Wo àwọn tó ṣeéṣe kí ọ̀kan nínú wọ́n di póòpù tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Aleem Maqbool, Rebecca Seales & Paul Kirby
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9
Ta ni yóò di Póòpù tuntun?
Ìpinnu yìí yóò ní ipa lórí ìjọ Àgùdà àtàwọn èèyàn bílíọ̀nù 1.4 tó jẹ́ ọmọ ìjọ náà káàkiri àgbáyé.
Àkójọpọ̀ àwọn Cardinal yóò ṣèpàdé ní ilé ìjọsìn Sistine ní Vatican níbi tí wọ́n ti máa jíròrò, tí wọ́n sì máa dìbò yan títí tí ẹnìkan fi máa borí.
Pẹ̀lú ìdá ọgọ́rin àwọn cardinal tí Póòpù Francis yàn sípò nígbà tó wà láyé, kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa yan póòpù nìyí.
Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn, àwọn èèyàn Yúróòpù díẹ̀ kan lẹ́tọ̀ọ́ pé kí wọ́n dìbò yàn wọ́n láti di póòpù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Póòpù Francis ló yan ọ̀pọ̀ àwọn cardinal náà, kìí ṣe pé wọ́n le di póòpù bẹ́ẹ̀.
Èyí ló fi ṣòro láti sọ pé ẹni báyìí ni wọ́n máa dìbò yàn láti di póòpù tuntun.
Ṣé àwọn cardinal yóò dìbò fún ara ilẹ̀ Africa tàbí Asia láti di póòpù tuntun àbí wọ́n máa ṣàtìlẹyìn fún ọ̀kan lára àwọn alákòso Vatican tẹ́lẹ̀.
Èyí ni àwọn tó ṣeéṣe kí wọ́n gba ipò póòpù lẹ́yìn ìpapòdà Póòpù Francis.
Pietro Parolin
Ọmọ orílẹ̀ èdè Italy
Ẹni àádọ́rin ọdún

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Cardinal Parolin tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Italy ni akọ̀wé Vatican lábẹ́ àkóso Póòpù Francis – èyí túmọ̀ sí pé òun ni olùbádámọ̀ràn àgbà sí póòpù kó tó jáde láyé.
Akọ̀wé náà tún ni olórí Roman Curia tó jẹ́ àárín gbùngbùn ilé ìjọsin náà.
Pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé ó ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣojú póòpù, ọ̀pọ̀ ló ń rò ó pé òun ló ń léwájú nínú àwọn olùdíje.
Cardinal Parolin jẹ́ ẹni tí ọ̀pọ̀ máa ń rí bíi ẹni tó máa ń gbé bí àgbáyé ṣe ń rí wọ́n síwájú àwọn ìlànà ìjọ Àgùdà. Àwọn kan kò fẹ́ràn èyí nípa rẹ̀ àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ríi gẹ́gẹ́ bí ohun tó dára.
Ó jẹ́ ẹni tó máa ń bu ẹnu àtẹ́ lu àjọṣepọ̀ àwọn akọsákọ tàbí abosábo káàkiri àgbáyé. Ní ọdún 2015 nígbà tí Republic of Ireland dìbò láti ṣàtìlẹyìn fún ìbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo, Cardinal Parolin júwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjákulẹ̀ fún ọmọnìyàn.
Nínú àwọn èèyàn 266 tó ti jẹ póòpù rí, 213 ló jẹ́ ọmọ Italy àmọ́ láti bíi ogójì ọdún sẹ́yìn, kò sí póòpù kankan tó tíì jẹ láti Italy, ó sì ṣeéṣe kó tẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀.
Luis Antonio Gokim Tagle
Ọmọ orílẹ̀ èdè Filipino
Ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́rin (67)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣé ó ṣeéṣe kí póòpù wá láti Asia?
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni Cardinal Tagle ní ọ̀pọ̀ ìrírí nídìí iṣẹ́ pásítọ̀ – èyí tọ túmọ̀ sí pé èèkàn ni nínú àwọn àgbà ìjọ láàárín àwọn póòpù, kìí ṣe onímọ̀ nípa òfin ilé ìjọsìn nìkan.
Ìjọ Àgùdà ní ipa tó pọ̀ ní Philippines, níbi tí ìdá ọgọ́rin àwọn èèyàn ibẹ̀ ti jẹ́ ọmọ ìjọ Àgùdà. Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè náà márùn-ún ló wà nínú àwọn cardinal, tí gbogbo wọn bá sì ṣe àtìlẹyìn fún Cardinal Tagle, wọ́n le rí agbára láti gbé èèyàn wọn dé ipò póòpù.
Àwọn kan máa ń rí Tagle bíi ọmọ ìjọ Àgùdà tí kìí ṣe àṣejù, táwọn míì sì máa ń pè é ní Francis ilẹ̀ Asia nítorí ìfarajìn rẹ̀ sọ́rọ àwùjọ àti ojú àánú tó ní sáwọn arìnrìnàjò tí póòpù tó dolóògbé náà ní.
Kò faramọ́ fífi ààyè gba oyún ṣiṣẹ́ bí ó ṣe ní ọ̀nà ìpànìyàn kan ni.
Àmọ́ lọ́dún 2015, nígbà tó jẹ́ Archbishop ti Manila, Cardinal Tagle ní ó yẹ kí ilé ìjọsìn náà ṣe àtúngbéyẹ̀wò àwọn òfin wọn nípa àwọn obìnrin tí kò ní ọkọ, àwọn tó ti kọ ara wọn sílẹ̀ àtàwọn tó máa ń ní ìbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo.
Ó ní ọwọ́ líle tí ilé ìjọsìn fi ń mú àwọn èèyàn náà ń fa ìpalára tó pọ̀ àti pé gbogbo èèyàn ló nílò àánú àti ọ̀wọ̀.
Kódà ní ọdún 2013 tí wọ́n yan póòpù Francis ni àwọn kan ti ń sọ pé ó ṣeéṣe kí Cardinal Tagle di póòpù àmọ́ tó ní eré ni òun ka ọ̀rọ̀ náà sí.
Fridolin Ambongo Besungu
Ọmọ orílẹ̀ èdè Congo
Ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin (65)

