Kí ló dé tí ẹnu ń kun Seyi Makinde àti Gómìná ìpínlẹ̀ Kano tẹ́lẹ̀ Rabiu Kwankwaso lórí ìpàdé bòńkẹ́lẹ́ tí wọ́n ṣe nílùú Ibadan?

Oríṣun àwòrán, Oyo state Government
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Kano to tun jẹ oludije fun ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People's Party (NNPP), Rabiu Kwankwaso bẹ Gomina Seyi Makinde ti Ipinlẹ Ọyọ wo lọjọru eyi to mu ki ọpọ ẹnu maa kun awọn mejeeji paapaajulọ pẹlu bi ọrọ oṣelu ṣe ti n gberasọ ni imurasilẹ fun eto idibo apapọ lọdun 2027.
Aisi ni ẹgbẹ oṣelu kan naa awọn mejeeji yii tubọ mu ki ọpọ maa beere pe ajọṣepọ afaa ati iya alaro n fẹ amojuto,gẹgẹbi ọrọ awọn agba.
Amọṣa o, Rabiu Kwankwaso ṣalaye lẹyin ipade bonkẹlẹ ti wọn ṣe ni ọfiisi ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa lagbegbe Agodi nilu Ibadan pe abẹwo oun ko ni ṣe pẹlu ọrọ oṣelu rara biotiwulẹ o mọ.
Kwankwaso, to tun ti fi igba kan ri jẹ minisita fun eto aabo lorilẹede Naijiria de si ile ìjọba Ipinlẹ Oyo ni bi aago meji aabo ọsan ọjọ karundinlogbon oṣu Keji ọdun 2026.
Kwankwaso ati Seyi Makinde ni wọn dijọ wọ yara ipade igbimọ iṣejọba ti Ijọba Ipinlẹ Oyo ti wọn si ṣe ipade alatilẹkunmọriṣe eyi to gba wọn fun ogoji isẹju o le diẹ.
Lẹyin ipade naa ni Kwankwaso ṣalaye fun awọn akọroyin wi pe ọfiisi ẹgbẹ oṣelu NNPP tuntun fun Ipinlẹ Oyo ni oun wa ṣii ati wi pe, Gomina Seyi Makinde wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP eyi ti oun ati awọn oloṣelu kan jọ daa silẹ ni ọdun 1998.
O tẹsiwaju pe ẹgbẹ oṣelu oun ni ẹgbẹ oṣelu PDP nitori wi pe ẹmeji ọtọtọ ni oun jẹ Gomina nipinlẹ Kano labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ti oun si tun jẹ minisita fun aabo orile-ede yii nitori oun jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Kwankwaso ẹniti adari agba fun ẹgbẹ oṣelu NNPP Ajid Ahmed kọwọrin pẹlu rẹ ni, bi ẹgbẹ oṣelu NNPP yoo ṣe fẹsẹ wale nipinlẹ Oyo ṣaaju eto idibo ọdun 2027 ni oun wa yanju ati pe ti oun baa ti ṣii ọfiisi ẹgbẹ oṣelu NNPP ti Ipinlẹ oyo tuntun tan, ni oun yo pada si ilu Abuja.
Te ba gbagbe, Kwankwaso loti fi igbakanri jẹ Gomina Ipinlẹ Kano labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ko to lọ si ẹgbẹ oṣelu APC nibiti o ti tun kuro to si dije du ipo aarẹ Orilẹ-ede yii ninu ẹgbẹ oṣelu NNPP ninu eto idibo Aarẹ ọdun 2023.

Oríṣun àwòrán, Oyo Govt
























