Ojú lásán kọ́ ni ọ̀rọ̀ iná tó jó ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ, ejò lọ́wọ́ nínú – PDP yarí

Oríṣun àwòrán, @abati1990
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti ke si awọn agbofinro lati ṣe iwadii kulẹkulẹ ohun to ṣokunfa ina to sẹyọ nile ẹjọ to ga julọ lọjọ Aje.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ẹgbẹ oselu naa, Debo Ologunagba, fi lede lo ti kede bẹẹ.
Atẹjade naa ni iyalẹnu nla lo jẹ fun PDP pe ina le dede sọ nile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria, awọn si gbagbọ pe ejo lọwọ ninu iṣẹlẹ ọhun.

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig
Ologunagba ni “Ẹgbẹ oṣelu PDP kọminu lori ina to ṣẹyọ paapaa bi ọpọ eeyan ṣe gbagbọ pe o ṣeeṣe ki wọn mọọmọ da ina ọhun lọna ati dena ile ẹjọ ọhun ninu ojuṣe rẹ lori ẹjọ to waye lori esi ibo Aarẹ to wa niwaju rẹ.”
“Ẹgbẹ oṣelu wa n beere fun iwadii kikun lori ohun to ṣokunfa ina naa ati lati mọ boya o lọwọ aye ninu.”
“PDP n fẹ ki ijọba kede esi iwadii naa fun gbogbo agbaye yatọ si awọn iwadii iṣẹlẹ ina kan to ti waye ṣaaju, eyii ti ijọba APC fi ọwọ bo mọlẹ.”

Oríṣun àwòrán, @abati1990
Ologunagba wa ke si ijọba ko mu eto abo lọkunkundun lagbegbe ile ẹjọ ọhun.
Lẹyin naa lo ni ki ijọba fi aridaju sita pe awọn iwe to ṣe koko si ile ẹjọ naa ko ba ina ọhun lọ.
Ẹwẹ, Agbẹnusọ ile ẹjọ naa, Festus Akande ti sọ pe ina mọnamọna to ṣe segesege lo ṣokunfa ijamba ina naa.
Akande lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin Punch.
Akande fi kun pe irọ ni igbagbọ awọn eeyan kan pe awọn faili to ni ṣe pẹlu igbẹjọ Atiku Abubakar ati Peter Obi, eyii ti wọn pe lodi si esi ibo Aarẹ ọdun 2023 ti ba ina ọhun lọ.
Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà jóná, àwọn fáílì ẹjọ́ di eérú

Oríṣun àwòrán, JUDICIARY
Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jóná ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé.
Ilé ẹjọ́ náà tó wà ní Three Arms Zone ní olú ìlú Nàìjíríà, Abuja ló jẹ́ ọ́fíìsì àwọn adájọ́ àgbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta Nàìjíríà.
Ohun tó ṣokùnfà iná náà ni kò ì tíì yé ẹnikẹ́ni ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ti ń ṣiṣẹ́ láti pa iná náà.
Ìròyìn tó gbòde tí BBC kò ì tíì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ báyìí ni pé iná ọ̀hún ṣàkóbá fún ọ́fíìsì àwọn adájọ́ àgbà mẹ́ta àmọ́ iye àwọn nǹkan tí iná náà bàjẹ́ kò ì tíì jẹ́ mímọ̀.
"Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn fáílì kan bá iná náà lọ, àmọ́ a ní ẹ̀dá gbogbo rẹ̀ lórí kọ̀mpútà"
Agbẹnusọ ilé ẹjọ́ náà, Dókítà Festus Akande ní àwọn ìwé àti fáílì kan ti jó.
Akande ní iná náà ṣàkóbá fún ọ́fíìsì ọ̀kan nínú àwọn adájọ́ àgbà Nàìjíríà amọ kò dárúkọ èyí tó jẹ́ gan nínú àwọn adájọ́ náà.
Bákan náà ló ní iná mọ̀nàmọ́ná ló ṣokùnfà iná ọ̀hún.
Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ló ti kọ́kọ́ gbìyànjú láti pa iná náà pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń pa iná tó wà ní ọ́fíìsì wọn.
Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn fáílì kan bá iná náà lọ, ó ní àwọn ní ẹ̀dá gbogbo rẹ̀ lórí kọ̀mpútà àwọn.