Oríṣun àwòrán, AFP
Ó ṣeéṣe kí póòpù tuntun wá láti ilẹ̀ Africa, níbi tí ìjọ Àgùdà ti ń gbòòrò si ní ọdọọdún. Ọ̀kan lára àwọn olùdíje tó ń léwájú ni Cardinal Ambongo tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo (DRC).
Láti bíi ọdún méje ló ti jẹ́ Archbishop Kinshasa, Póòpù Francis ló yàn-án gẹ́gẹ́ bí cardinal.
Ipò rẹ̀ lórí àṣà ló ṣe lòdì sí bíbuwọ́lu ìgbéyàwó akọsákọ àti abosábo.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ ló pọ̀ jù ní DRC, àwọn Kristẹni ń kojú ìkọlù látọwọ́ àwọn alákatakítí ẹ̀sìn Islam, táwọn èèyàn sì ń rí Cardinal Ambongo gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń jà fún ilé ìjọsìn.
Àmọ́ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe lọ́dún 2020 pé kí wọ́n fi ààyè gba àwọn mùsùlùmí láti jẹ́ mùsùlùmí, káwọn ẹlẹ́bọ jẹ́ ẹlẹ́bọ, pé àwọn máa báwọn siṣẹ́ bẹ́ẹ̀ àmọ́ kí oníkálukú ní ààmì ìdánimọ̀ tirẹ̀.
Ó ṣeéṣe káwọn cardinal kan má faramọ́ irú ọ̀rọ̀ báyìí bí ó ṣe jẹ́ pé iṣẹ́ ìjọ Àgùdà ni láti tan ìyìnrere ká gbogbo ayé.
Peter Kodwo Appiah Turkson
Ọmọ orílẹ̀ èdè Ghana
Ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (76)

Oríṣun àwòrán, Reuters
Tí wọ́n bá yàn-án, Cardinal Turkson ni yóò jẹ́ ọmọ Africa àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ póòpù láti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (1,500) ọdún sẹ́yìn.
Gẹ́gẹ́ bí Cardinal Ambongo, òun náà sọ pé òun kò wá láti di póòpù. "Kò dá mi lójú pẹ ẹnìkankan máa ń gbèrò láti di póòpù," ó sọ fún BBC lọ́dún 2013.
Nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lórí pé ṣé ó ṣeéṣe kí Africa pèsè póòpù tí a bá wo bí ìjọ náà ṣe ń dàgbà si ní Africa, ó ní òun kò rò pé bí ìjọ ṣe ń dàgbà sin í ẹkùn kọ̀ọ̀kan jẹ́ ohun tó yẹ kí wọ́n máa lò láti fi yan póòpù.
Turkson ni àkọ́kọ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Ghana tó máa di Cardinal lábẹ́ Póòpù John Paul ii lọ́dún 2003.
Ó wà lára àwọn Cardinal tí wọ́n ń yàn láti di póòpù lọ́dún 2013 kó tó já mọ́ Póòpù Francis lọ́wọ́.
Kò faramọ́ sísọ ìbaṣepọ̀ akọsákọ tàbí abosábo di ìwà ọ̀daràn nílẹ̀ Africa tó fi mọ́ orílẹ̀ èdè rẹ̀, Ghana.
Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀l;u BBC lọ́dún 2023, Turkson ní òun rò pé kó yẹ kí ìbáṣepọ̀ akọsákọ tàbí abosábo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Lọ́dún 2012, ó sọ̀rọ̀ nípa bí Islam ṣe ń gbilẹ̀ ní Europe níbi ìpàdé àwọn bíṣọ́ọ̀bù ní Vatican tó sì fa ọ̀pọ̀ ìbẹ̀rù bojo àmọ́ tó padà tọrọ àforíjì.
Peter Erdo
Ọmọ orílẹ̀ èdè Hungary
Ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin (72)

