Ẹbí Alexx Ekubo sọ̀rọ̀ lórí irúfẹ́ jẹjẹrẹ kíndìnrín tó sokùnfa ikú rẹ̀

Alexx Ekubo n wo ẹgbẹ

Oríṣun àwòrán, @Alexxekubo/Instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Awọn ẹbi gbajumọ oṣere, Alex Ekubo ti sọro lori iku oṣere naa bi wọn ṣe kede pe ẹya aisan kindinrin tawọn oloyinbo n pe ni "metastatic kidney cancer" lo ṣekupa a.

Loju opo Instagram ni ẹbi rẹ ti kede iku rẹ ati ohun to ṣekupa naa lọjọru, ọjọ Kẹtala, oṣu Karun-un, ọdun 2026.

Atẹjade naa ni pẹlu ibanujẹ ni awọn fi kede iku oṣere naa ati pe o du emi rẹ gidigidi ki o to pada ki duniya ni odigba ni ile iwosan Evercare Hospital to wa ni ipinle Eko.

Ẹbi rẹ ni gbogbo bi Alexx Ekubo ṣe wa ninu irora lori aarẹ lo n ni igbagbọ pe oun maa ri iwosan pẹlu ireti pe oun maa pada fi ọrọ oun ṣe awokọṣe fun ọmọ araye amọ ti iku pada ja a ni tan mọọn.

Wọn wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati fun awọn laaye lati ṣọfọ ẹni wọn to papoda, ki wọn si maa fi adura ranṣẹ ki Eledumare tẹ Alexx Ekubo si afẹfe rere.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọn maa kede bi eto isinku rẹ ṣe maa waye lọjọ iwaju, ti wọn si tun dupẹ lọwọ awọn eeyan fun gbogbo adura ati aduroti ti wọn ṣe fun Alexx lati igba to ti jade laye.

Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa jẹjẹrẹ kíndìnrín, àìsàn

Aworan Kindinrin to bajẹ ati Alex Ekubo

Ọkan lara awọn ẹya ara to ṣe pataki si wiwa laye eeyan ni kindinrin jẹ.

Bi iroyin iku oṣere tiata Alex Ekubo ti jade ni irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, tawọn kan si n sọ pe aisan jẹjẹrẹ kindinrin ni o sokunfa iku rẹ bi o tilẹ jẹ pe a ko le fi eyi mulẹ.

Lati igba naa ni ọpọ eeyan ti n wadii nipa ohun ti jẹjẹjẹ kindinrin jẹ gan-an.

Bakan naa ni wọn fẹ mọ awọn ohun to n se okunfa aisan jẹjẹrẹ kindinrin, bawo la se le dena rẹ, awọn ami idamọ rẹ atawọn itọju to wa nilẹ, ti ẹmi ko fi ni bọ.

Idi ree ti BBC News Yoruba se se akojọpọ iroyin yii lati seto ilanilọyẹ nipa ọpọ ohun to yẹ ka mọ nipa arun jẹjẹrẹ Kindinrin, ka le dena rẹ.

Alex Ekubo fi ọwọ sori, o n rẹrin-in, o kọ oju si ẹgbẹ

Oríṣun àwòrán, Alex Ekubo/Instagram

Ki ni aisan jẹjẹrẹ kindinrin?

Aisan jẹjẹrẹ kindinrin maa n ṣe eeyan nigba ti awọn sẹẹli aisan jẹjẹrẹ ba bẹrẹ si ni pọ ninu kindinrin eeyan.

Kindinrin jẹ ẹya ara to ṣe pataki nitori ohun lo maa n ṣe ayẹwo ẹjẹ lara eeyan, to maa n jẹ ki awọn omi ara wa bo ṣe yẹ, to si maa n gbọn awọn ohun ti ko da lara danu.

Amọ kindinrin ko ni le ṣe awọn ojuṣe yii nigba ti jẹjẹrẹ inu kindinrin ba n ba eeyan finra.

Aisan jẹjerẹ maa n ṣe eeyan nigba ti awọn inu kindinrin ba n dagba ju bi o ṣe yẹ lọ, to si le ṣe akoba fun kindinrin mejeeji to maa n wa lara eeyan.

