Mohbad kò bá má kú, ká ní òun àtàwọn òbí rẹ̀ sá di OPC tàbí sọ fún wa nípa ìdojúkọ rẹ̀ – OPC

Oríṣun àwòrán, Mohbad
Ẹgbẹ Oodua People’s Congress, OPC ti fi aidunnu rẹ han lori iku ọdọmọde olorin takasufe, IleriOluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad.
Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi sita lati ọwọ akọwe agba rẹ, Bunmi Fasehun, OPC awọn ko bá daabo bo Mohbad tó ku lẹni ọdun metadinlọgbọn lọwọ awọn to n lepa ẹmi rẹ, ti o bá sọ ilakọja rẹ fawọn.
Aarẹ OPC, Otunba Wasiu Afolabi ṣapejuwe iku Mohbad gẹgẹ bii ibanujẹ nla.
OPC ri iku Mohbad gẹgẹ bii adanu to ṣe ẹgbẹ naa tori aṣoju ẹya Yoruba ni Mohbad jẹ pẹlu orin to n kọ.
"O yẹ kí awọn obi Mohbad at'awọn to n ṣiṣẹ pọ pẹlu Mohbad fi ọrọ naa to OPC leti"
Otunba Afolabi sọ ninu atẹjade naa pe Mohbad gbe èdè Yoruba larugẹ nipa fifi ede abinibi kọrin eleyii tàwọn eeyan tẹwọ gbà.
O ni OPC gbagbọ pe o yẹ kí awọn obi Mohbad at'awọn to n ṣiṣẹ pọ pẹlu rẹ fi ọrọ naa to OPC leti nigba ti awọn kan ti bẹrẹ sí ni ṣe ikọlu sí i.
Aarẹ OPC ni ẹgbẹ naa ti pẹtu si irú aawọ bẹẹ tẹlẹ ri ti alaafia si jọba.
Otunba Afolabi ni “a maa n da iṣẹ wa ṣe nigba mii, bakan naa ni a maa n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbofinro nigba mii.
"Ni ọpọ igba, tàwọn eeyan ba ti gbọ orukọ OPC lasan, ọrọ ti yanju niyẹn"
“Ṣugbọn a gbọdọ ri pe a daabo bo ẹni ti wọn ba fẹ yanjẹ.
“Igba miiran gan an, a le gbe ẹjọ naa de ọdọ ijọba.
“Ni ọpọ igba, tàwọn eeyan ba ti gbọ orukọ OPC lasan, ọrọ ti yanju niyẹn.
“Eyi lo jẹ ko ba wa ninu jẹ pe Mohbad ko jẹ ki a gbọ si ọrọ naa.”
OPC wa kepe ileeṣẹ ọlọpaa, ajọ DSS ati ijọba lati rí pe idajọ ododo waye lori gbogbo awọn to lọwọ ninu iku Mohbad.
Ẹgbẹ OPC ni ọpọ ẹri lo wa lori ayelujara lori iku Mohbad eleyii to le ṣe iranwọ fún idajọ ododo.
Bakan naa ni ẹgbẹ OPC sọ pe awọn ọlọpaa ti wọn kọ lati gbe igbesẹ lori ẹjọ ti Mohbad pe gbọdọ foju wina ofin.
Mohbad bá àwọn ẹni ibi jẹ, ó bá wọn mu, kò mọ̀ pé ẹ̀mí òun yóò kúrú – Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Tunde Bakare/Mohbad
Pasitọ agba ijọ Citadel Global Community Church, Tunde Bakare, ti sọ pe gbajugbaja olorin takasufe to jade laye, Ilerioluwa Aloba ‘Mobad’ ba awọn ẹni ibi dowopọ nigba aye rẹ.
Bakare lo sọ ọrọ naa nibi iwaasu rẹ ninu ijọ The Envoy Nation, to wa nilẹ Gẹẹsi.
Ninu iwaasu naa to waye lasiko ajọ ajọduin ọdun keji ijọ naa ni Bakare ti sọ pe awọn eeyan buburi ni Mohbad ba rin lasiko to wa laye.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 yii ni Mohbad dagbere faye, ti wọn si sin oku rẹ lọjọ keji.
Bakare sọ pe “Melo ninu yin lo mọ Mohbad, olorin ọmọ Naijria to jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgbọn?
“Nigba to n mu ọti ati siga, to si n ba awọn eeyan buburu rin, ko mọ pe yoo kere iṣe ọwọ rẹ laipẹ ti ẹmi rẹ yoo si ge kuru laipẹ ọjọ.
"Ṣe orukọ ọmọluabi ni Mohbad bí?”
“Mi o da lẹbi o, mo kan n bi yin ni pe ṣe orukọ ọmọluabi ni Mohbad?”
Ẹwẹ, lẹyin ti fidio iwaasu naa gbode lori ayelujara, ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ pasitọ naa fun ọrọ rẹ.
Lara awọn eeyan to n sọko orọ si Bakare ni gbajugbaja oṣere, Tonto Dikeh ati Femi Fani-Kayode.
Wayi o, ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣe ayẹwo oku oloogbe naa lati mọ iru iku to pa a, o si ti ke si awọn araalu ki wọn ni suuru titi ti esi ayẹwo naa yoo fi jade.
"Mohbad ti kú, kó tó dé ilé ìwòsàn wa, Nọ́ọ̀sì wa kọ́ ló fún-un ní abẹ́rẹ́"