Oríṣun àwòrán, Reuters
Láti ìgbà tí Peter Erdo ti wà lẹ́ni ọdún mọ́kànléláàádọ́ta (51) ló ti di Cardinal tí wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún-un ní ilé ìjọsìn ní Europe. Ó ti darí ìgbìmọ̀ Council of European Bishops' Conferences ní ẹ̀ẹmèjì láàárín ọdún 2006 sí 2016.
Ó jẹ́ ẹni mímọ̀ dáadáa láàárín àwọn cardinal ilẹ̀ Africa.
Edro jẹ́ Archbishop Budapest àti Primate ilẹ̀ Hungary. Inú ìjọ Àgùdà ló dàgbà sí, tó sì wà lára àwọn olùdíje tó ń léwájú.
Ó kó ipa pàtàkì nígbà tí Póòpù Francis ṣe àbẹ̀wò sí Hungary lọ́dún 2021 àti 2023 tó sì wà lára àwọn tó yan Francis àti ẹni tí Francis gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀, Póòpù Benedict XVI.
Ojú tó fi máa ń wo ọ̀rọ̀ ìdílé jẹ́ ohun tó máa ń dún mọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn nínú.
Nígbà làásìgbò báwọn arìnrìnàjò lọ́dún 2015, Cardinal Erdo ní ilé ìjọsìn kò ní gba arìnrìnàjò kankan sọ́dọ̀ nítorí ó máa túmọ̀ sí pé àwọn ń fi èèyàn ṣọ̀fà ni.
Angelo Scola
Ọmọ orílẹ̀ èdè Italy
Ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Cardinal tí ọjọ́ ori wọn bá wà lábẹ́ ọgọ́rin ọdún nìkan ni wọ́n ní àǹfàní láti dìbò láti yan póòpù àmọ́ wọ́n le dìbò yan Angelo Scola.
Archbishop tẹ́lẹ̀ rí náà fún Milan jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdíje tó léwájú lọ́dún 2013.
Orúkọ rẹ̀ tún ti jẹ jáde lásìkò yìí nítorí ìwé kan tó ń ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ lórí ọjọ́ ogbó. Póòpù Francis ló kọ ọ̀rọ̀ àkọ́sọ ìwé náà kó tó di èrò ilé ìwòsàn.
Ó kọ pé "ikú kìí ṣe òpin ohun gbogbo, bíkòṣe ìbẹ̀rẹ̀ ohun kan."
Francis ṣàfihàn ìfẹ́ sí Scola àmọ́ ó ṣeéṣe káwọn cardinal má dìbò yàn-án nítorí ọjọ́ orí rẹ̀.
Reinhard Marx
Ọmọ orílẹ̀ èdè Germany
Ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rin (71)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àgbà àlùfáà ìjọ Àgùdà Germany àti èèkàn inú Vatican.
Archbishop Munich náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùbádámọ̀ràn tí Póòpù Francis yàn nígbà tó di póòpù lọ́dún 2013. Ó máa ń gba póòpù nímọ̀ràn lórí àtúnṣe ìjọ fún ọdún mẹ́wàá tó sì ń ṣe àkóso ètò owó Vatican títí di àsìkò yìí.
Cardinal Marx jẹ́ ẹni tó máa ń pè fún ọ̀nà láti gba àwọn tó ń ní ìbáṣepọ̀ akọsákọ mọ́ra nínú ìwáàsù ìjọ Àgùdà.
Lọ́dún 2021, ó gbìyànjú láti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ lórí àṣìṣe kan tó wáyé lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ àwọn ọmọdé ní ìjọ Aguda ní Germany àmọ́ tí Póòpù Francis kọ̀ láti buwọ́lu ìwé náà.
Ní ọdún méjì sẹ́yìn lọ kúró ní ipò ìgbìmọ̀ àwọn Cardinal tí ọ̀pọ̀ sì ri bíi ìfàsẹ́yìn lórí ipò rẹ̀.
Marc Ouellet
Ọmọ orílẹ̀ èdè Canada
Ẹni ọgọ́rin (80) ọdún