Ẹwẹ, "Metastatic kidney cancer" tawọn ẹbi Alex Ekubo sọ pe ohun lo ṣokunfa iku rẹ jẹ jẹjẹrẹ kindinrin to maa n tan de gbogbo awọn ẹya ara mii.

Bi apẹẹrẹ, jẹjẹrẹ le tan lati kindinrin wọ inu ọfun, ti wọn si maa ka a si jẹjẹrẹ kindinrin. Awọn jẹjẹrẹ kindinrin maa n tan ju ara wọn lọ.

Ki lo n fa jẹjẹrẹ kindinrin atawọn ami apẹẹrẹ rẹ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aisan jẹjẹrẹ kindinrin maa b saba waye nigba ti ayipada ba de ba awọn sẹẹli to wa ninu kindinrin eeyan.

Ohun kan to buru nibẹ ni pe awọn ayipada yii le waye lai si idi kan pato, bẹẹ naa si ni awọn nnkan to le ṣokunfa rẹ naa wa.

Bi o tilẹ jẹ pe iwadii ko i tii fidi rẹ mulẹ pe ohun kan pato lo n fa a, lara awọn nnkan to le fa jẹjẹrẹ kindinrin gẹgẹ bo ṣe wa loju opo ayelujara ileeṣẹ ilera Cleveland Clinic ni ọjọ ori.

Bi eeyan ṣe n dagba si ni ayipada n ba awọn ẹya ara eeyan naa, to si ṣeeṣe ki ayipada ba awọn sẹẹli to wa ninu kindinrin naa, ki wọn si dagba ju bo ṣe yẹ lo.

Awọn nnkan mii ti wọn ni o le fa jẹjẹrẹ kindinrin ni siga mimu tabi fifa awoọn eefin mii simu, apọju oogun lati fi ṣe imudoro kindinrin, nini aisan ẹjẹ ruru, ara asanju ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lara awọn ami apẹẹrẹ ti eeyan le maa ri ni ki ẹjẹ maa wa niu itọ, ki o maa rẹ eeyan ni gbogbo igba, ki iba maa ṣe eeyan ni gbogbo igba.

Awọn nnkan mii ti ẹni to ba ni jẹjẹrẹ kindinrin tun le maa ri ni ki wọn ma le jẹun daadaa, ẹyin ati ẹgbẹ riro, ki eeyan maa sadede ru.

Aworan ẹya ara to ni aisan jẹjẹrẹ Kindinrin

Oríṣun àwòrán, Cancer Treatment centre

Ṣe jẹjẹrẹ kindinrin ṣe e tọju?

Gẹgẹ bi gbogbo awọn aisan jẹjẹrẹ mii, itọju jẹjẹrẹ kindinrin maa n da lori bi wọn ba ṣe tete mọ nipa rẹ si.

Ti wọn ba tete ṣawari kindinrin nigba to ba wa ni ipele akọkọ, o ṣeeṣe lati tete ṣe itọju rẹ bii ṣiṣe iṣẹ abẹ, lilo imọ ablation eyi to tumọ si lilo ohun gbigbona tabi tutu lati fi ba awọn sẹẹli to ni jẹjẹrẹ.

Bakan naa ni wọn le ge lara kindinrin ti sẹẹli to ni jẹjẹrẹ n dagba lara rẹ tabi ki wọn yọ odidi kinrin naa danu to ba jẹ pe gige lara rẹ ko ni tan iṣoro naa.

Ajọ National Cancer Institute ni orile ede Amẹrika fidi rẹ mulẹ ida mẹtadinlọgọrin (77%) awọn eeyan to ni aisan jẹjẹrẹ kindinrin ni wọn ṣi lo ọdun marun-un sii, o kere tan, lẹyin ti wọn fidi rẹ mulẹ pe wọn ni aisan naa.

Didena aisan jẹjẹrẹ kindinrin

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iwosan Mayo Clinic ṣe s.o loju opo wọn, ko si ọna pato ti eeyan le fi dena jẹjẹrẹ kindinrin, awọn ohun ti wọn la kalẹ ni:

  • jijẹ awọn ounjẹ to dara
  • jijẹ eso ati awoọn ẹfọ daadaa
  • Ṣiṣe ere idaraya ni gbogbo igba
  • Jijina si mimu ọti ati siga
  • Didena ara asanju

Wo àìsàn tó pa Alex Ekubo, gbajúmọ̀ òṣèré lẹ́ni ogójì ọdún àti kókó méje nípa ìtàn ayé rẹ̀

Oloogbe Alex Ekubo wọ asọ kootu dudu, o fi igo dudu soju

Oríṣun àwòrán, AlexEkubo/ Facebook

Gbajugbaja oṣere tiata ọmọ Naijria kan, Alex Ekubo, ti jade laye lẹni ogoji ọdun (40).

