Wo bí o ṣe lè ṣe é tí ebi àti òuǹgbẹ kò fi ní mú ọ lásìkò ààwẹ̀ Ramadan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn Musulumi kaakiri agbaye ti n gbaradi lati bẹrẹ awẹ ni oṣu to n bọ yii.
Awẹ Ramadan jẹ ọkan gboogi ninu opo ẹsin Islam.
Ni oṣu to n bọ yii, ọpọ Musulumi ni yoo yago fun ounjẹ jijẹ ati omi mimu fun awọn asiko kan
O ṣe pataki pe ki ẹ mọ awọn anfani ilera to wa ninu yiyago fun ounjẹ ati omi fun igba pipẹ, igbesẹ yii nira fun awọn eeyan kan pupọ.
Awọn mii ni wọn ma n koju rirẹ ni ago ara wọn lasiko awẹ nitori wọn ko jẹun ni awọn asiko yii.
Bakan naa, awẹ tun nira fun awọn eeyan to ba ni aisan kan tabi omiran paapa awọn to ba ni ẹjẹ iru riru tabi itọ suga.
A ti ṣeto awọn oriṣiriṣi adanilẹkọọ ti awọn onimọ pese fun wa ti yoo pese iranlọwọ fun ọ gẹgẹ bii Musulumi lati gbaawẹ ni ilana ti ko ni ṣe akoba fun ilera rẹ.
BBC ba ọpọ eeyan sọrọ lati mọ nipa bi wọn se n gberọ lati lo awẹ ti ọdun yii.
Eyi ni awọn ilana ti onimọ ṣe agbekalẹ lori awẹ ti ko ni ṣe akoba fun ilera.
Jijẹ saari ni ọna mẹta

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Suhoor ni ounjẹ akọkọ fun eeyan to ba n gba awẹ.
Nnkan to ba jẹ lasiko yii ni yoo sọ bi ebi yooṣe pa ẹ to tabi bi yoo ṣe rẹ ọ to lasiko awẹ ọjọ naa.
Onimọ nipa ounjẹ Fadi Abbas ni "Lasiko Saari, ri pe o jẹ ounjẹ to ni ida aadọrin omi ninu."
Gẹgẹ bi o ṣe ṣalaye, jijẹ saari naa pin si ọna mẹta, ti isẹju marun un si gbọdọ wa laarin wọn.
"Ohun eso ni ki o fi bẹrẹ saari; bi cucumber, lettuce. Ri daju pe iyọ ko pọ ju ninu awọn ounjẹ naa.
"Nitori to ba jọ iyọ ju, ara rẹ yoo nilo ọpọ omi lẹyin wakati diẹ.
"Ipele keji ni jijẹ awọn ounjẹ to ni suga ati awọn eso to ni suga ninu."
Bi o ba fẹ, o le po awọn eso yii pọ, ko si da mu. Ikẹta ni mimu ọpọ omi.
Ajọ eleto ilera UK gba ni imọran pe ki alawẹ ma mu tii tabi kọfii lasiko saari nitori awọn wọnyi yoo jẹ ki ara bere fun ọpọ omi lẹyin wakati diẹ
Ki ni ko fi ja awẹ rẹ?
Jijẹ ounjẹ lasiko awẹ da lori bi apo mọlẹbi kọọkan ba ṣe ri lasiko awẹ.
Lasiko awẹ, ọpọ eeyan lo ma n pin ounjẹ pẹlu awọn mọlẹbi wọn ati awọn to wa ni agbegbe wọn.
Eyi lo maa n fa ki ọpọ ounjẹ po lasiko ti wọn ba fẹ ṣinu, ti ọpọ eeyan yoo si ni anfani si orisirisi ounjẹ lati jẹ.
Eyi tu mọ si pe eeyan le jẹ ju ohun to nilo lasiko isinu awẹ lai mọ ewu to wa nibẹ.
Jijẹ oriṣiriṣi ounjẹ lasiko iṣinu le fa inu riro ati awọn ijamba mii.
Iṣoro yii le pọ si fun awọn eeyan to ba ni ifunpa giga tabi itọ ṣuga.
Abbas ni awọn ọjọ akọkọ awẹ lo le ju nitori o jẹ ohun ojiji si ago ara.
Abbas síwaju si pe, nipa jijẹ saari, ounjẹ iṣinu pin si ipele mẹta, ti wọn si gbọdọ jẹ laarin iṣẹju mẹfa si ara wọn.
Fadi Abbas ni, "O dara ki o ja awẹ rẹ pẹlu omi. O gbọdọ jokoo mu omi yii."
Asiko to dara ju lati se ere idaraya
Ọpọ eeyan gbagbọ pe irun Tarawih ti to fun ṣiṣe ere idaraya lati le ọra kuro lara ṣugbọn eyi ko to rara.
Yatọ si irun kiki, o ni awọn ere idaraya miiran ti yoo se ọpọ anfani, Dokita onimọ nipa ounjẹ to n ṣe araloore, Ison Quanz ṣalaye.
"Ki eeyan to bẹrẹ eyi keyi ere idaraya, o gbọdọ waye lẹyin wakati mẹta ti eeyan ba jẹ saari tabi isisu tan.
"M saare lọ se ere idaraya ni awọn ọjọ akọkọ awẹ, ma se wọn ni diẹdiẹ.
Bakan naa lo tun gba awọn eeyan ni amọran pe ki wọn yago fun mimu ohun aladun, to ni ọpọ suga.
"E mu ohun to ba ọjọ ori mu, o se koko".















