NiMET dá ìyanṣẹ́lódì dúró, fún ìjọba ní gbèdéke láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń rí sí ojú ọjọ́ ní Nàìjíríà, NiMET ti ṣẹ́wélé ìyanṣẹ́lódì tó gùnlé fún ọ̀sẹ̀ méjì.
Èyí wáyé lẹ́yìn ìpàdé àwọn adarí ẹgbẹ́ náà pẹ̀lú mínísítà fétò ìrìnnà òfurufú, Festus Keyamo lọ́jọ́bọ̀.
Ní Ọjọ́rú ni àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì láti fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣiṣẹ́ tí kò rọrùn fún wọn.
Iléeṣẹ́ ìròyìn The Punch sọ pé ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìrìnnà òfurufú, Uzor Oluchi fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ti so ìyanṣẹ́lódì náà rọ̀ ná fún ọ̀sẹ̀ méjì.
Oluchi sọ pé "a ti ṣẹ́wélé ìyanṣẹ́lódì fún ọ̀sẹ̀ méjì, tí ìjọba kò bá dáhùn sáwọn ìbéèrè wa lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, a máa bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì náà padà."
Adarí àjọ NiMET, tó fi mọ́ àwọn aṣojú àwọn òṣìṣẹ́ àtàwọn alẹ́nulọ́rọ̀ ló péjú síbi ìpàdé náà.
Kí ló fa ìyanṣẹ́lódì àjọ NiMet tó n ṣàkóbá fún ìrìnàjò ọkọ̀ òfurufú ní Naijiria?

Iyanṣẹlodi ti ajọ Nimet to n ri si bi oju ọjọ ṣe ri ni Naijiria gunle ti ṣakoba fun irinajo ọkọ ofurufu kaakiri orilẹede Naijiria.
Ọpọ baalu to yẹ ko rinrin ajo lati ilu kan si omiran ni ko le fo latari iyanṣẹlodi ọhun.
Awọn oṣiṣẹ ajọ Nimet gunle iyanṣẹlodi ni Ọjọru, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, lati fi ẹhonu han lori bi wọn ṣe n ṣiṣẹ eyi ti wọn sọ pe ko rọrun to fawọn.
Ọpọ arinrin-ajo ni ko ri baalu gbe wọn lọ si ibi ti wọn n lọ nitori awọn oṣiṣẹ ajọ Nimet to da iṣẹ silẹ.
Iwe iroyin The Guardian ni, igbakeji ọga-agba akọṣẹmọṣẹ nipa iwoye bi oju ọjọ ṣe ri ni ajọ Nimet, Arabinrin Ibiam Aderonke, ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ n beere fun igbayegbadun lẹnu isẹ eyi to nii ṣe pẹlu owo oṣu wọn.
Arabinrin Aderonke sọ pe ''ajọ Nimet nikan ni oṣiṣẹ to wa ni ipele kẹrin lẹnu iṣẹ ko tii bẹrẹ si ni maa gba ẹkunwo owo oṣu to kere julọ ti ijọba ti buwọlu lati ọdun 2019.
Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ yii ko tii bẹrẹ si ni maa gba N70,000 to jẹ owo oṣiṣẹ to kere julọ ti ijọba to wa lode ṣẹṣẹ buwọlu.
Awọn oṣiṣẹ wa mii si n gba N28,000 lowo osu eyi ti ko to lati gbọ bukata wọn ninu ẹbi.''
Igbakeji olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu ni Naijiria, Samuel Uzor, naa fi aidunnu rẹ han lori bi ijọba ko ṣe tii ṣe imuṣẹ eyikeyi ninu awọn adehun ti wọn jọ fọwọ si lọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kinni ọdun yii.
Ọpọ ileeṣẹ ọkọ ofurufu ni Naijiria ni wọn ti wọgile irinajo ọkọ ofurufu to yẹ ki wọn gunle lati Ọjọru, nigba tawọn mii si n ṣiṣẹ.
Airpeace fagile irinajo ọkọ ofurufu
Ileeṣẹ ọkọ ofurufu Airpeace wa lara awọn ileeṣẹ to ti da irinajo ọkọ ofurufu duro ti wọn ko si sọ asiko ti wọn yoo bẹrẹ iṣẹ pada.
Ninu fidio kan to lu ori ayelujara pa l'Ọjọru ni ọga agba Airpeace, Allen Onyema, ti paṣẹ idaduro irinajo ọkọ ofurufu nile iṣẹ ọhun.
Ẹnikan to dabi oṣiṣẹ Airpeace lo beere lọwọ Ọgbẹni Onyema bo ya awọn baalu ileeṣẹ naa yoo gbera, amọ, o ni ko si nnkan to jọ bẹẹ.
Onyema paṣẹ wi pe ki wọn fagile gbogbo irinajo ọkọ ofurufu titi ti ajọ Nimet yoo fi pari iyanṣẹlodi wọn.
Ileeṣẹ ọkọ ofurufu United Nigeria si n ṣiṣẹ
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọkọ ofurufu United Nigeria ni awọn ko ni dawọ iṣẹ duro bo tilẹ jẹ pe ajọ Nimet n yanṣẹ lodi lọwọ.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Chibuike Uloka, fi sita l'Ọjọbọ ọjọ kẹrinlelogun oṣu yii ni o ti sọ pe ko sewu fawọn baalu United Nigeria to n ṣiṣẹ lasiko iyanṣẹlodi ajọ Nimet yii.
O ni gbogbo nnkan to yẹ kawọn ṣe ni awọn n ṣe bo tilẹ jẹ pe awọn oṣiṣẹ ajọ Nimet ti da iṣẹ silẹ.
Ileeṣẹ ọkọ ofurufu United Nigeria ṣalaye pe awọn n lo ọna mii lati mọ bi oju ọjọ ṣe ri lasiko yii ti Nimet n yanṣẹ lodi.
Abẹwo BBC Pidgin si papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe niluu Abuja fi han pe iyanṣẹlodi ajọ Nimet ko da iṣẹ duro rara.
Akọroyin BBC Pidgin to lọ si papako ofurufu l'Abuja l'Ọjọru fidi rẹ mulẹ pe awọn baalu lati ileeṣẹ ọkọ ofurufu bii Ibom Air, Aero, Max Air, United Nigeria ati Arik si n ṣiṣẹ.
Amọ, awọn ero to fẹ wọ baalu Airpeace ko le gunle irinajo wọn.
Awọn ero kan tiẹ ti ṣe ayẹwo tikẹẹti wọn tan ki awọn oṣiṣẹ Airpeace to sọ fun wọn pe ọkọ ofurufu naa ko ni lọ irinajo mọ.
Ẹnikan to n ṣiṣẹ pẹlu ajọ FAAN to n ri si ọrọ ọkọ ofurufu ni Naijiria sọ pe yatọ si aṣẹ Ọga agba Airpeace to wọgile irinajo ọkọ ofurufu nile iṣẹ naa, o ni awọn awakọ baalu Airpeace gan an n bẹru lati gunle irinajo kankan.
Awọn awakọ baalu naa sọ pe ewu nla lo wa nibi ki baalu maa fo lai mọ bi oju ọjọ ṣe ri.