Ojiji ni iroyin iku naa gbode nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kejila, oṣu Karun-un ọdun 2026.

Bi iroyin iku naa ṣe n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi, ti wọn ko fẹ tete gbagbọ pe arẹwa ọkunrin naa ti jade laye, ni awọn oṣere lede oyinbo, ede Yoruba ati ede Igbo bẹrẹ si I kẹdun iku naa loju opo wọn.

Eyi lo mu ọpọ eeyan gba pe loootọ ni Alex Ekubo, ọdọmọde elere tiata naa ti di ara ọrun.

Lara awọn oṣere to fidi iku naa mulẹ loju opo ayelujara wọn ni Funke Akindele, Bolanle Ninalowo ati Godwin Nnadiekwe.

Ki lo pa Alex Ekubo?

Bo tilẹ jẹ pe ko ti I sẹni to fidi iku pato to pa gbajumọ oṣere naa mulẹ, iroyin to gbode ju ni pe Jẹjẹrẹ inu Kindinrin lo mu Alex Ekubo lọ.

Bakan naa ni awọn ẹka iroyin kan ṣalaye pe aisan ranpẹ lo ṣe oloogbe naa ko too jade laye.

Ṣugbọn akọsilẹ fi han pe o ti n pẹ ọdun meji lọ ti Oloogbe Alex ti gbe ohunkojun jade loju opo ayelujara rẹ gbẹyin.

Eyi ni ọpọ si fi n sọ pe awon asiko ti ara rẹ ko ya ni oṣere naa ko raye lati gbe ohun tuntun si oju opo naa.

Aarin kan ninu ọdun 2025 to kọja si ni a gbọ pe aarẹ ti wọn lo ṣe Oloogbe Ekubo lagbara si i.

Ẹnikan ti ko darukọ rẹ lara awọn to sunmọ oṣere naa, ṣalaye pe ọjọ Aje ni wọn tun sare gbe Alex lọ sileewosan, lẹyin ti aarẹ naa le si i.

O ni afẹfẹ Oxygen ni oṣere naa fi n mi ko too dagbere faye lọjọ Iṣẹgun.

Oloogbe Alex Ekubo wọ asọ shaati dudu, o fi nnkan sọrun, o lo aago sọwọ

Oríṣun àwòrán, AlexEkubo/ Facebook

Koko meje nipa itan aye gbajumọ osere, Alex Ekubo to di oloogbe

Alexx Ekubo (Alexx Ekubo-Okwaraeke), oṣere tiata ni wọn bi lọjọ kẹwaa oṣu Kẹrin ọdun 1986.

Portharcourt, nipinlẹ Rivers ni wọn ti bi I, amọ ọmọ ilu Arochukwu, nipinlẹ Abia ni.

Ẹkọ nipa imọ ofin ni Alex kọ ni Yunifasiti ilu Calabar ni ipinlẹ Cross Rivers.

O si tun gba Diploma ninu imọ nipa iṣẹ iroyin nile ẹkọ gbogboniṣe ilu Calabar bakan naa.

Ere oniṣe kan ti wọn pe ni Weekend Getaway lo fi Oloogbe Alex han fun aye ri .

Lẹyin eyi, aimọye sinima ni Alex ti kopa ninu wọn, eyi ti ko lonka.

Bakan naa, Alex Ekubo ti gba ọpọ ami ẹyẹ titi to fi mọ oṣere to dangajia julọ nibi ka ṣe amugbalẹgbẹẹ osere, eyi to waye ni ọdun 2013.

Ni osu kẹjọ ọdun2021 ni ariwo ta pe Alex ati aya afẹsọna rẹ, Fancy Acholonu ti tuka eyi to ya ọpọ eeyan lẹnu.

Lẹyin eyi, o kọle to si ko lọ sile rẹ amọ lati igba naa, a ko gbọ pe Alex fẹ iyawo tabi bimọ ko to fi aye silẹ.