoya ni pe bi oun ṣe jẹ ọga ileeṣẹ ni ẹni ọdun mejilelogun jẹ nnkan to le diẹ nitori oun jẹ ọdọ ṣugbọn o ti fihan wọn pe oun koju oṣuwọn.
"Pe mo jẹ ọmọ ọga nikan kọ lo gbe mi de ibi, mo ti n kọ nipa iṣẹ yii fun gbogbo aye mi, lati igba ti mo ti wa ni ile ẹkọ.
"Mo ti n tẹle ipasẹ Baba mi, ki n se pe mo kan dede n ṣe ."







