Ẹ̀sùn lásán ni wọ́n ṣì fi kan Aiyedatiwa, a kò tíì yọọ́ nípò — Ilé Aṣòfin Ondo

Oríṣun àwòrán, Ile aṣofin Ondo
Ile aṣofin ipinlẹ Ondo lo ti fi lede pe awọn ko ni fi igba kan bọ ọkan ninu lori iwadi ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan igbakeji gomina ipinlẹ ọun, Lucky Aiyedatiwa.
Atẹjade kan latọwọ ẹni to jẹ alaga igbimọ to n moju to eto iroyin nile aṣofin naa, Olatunji Oshati, ni awọn aṣofin naa ti wi pe ifẹsunkanni lasan ṣi ni ọrọ naa titi di igba ti iwadi yoo pari.
Oshati to rọ awọn araalu lati ma ṣe sọ ọrọ ana di bamii kojumọ o too mọ ṣalaye pe “ni tootọ, bi a ṣe kọwe si igbakeji gomina lori ẹsun ti wọn fi kan-an ni ibẹrẹ iyọni nipo, amọ awọn igbesẹ to rọ mọọ pọ gan kii sii ṣe ohun tẹnikan lee ṣe loru mọju.
“A mọ pe awọn araalu n reti ki a ṣe ohun to tọna, a ko si nii jawọn kulẹ.
“A fẹẹ ki wọn mọ pe ilana to kẹnu wa ninu ofin orilẹ ede yi nipa iru iṣẹlẹ yi taa gbọdọ tẹlẹ, a si ni ẹtọ labẹ ofin lati rii pe a moju to gbogbo ohun to ba n lọ nipa eto iṣejọba ko ma baa si magomago ninu eto inawo.
“A waa rọ gbogbo araalu lati yago fun ahesọ to le domi alaafia ilu ru tori pe ko si ẹnikẹni ninu gomina ati igbakeji rẹ to kọja ofin.
“A ti kọwe ranṣẹ si igbakeji gomina nipa ẹsun ti wọn fi kan-an, o si ni ẹtọ labẹ ofin lati sọrọ gbera rẹ lẹyin leyi ti yoo mu ẹkọ o fi oju mimu han.
“A si fi da gbogbo aye loju pe ilana ti ofin la kalẹ ni a maa tẹle lai si makaruru kankan.”
Ẹwẹ, awọn agbofinro lo ti sọ ọna abawọle sile aṣofin naa di ibi to nira lati wọ pẹlu bi wọ ṣe pọ niye ju ti tẹlẹ lọ.
Awọn agbofinro ọun ni wọn n ṣe ayẹwo finnifinni fun ẹnikẹni to ba fẹẹ wọ ile aṣofin naa ti wọn si n da ẹni ti ko ba ni idi pataki lati wọle pada.
Ọkan lara awọn agbofinro naa to ni ohun ko lẹtọ lati ba akọroyin sọrọ wi pe niṣe ni awọn wa nibẹ lati pese aabo to peye ati lati dena ohunkohun to le fa laasigbo nile igbimọ naa.
Titi akoko ti a n ko iroyin yi jọ, igbakeji gomina, Lucky Aiyedatiwa ni ko tii wi ohunkohun lori gbogbo ọrọ naa bo ti lẹ pe o ti di aruwo laarin ilu ati lori ẹrọ ayelujara.
Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ondo kọ̀wé sí igbákejì gómìnà kó wá wí tẹnu rẹ̀ lórí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo ni Ọjọru, ogunjọ oṣu kẹsan ọdun yi lo ti pa akọwe ile aṣofin naa laṣẹ lati fi iwe ranṣẹ si igbakeji gomina ipinlẹ ọun, Lucky Aiyedatiwa, lati sọ ohun to mọ nipa ẹsun iwa ibajẹ ti awọn kan nile aṣofin naa fi kan-an.
Adari ọmọ ile to pọ ju lọ, Oluwole Ogunmolasuyi, lo gbe aba naa kalẹ niwaju awọn akẹgbẹ rẹ, ti Tope Agbulu, to n ṣoju ẹkun iwọ-oorun-guusu Akoko keji, si kin aba naa lẹyin.
Eyi lo mu ki abẹnugan ile aṣofin ọun, Olamide Oladiji, ni ki awọn to ba faramọ aba naa o paruwo soke ti ko si si aṣofin kan to tako aba naa.
Lẹyin eyi ni Oladiji paa laṣẹ fun akọwe ile aṣofin naa, Benjamin Jaiyeola, lati kọ iwe ranṣẹ si ọgbẹni Aiyedatiwa ko le mọ ẹsun ti wọn fi kan-an.
Oladiji wi pe aṣofin mẹsan lo buwọ lu iwe ẹsun naa ki Ogunmolasuyi o too gbe ka iwaju ile.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ iwa ibajẹ ọun ni pato ninu gbogbo ọrọ ti wọn sọ nibi ijoko awọn aṣofin naa, iwadi ileeṣẹ BBC News Yoruba fihan pe ẹsun ti wọn fi kan igbakeji gomina naa ni pe o buwọ lu rira ọkọ ayẹta ti owo rẹ to ọọdunrun miliọnu naira fun ara rẹ lai fi to igbimọ iṣejọba leti.
Aiyedatiwa ni wọn ni o buwọ lu rira ọkọ naa lakoko to jẹ adele gomina laarin oṣu mẹta ti gomina Oluwarotimi Akeredolu fi n gba itọju lorilẹ ede Germany.
Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ gomina Akeredolu to ni aaye ko gba oun lati sọrọ sita wi pe Aiyedatiwa lo da gbe igbesẹ naa lai fi ọrọ lọ ẹnikẹni.
O fi kun pe ninu owo iranwọ ‘subsidy’ ni Aiyedatiwa ti ni ki wọn yọ ọọdunrun miliọnu naira owo ọkọ ọun.
Ẹwẹ, Lucky Aiyedatiwa ni ikọ iroyin BBC News Yoruba ko lee ba sọrọ titi di akoko yi ni bi igbakeji gomina naa ko ṣe gbe ipe, ti ko si fesi si atẹjiṣẹ taa fi ṣọwọ sii.
Ṣaaju ni Gomina Akeredolu ti fi ọwọ osi juwe ile fun gbogbo awọn oluranlọwọ feto iroyin to n ṣiṣẹ lọfiisi Aiyedatiwa lọjọ kejila oṣu yi leyi ti ko fi si ẹnikẹni to le sọrọ lorukọ igbakeji gomina ọun.












