Dókítà sọ pé màá lo òògùn fún ọdún márùn-ún, mi ò sì gbọdọ̀ bímọ́ – Tope Osoba
Gbajumọ oṣerebinrin, Temitope Osoba ti ṣalaye iru aisan to n ṣe e , ati bi igbeaye rẹ ṣe n lọ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Yoruba, Arabinrin Osoba sọ pe oun ji ni owurọ ọjọ kan, ni oun ṣakiyesi koro kan nibi ọyan oun.
"Ọjọ yẹn, mo kan ṣa n fi ọwọ kan ara mi, ni mo ri pe kinikan ti ko tobi ju koro ẹwa lọ.
"Mo lọ si ileewosan aladani kan, nibi ti dokita ti sọ fun mi pe, ko si ewu."
O ni dokita naa sọ pe boya nitori oun ko ti i bimọ ri, ti oun ko si ti i fun ọmọ lọyan ri, lo fa a.
Arabinrin Osoba sọ pe oun pada sile lootọ, amọ gbogbo igba ni oun n yẹ koro naa wo.
"Nigba to ya, o n tobi si i. Ara mi ko si balẹ mọ pẹlu rẹ."

Oríṣun àwòrán, Others
Aibalẹ ọkan yii lo mu Temitope Osoba gbera lọ si ibudo ayẹwo lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ.
Nibẹ ni wọn ti sọ fun pe koko ni, eyi ti wọn n pe ni lump ni ede Gẹẹsi.
O ni wọn yọ koko naa nileewosan, ti oun si bẹrẹ si ni gbe igbe aye ọtun.
"A ṣe wọn ti yẹ ẹ wo nile iwosan ijọba, wọn si ri i pe aarun jẹjẹrẹ wa ninu koko naa.
Temitope ṣalaye pe ọjọ naa jẹ ọjọ ti ko dara rara, "nitori mi o ni igbagbọ pe iru nnkan bẹẹ le wa lara mi."
O ni ibanujẹ lo jẹ, nitori oun bẹrẹ si ni kọminu pe ṣe ibi ti oun yoo pari gbogbo laalaa oun si re e .
"Mo ronu pe ṣe wọn o ge ọyan mi ni, tabi maa ku?"
Oṣerebinrin naa sọ pe bi oun ṣe bẹrẹ si ni gbadura niyẹn, pe ki Ọlọrun ṣaanu oun.
Bakan naa lo sọ pe awọn dokita ṣe ayẹwo alaworan mii, ti wọn n pe ni 'CT Scan' fun oun, lati mọ ibi ti aarun naa ti ran de ninu ara rẹ.
Ayẹwo naa lo fihan pe ko si ohunkohun nibẹ, bi ko sẹ awọn ralẹ-ralẹ nibi to ti kọkọ ri koro.
Ṣe ẹ o gbagbe pe o ti kọkọ ṣe iṣẹ abẹ kan lati yọ koro naa? O ni dokita sọ pe oun yoo 'se iṣẹ abẹ miran, ṣugbọn wọn o ni ge ọyan rẹ, bẹẹ ni ko ni ṣe 'chemotherapy".
Owo ti awọn dokita ni ko san an pọ debi pe, o ni lati bẹbẹ si tọrọ owo lọwọ awọn akẹẹgbẹ rẹ.
Oṣerebinrin, Foluke Daramola, lo pada ba a ṣe agbatẹru ikowojọ lori ayelujara, ti awọn eeyan fi bẹrẹ si ni da owo jọ fun, paapaa lẹyin to gbe aworan ati fidio rẹ sori ayelujara.
Ikowojọ naa lo ran an lọwọ to fi bọ lọwọ aarun jẹjẹrẹ ọyan.
Ki lo n fa aarun jẹjẹrẹ ọyan?
Aarun jẹjẹrẹ ọyan jẹ ọkan lara aarun jẹjẹrẹ to wọpọ julọ jakejado agbaye, to si saba maa n fa iku awọn obinrin jakejado agbaye.
Onimọ Sayẹnsi kan, Dokita Jingmei Li, sọ pe bi aarun jẹjẹrẹ ọyan se n fi ojoojumọ gbilẹ si, la lee so mọ ilana igbe aye wa ati awọn ohun to rọ mọ ilana ibimọ.
"Lara rẹ la ti ri iwa jijẹ awọn ounjẹ afaralokun taa mọ si Cabonhydrate eyi to maa n jẹ ka sanra asanju, ati minu ọti lile ni amuju."
Koda, iwadi tun fidi rẹ mulẹ pe, ọmọ bibi maa n mu adinku ba nini arun jẹjẹrẹ ọyan lọjọ iwaju, bẹẹ si awọn obinrin to ba loyun akọni, ti osu rẹ si pe titi to fi bimọ, ko to pe ẹni ọdun marundinlogoji, lee ma ni arun jẹjẹrẹ ọyan lọjọ iwaju.
Idena arun jẹjẹrẹ ọyan
Dokita Li ni bi o tilẹ jẹ pe owo tuulu lawujọ agbaye ti na lati se awọn oogun fun itọju awọn obinrin to ni arun jẹjẹrẹ ọyan, amọ o ni ohun to daa ni pe ka dena awọn obinrin lati ri arun naa.
"Ọpọ ohun la ti se nidi ipese oogun ati tawọn ileesẹ apoogun si n pawo wọle lojoojumọ amọ mo fẹ se nkankan lati tiẹ fi dena arun jẹjẹrẹ ọyan, nibayii ta n gba owo lọwọ orilẹede Singapore."
O ni ayẹwo ọyan le ṣawari arun jẹjẹrẹ ọyan taa ba ri ami miran pe arun yi ti wọnu agọ ara, ti koro ọyan naa ko si to ibu eso bluberry.
Lii ni " Ko jẹ ka kọlu awọn ọmọ ogun arun naa nigba ti ọta si wa ni kekere." O ni idaniloju wa pe ti itọju to yanranti ba wa ni akoko yii, ida ọgọrin ninu ọgọrun awsn obinrin to ni arun jẹjẹrẹ ọyan ni yoo lo kọja ọdun mẹẹdogun si lẹyin ti wọn kede pe wọn ni arun yii.
Amọ, o ni ti koro ọyan ọhun ba ti tobi to eso ọsan lasiko ti wọn kofiri ninu agọ ara, o seese ki ẹmi ẹni bẹẹ ma gun to ọdun mẹẹdogun mọ lẹyin ikede eyi.
"Aarun jẹjẹrẹ kọọkan lo yatọ si ara wọn, ta ba ni ẹgbẹrun mẹwa arun jẹjẹrẹ, a nilo itọju lọna ẹgbẹrun mẹwa, idi si ree ti mo se n pariwo pe ka tete sawari arun jẹjẹrẹ lọna abayọ, dipo ka maa wa itọju fun-un."



