‘’Olóògbé Taiwo Akinkunmi tó ya àsìá Nàìjíríà ṣe gudugudu méje láti mú ìsọ̀kan bá orílẹ̀èdè wa’’

Oríṣun àwòrán, Taiwo Akinkunmi/Facebook
Ọ̀kan lára olùdarí ẹgbẹ́ Project One, Oluwarotimi Akinnadeju ,ti ní ìtàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò pé tí a kò bá sọ nípa ẹni tó ya àwòrán àsìá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ó tẹ̀síwájú pe asíà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣàlàyé nípa ìṣọ̀kan, àlàáfíà ati ìbágbépọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ó wá rọ àwọn ènìyàn tó ń jápa kúrò lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú orílẹ̀ wọn, nítorí pé àwọn kan ló tún ìlú tí wọ́n ń sálọ ṣe.
Ìdí niyii tí ó fi yẹ kì à máa gbé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lárugẹ níbi kíbi tí a bá wà.
Olùdarí àjọ ètò ìlánilọ́yẹ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Ọmọ̀wé Garba Abari ni ipa pàtàkì tí olóògbé Taiwo Akinkunmi kó nípa ìṣọ̀kan àti àlàáfíà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò ṣeé fọwọ́rọ́ sẹ́yìn .
Ó wá rọ gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti máa sọ ìrètí nù,bó tilẹ̀ jẹ pé a ń kojú àwọn ìpèníjà àti ìṣòro.
Ó tẹ̀síwájú pé kí gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fọwọ́sowọ́pọ̀ láti gbé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lárugẹ, kí a sì jẹ́ aṣojú rere fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà níbi kíbi tí wọ́n bá wà.
Ọ̀mọ̀wé Garba tún rọ gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti máa ṣe ìrántí àwọn asíwájú rere tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn sílẹ̀ fún ìdàgbàsókè àti ìsọkan orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.















