Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ọkọ mi ti lawọ́ sí mi, lèmi náà gbọdọ̀ ṣe jẹ́ ọmọ dáadáa - Shade Okoya
Odu ni Dokita Shade Okoya, kii ṣe aimọ fun oloko, jakejado Naijiria ati awujọ agbaye.
Awọn ti ko ba mọ ọ nitori okowo, yoo mọ ọ nitori ẹwa rẹ tabi nitori pe o jẹ iyawo ọkan lara awọn olowo ni Naijiria, Oloye Razak Okoya.
Lati ọjọ to pẹ ni oriṣiriṣi iroyin, paapaa, awọn to jẹ ahesọ, ti ma n jade nipa igbeyawo Shade pẹlu Okoya.
BBC Yoruba, ninu ifọrọwanilẹnuwo yii, ba Oloye Shade Okoya sọrọ lori igbeyawo rẹ pẹlu ọkọ rẹ, iṣẹ rẹ gẹgẹ bi alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Eleganza, ati irinajo rẹ gẹgẹ bi obinrin.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo naa, Shade Okoya ṣalaye pe lọgan ti ọkọ oun ri oun lo ti fi ifẹ han si oun, to si ṣe gbogbo nnkan to yẹ ni kiakia lati fi oun ṣe aya.

Oríṣun àwòrán, This Day Live/Instagram
Nigba ti Shade Okoya wa ni ọdọ lo fẹ ọkọ rẹ, eyi ti oriṣiriṣi awuyewuye waye lori rẹ lasiko naa.
O sọ fun BBC pe, ọpọ eeyan ni ko lero pe igbeyawo oun pẹlu baba naa le pẹ rara, o ni amọ oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe awọn ti pe ọpọlọpọ ọdun bayii.
Igbeyawo wọn ti le ni ọdun mẹẹdọgbọn.
"Ẹni to lawọ pupọ ni ọkọ mi, lati ibẹrẹ si lo ti fi ow oba mi ṣe. Nitori naa, ni emi naa ko gbọdọ ṣe ma jẹ ọmọ daadaa.
"O ni igbagbọ oun ni pe, paapaa bi ọkọ oun, awọn ọkunrin to ba dagba ma n ni iriri daadaa.
"Ọkọ mi dagba ju mi lọ lootọ, amọ mi o ro pe mo padanu nkankan boya t imo ba fẹ ọmọde."

Arabinrin Okoya ṣalaye pe adura ati ipinnu, pẹlu igbọran si aṣẹ ọkọ, lo mu ki igbeyawo oun dara, to si tọjọ.
"Ara ọkọ mi ni mo ti kọ iwa irẹlẹ. To o ba fẹ duro nile ọkọ, o gbọdọ ni iwa irẹlẹ."
Bakan naa lo ṣalaye pe iṣẹ mẹta ni oun n ṣe – itọju ọkọ, awọn ọmọ ati iṣẹ oojọ.
"Lootọ ni mo ni awọn oṣiṣẹ, ṣugbọn funra mi ni mo n ṣe awọn nnkan ti ọkọ mi ba nilo nitori pe agbalagba to nilo itọju ni .
Lori boya awọn ẹbi rẹ fọwọ si igbeyawo rẹ pẹlu agbalagba, Arabinrin Okoya sọ pe oun ko ni baba laye, amọ iyaaya oun ati iya oun ṣe atilẹyin fun oun.
"Lati ibẹrẹ ni ọkọ mi ti sọ fun mi pe awọn ko le fẹ iyawo to ya ọlẹ, emi naa si fẹran iṣẹ. Eyi ni irolagbara ti ọkọ mi fun mi – wọn kọ mi lati maa pawo funra mi gẹgẹ bi obinrin.
Lori aṣiri ẹwa rẹ, Arabinrin Shade Okoya sọ pe, ifọkanbalẹ, imọtoto ara ati ounjẹ aṣaraloore, ni aṣiri ẹwa oun.
Ta ni Rasaq Okoya tọ́rọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ ń fa awuyewuye lórí ayélujára?
O ṣeeṣe ki ọpọ awọn ọmọ ode oni ma mọ ẹni ri Rasaq Okoya jẹ. Rasaq Okoya jẹ eeyan to gbajumọ nilẹYoruba ati Naijiria, paapaa fun ileeṣẹ rẹ, Eleganza Group, to n ṣe awọn ohun elo ile.
Ti a ba n sọrọ nipa onisowo to lamilaaka lorilẹede Naijiria, ọkan gboogi ni Razaq Okoya.
O jẹ alaga ati oludari ileeṣẹ Eleganza to wa niluu Eko.
Ọpọ eeyan to wa ni Naijiria lati nnkan bi ọdun 1980, ni yoo mọ nipa awọn ohun elo ile bii aga onike, ike ipọni, kula ounjẹ, ati awọn nnkan miran ti ileeṣẹ Eleganza n ṣe.
Wọn bi Okoya si ilu Eko ni ọjọ kejila oṣu kinni ọdun 1940 ni ile Tiamiyu Ayinde ati Idatu Okoya.
Ẹni ọdun marundinlaadọrun ni Okoya, to si jẹ ọmọbibi ilu Eko.
O lọ si ile ẹkọ alakobẹrẹ ni Absar-un-deen ni Oke Popo ni Isalẹ-Eko.
O bẹrẹ lati kọ iṣẹ ransọransọ pẹlu baba rẹ, to si ti mọ nipa iṣẹ naa ko to pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ.
Okoya ni ọpọ iyawo, to si bi ọpọ ọmọ.
Ní 1999 ni ó fẹ́ Shade Okoya tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ tó kéré jùlọ, òun sì ni ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ mọ̀-ọ́n.