Oríṣun àwòrán, Reuters
Fún ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti rò pé Cardinal Ouellet yóò jẹ́ olùdíje fún ipò póòpù, lọ́dún 2005 àti 2013.
Fún ọ̀pọ̀ ló fi jẹ́ olórí Vatican Dicastery fáwọn bíṣọ́ọ̀pù, tó máa ń yan ẹni tí yóò jẹ bíṣọ́ọ̀bù káàkiri àgbáyé.
Nítorí pé ó tip é ọgọ́rin ọdún, k]o nílè kópa níbi ètò ìdìbò, tí èyí sì lè ní ipa lórí ìyànsípò rẹ̀.
Ó máa ń tako yíyan àwọn obìnrin sí ipò àlùfáà àmọ́ tó pè fún fífún àwọn obìnrin iṣẹ́ si láti le tẹ ìjọ náà síwájú.
Ó sọ pé "ọkùnrin ni Jésù, ìjọ jẹ́ obìnrin.
Robert Prevost
Ọmọ orílẹ̀ èdè America
Ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rin (69)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣé ó ṣeéṣe kí Amẹ́ríkà jẹ póòpù fún ìgbà àkọ́kọ́?
Cardinal Prevost jẹ́ ẹnìkan tí ọ̀pọ̀ gbà pé ó ní gbogbo àmúyẹ láti di ipò náà mú.
Ní ọdún méjì sẹ́yìn ni Póòpù Francis yan Prevost láti rọ́pò Marc Ouellet gẹ́gẹ́ bíi adarí Vatican Dicastery fún bíṣọ́ọ̀bù, tó túmọ̀ sí pé iṣẹ́ rẹ̀ ni láti yan àwọn bíṣọ́ọbù.
Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ajíyìnrere fún ọ̀pọ̀ ọdún ní Peru kó tó di archbishop níbẹ̀.
Prevost kìí ṣe ọmọ Amẹ́ríkà nìkan, òun ni olórí Pontificial Commission fún Latin America.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ri bíi ẹni tó le ṣe àtúntò àmọ́ àwọn kan ń wò ó pé ọjọ́ orí rẹ̀ kéré láti jẹ póòpù.
Nígbà tó wà ní archbishop Peru, àwọn ẹ̀sùn pé ó fọwọ́ bo ìwà ìfipábánilòpọ̀ mọ́lẹ̀ àmọ́ tí ìjọ náà jiyà àwọn ẹ̀sùn náà.
Robert Sarah
Ọmọ orílẹ̀ èdè Guinea
Ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin (79)

Oríṣun àwòrán, GUY PETERSON/AFP
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n fẹ́ràn Cardinal Sarah ní ìjọ Àgùdà, tó sì gbajúmọ̀ fún títẹ̀lé àwọn ìlànà ìjọ náà, táwọn mìíràn sì máa ń rip é ó lòdì sáwọn àtúntò Póòpù Francis.
Sarah di archbishop tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré jùlọ nígbà tí wọ́n yàn-án lẹ́ni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n nígbà tí Póòpù John Paul II yàn-án ní prelate fún Conakry ní Guinea.
Ọdún 2021 ló fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ọ́fíìsì tó ń rí sí ètò ìjọ Aguda ṣe ń wáyé.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kií ṣe ààyò fún ipò póòpú, ó ṣeéṣe kó rí àtìlẹyìn àwọn kan.
Michael Czerny
Ọmọ orílẹ̀ èdè Canada
Ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin (79)

Oríṣun àwòrán, ANGELO CARCONI/EPA-EFE/REX/Shutterstock
Póòpù Francis ló yan Czenry gẹ́gẹ́ bí cardinal báwọn méjéèjì ṣe jọ jẹ́ Jesuit.
Ní Czechoslovakia tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ti bi àmọ́ àwọn ẹbí rẹ̀ ṣe ìrìnàjò lọ sí Canada nígbà to wà ní ọmọ ọdún méjì.
Ó ṣiṣẹ́ dáadáa ní Latin America àti Africa níbi tó ti bẹ̀rẹ̀ African Jesuit Aids Network, tó sì tún ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní Kenya.
Czerny gbajúmọ̀ láàárín àwọn onítẹ̀síwájú ìjọ Aguda, táwọn kan sì máa ń rip é ó súnmọ́ Póòpù Francis.
Òun ni adarí Vatican Dicasteryfún ìgbéga ìdàgbàsókè ọmọnìyàn báyìí.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olùdíje tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rinlẹ̀ ni, ó ṣeéṣe káwọn cardinal má yàn-án nítorí wọ́n le fẹ́ má yan Jesuit méjì tẹ̀lé ara wọn.











