Ilé ẹjọ́ ju pásítọ̀ sí ẹ̀wọ̀n gbére fún bíbá ọmọdé mẹ́ta lò pọ̀, ó tún ṣẹ́ oyún fún wọn

Pasito Ajiboye Olayinka, wọ asọ funfun, o na ọwọ kan soke, eeyan pupa ni, o si mu ẹrẹ amohunbugbẹmu lọwọ keji

Oríṣun àwòrán, Ajiboye Olayinka

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara ti dajọ ẹwọn gbere fun pasitọ kan, Ajiboye Olayinka, fun jijẹbi ẹsun ifipa ba awọn ọmọde mẹta lo pọ, ati ṣiṣẹyun fun wọn lẹyin ibalopọ aitọ.

Olayinka ni olori ijọ Mission House of Divine Land of Joy and Prayer Ministry, nipinlẹ Kwara, lara awọn ọmọ to n wa si ṣọọṣi rẹ ni wọn lo ṣe aṣemaṣe pẹlu.

Ọjọ ori awọn ọmọbinrin naa ko ti i pe mejidinlogun bi kootu ṣe ṣalaye, eyi to tumọ si pe ọmọ kekere ṣi ni wọn labẹ ofin.

Inu ile ti wọn kọ fun pasitọ Olayinka ninu ọgba ṣọọṣi naa ni wọn lo ti n ba awọn ọmọde mẹta naa sun ki aṣiri too tu.

Bakan naa ni Kootu fidi ẹ mulẹ pe wọn tun ba ibọn lọwọ Pasitọ Olayinka pẹlu.

Pasito Ajiboye Olayinka, o wọsọ funfun, o n rẹrin-in, eeyan pupa ni.

Oríṣun àwòrán, Ajiboye Olayinka

Àkọlé àwòrán, Pasito Ajiboye Olayinka

Ki lo sele gan-an?

Ṣaaju ki Adajọ Hammed Gegele too da ẹjọ naa l'Ọjọruu, o ṣalaye pe Pasitọ Olayinka ti sọ awọn ọmọ naa di irinṣẹ ibalopọ nigbakugba to ba wu u.

Adajọ Gegele sọ pe iwadii fi han daju, pe pasitọ yii tun fipa mu wọn lati bura pẹlu Bibeli, pe wọn ko ni I sọ ohun toun n ṣe fun wọn fun ẹnikẹni.

"Ọkan lara awọn ọmọdebinrin naa ṣalaye bi olujẹjọ yii ṣe mu un lọ sile ibi ti wọn gbe ẹrọ amunawa (jẹnẹretọ) si, to si fipa ba oun lo pọ lẹyin to fi ororo iyasimimọ pa nnkan ọkunrin rẹ."

Adajọ Gegele tẹsiwaju, pe ọkan lara awọn ọmọbinrin naa tun ṣalaye bi olori ijọ wọn ṣe maa n ji I lẹyin ti iṣọ oru ba pari, ti yoo si ba a lo pọ leralera.

Kootu fi kun un pe awọn ọmọde naa sọ pe ibalopọ gbogbo igba yii di oyun fun awon kan ninu wọn.

Ati pe Pasitọ Olayinka fipa mu won lati ṣẹ awọn oyun naa bi wọn ṣe.

Wọn lo dunkooko iku mọ won pẹlu.

Kootu ṣapejuwe pasitọ Olayinka bii ẹni to fẹran lati maa ba ọmọde ṣe aṣemaṣe, to si tun n ni ibalopọ pẹlu ọpọ awọn obinrin miran.

Iru eeyan bẹẹ ko yẹ ni awujọ eeyan ni Adajọ Gegele wi.

Awọn ẹsun mẹjọ ti wọn fi kan Pasitọ Olayinka

Lọjọ kọkanla, oṣu Keji ọdun 2026 ti igbẹjọ waye ṣaaju, kootu gbọ ọrọ lẹnu olujẹjọ ati agbẹjọro rẹ ṣaaju idajọ yii.

Wọn kede awọn ẹsun mẹjọ ti wọn fi kan Pasitọ Olayinka lọjọ naa, awọn ni:

Igbimọpọ huwa ọdaran, nini ibalopọ aitọ pẹlu awọn ọmọde, ṣiṣẹ oyun lọna aitọ, nini nnkan ija lọwọ lọna aitọ atawọn ẹsun mi-in to lodi si ofin ẹtọ awọn ọmọde nipinlẹ Kwara.

Lasiko igbẹjọ naa, agbẹnusọ ijọba to lewaju, Issa Zakari, pe ẹlẹrii mejila jade lati jẹrii, o si ko awọn ẹri to daju to si tako pasitọ kalẹ niwaju adajọ.

Adajọ wọn ẹwọn gbere mẹta ọtọọtọ fun pasitọ

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Adajọ Gegele sọ pe ẹwọn gbere mẹta ọtọọtọ ni Pasitọ Olayinka yoo ṣe fun ẹsun biba ọmọde mẹta ti wọn ko si abẹ iṣọ rẹ lo pọ.

Fun ẹsun oyun ṣiṣẹ, kootu ju u si ẹwọn ọdun mẹrinla.

Fun ti ibọn "pump-action" ti wọn ba lọwọ rẹ, kootu paṣẹ pe ijọba apapọ ti gbẹsẹ le e.

Adajọ Gegele sọ pe Pasitọ Olayinka lo ipo rẹ bii olori ẹsin lati fi rẹ awọn ọmọdebinrin ti ọjọ ori wọn ko to nnkan kan jẹ.

O sọ wọn di irinṣẹ ibalopọ, o n mu wọn gun nigba to ba wu u, o si n ko ba aye ati irori wọn.

Gbogbo eyi ni kootu to pọ, ti Adajọ Gegele fi paṣẹ pe ẹwọn gbere ni Pasitọ Olayinka yoo ti lo iyoku aye rẹ.

O ni eyi yoo jẹ ẹkọ fun awọn eeyan ti won maa n lo ipo agbara ti wọn wa fi rẹ awọn eeyan abẹ wọn jẹ.