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ile iwosan kan nipinlẹ Eko, Perez Medcare hospital, ti kede fun araye pe oun ko mọ ohunkóhun nípa ikú tó pa gbajúmọ̀ akọrin takansufe nnì, Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ eeyan mọ si Mohbad.
Ni ọjọ Kejila oṣù kẹsàn-án ọdun 2023 yìí ni ariwo ta pe akọrin ẹni ọdún mẹtadinlọgbọn naa ku lasiko aisan ranpẹ.
Onírúurú ìròyìn tí ko fẹsẹ mulẹ si ló n lọ pe ile iwosan kan, ti wọn gbe Mohbad lọ lasiko ti ara rẹ ko ya, ni Nọọsi kan tí fún ní abẹrẹ, tó sì mi kanlẹ laipẹ lẹyin naa.
Àmọ́ ile iwosan naa ti wa fi atẹjade kan síta lọ́jọ́ aje pe oun ko mọ bí Mohbad ṣe ku, nọọsi kankan ko si fun ni abẹrẹ nile iwosan Perez Medcare.
"Aago mẹ́rin àbọ̀ irọlẹ ni wọn gbé ara Mohbad ti ko mí mọ wọnú ọgbà ilé ìwòsàn wá"
Atẹjade ọhun, to wá loju opo ayelujara Instagram ilé ìwòsàn náà sísọ lójú rẹ pe oku ni wọn gbé Mohbad wọnú ilé ìwòsàn àwọn.
Bákan ni ile iwosan Perez ṣẹ pé lórí ìròyìn kan tó ní wọn gba akọrin naa wọlé bíi aláìsàn sínú ilé ìwòsàn náà.
Atẹjade naa tẹsiwaju pé "Deedee aago mẹ́rin àbọ̀ irọlẹ ọjọ Kejila, osu Kẹsan ọdun 2023, ni wọn gbé ara Mohbad ti ko mí mọ wọnú ọgbà ilé ìwòsàn wá.
Àwọn osisẹ eleto ìlera wa si bẹ̀rẹ̀ isẹ lójú ẹsẹ láti tọju rẹ àmọ́ a ri pe ko si ẹ̀mí mọ lára akọrin naa, ọkàn rẹ ko sisẹ mọ, bákan naa ni o ti ranju silẹ lai sẹju.
A wá sa gbogbo ipá wa lati ji pada saye ṣùgbọ́n a rí pe àwọn ẹ̀yà ara rẹ kan ti n gan, ti a si sọ fun awọn eniyan to gbe wa sọdọ wa pe o ti ku, ki wọn to gbe wa.
Nigba ti a si beere nípa ohun to sẹlẹ si Mohbad, wọn ni Nọọsi kan tí kọ́kọ́ wá fun ni abẹrẹ tẹ́lẹ̀ ninu ile, ki wọn to gbe wa sile iwosan wa.
A si rọ àwọn ènìyàn tó gbé akọrin naa wa sile ìwòsàn wa pe ki wọn tètè máa gbe e lọ sílè iwosan ìjọba, níbi tí wọ́n yóò ti ní anfaani lati tẹ ẹ sile igbokunpamọsi."

Oríṣun àwòrán, Perez Medcare Hospital
"Nọọsi ile iwosan wa kọ lo fún Mohbad ni abẹrẹ ko to ku"
Atẹjade naa wa tẹnumọ pe irọ lasan ni ayédèrú iroyin ti wọn n pín kiri pe òṣìṣẹ́ ile iwosan oun ni Nọọsi to fún Mohbad ni abẹrẹ.
Ile iwosan Perez Medcare fikun pe ile iwosan naa kọ lo wa ninu fídíò kan to ń safihan Mohbad lórí ibùsùn tí wọn ti n tọju rẹ.
Ikú Mohbad yii lo ti n fa awuyewuye lori ayelujara yíká orilẹ-ède Naijiria àtàwọn ìlú kan nilẹ òkèèrè, ti iléeṣẹ́ ọlọ́pàá si ti gbe ìgbìmọ̀ oluwadi kan kalẹ láti ṣe àwárí ikú tó pa gbajúmọ̀ akọrin takansufe náà.
Ìgbìmọ̀ oluwadi iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ọhun sì ti pàṣẹ pe kí wọn lọ hun oku Mohbad tí wọn sìn lẹyin wakati díẹ̀ to dagbere faye fun ayẹwo ìgbàlódé láti mọ irú ikú tó pá a.
Ayẹwo naa ti waye, tí gbogbo ènìyàn sì ń dúró de ìkéde èsì ayẹwo ikú tó pa akọrin naa

















