Èyí ni bí Mohbad ṣe ní ìfarapa tó sọ ọ́ di èrò ọrùn

Aworan Ilerioluwa Aloba, ẹni ti ọpọ mọ si Mohbad

Oríṣun àwòrán, Instagram/iamMohbad

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ile-ẹjọ Majisireeti to gbe idajọ kalẹ lori iku Mohbad ti ṣalaye ohun pato to ṣokufa iku oloogbe naa.

Ninu iwe ti ile-ẹjọ gbe sita fun awọn akọroyin, lo ti han pe ninu oṣu Kẹsan an, ọdun 2023, Mohbad ati ọrẹ rẹ, Adeyemo Boluwatife, ti wọn pe ni Darosha, pẹlu Wunmi, iyawo Mohbad ati Primeboy to jẹ ọrẹ oloogbe, pẹlu dẹrẹba wọn Fedelis Esandor ati awọn mii lo tẹle Mohbad lọ si agbo orin ti Sobrekon gbe kalẹ ni Ikorodu.

Nigba ti wọn fẹ kuro, Primeboy gbiyanju lati da Mohbad duro nitori awọn ọmọ ita to wa ni agbegbe naa.

Ile-ẹjọ ni ọrọ naa bi Mohbad ninu, to si nawọ ẹsẹ si Primeboy ṣugbọn Primeboy ko ba ja pada.

"Bi Mohbad se n gba Primeboy ni ẹsẹ lo fi ọwọ gba gilaasi ọkọ, to si ya ọwọ rẹ ọtun, to si farapa.

Ọwọ rẹ bẹrẹ si ni ma wu, to si jẹ pe aimọsẹ nọọsi ti wọn pe ko wa tọju ọwọ jẹ ohun to ṣokunfa iku rẹ."

Iku Mohbad ti fa ọpọ rogbodiyan ati iwọde laarin awọn ọdọ Naijiria

Mohbad ti wọ́gilé ẹjọ́ tó pè tako Naira Marley ṣáájú ikú rẹ̀ - Ilé ẹjọ́

Aworan Mohbad, Naira Marley, Sam Larry ati Primeboy

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ile ẹjọ Magistrati to gbe idajọ kalẹ lori igbẹjọ gbajugbaja olorin to ti di oloogbe, Ilerioluwa Aloba, ẹni ti ọpọ mọ si Mohbad ṣalaye pe oloogbe naa ti wọgile ẹjọ to pe tako ọga rẹ, Abdulazeez Fashola, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Naira Marley ni ileeṣẹ ọlọpaa Ilasan to wa ni agbegbe Lekki ni ọjọ kẹjọ oṣu kẹwaa ọdun 2022 saaju ko to jade laye.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Eyi jẹ ọkan lara awọn idi pataki ti ile ẹjọ Magistrati to n jokoo ni agbegbe Yaba fi da Naira Marley ati awọn yooku lare pe ko lọwọ ninu iku Mohbad.

Ile ẹjọ tun tun da agbe orin larugẹ, Samson Balogun Eletu, ti wọn n pe ni Sam Larry, mọnija Mohbad tẹlẹ, Babatunde Opere ati Ibrahim Owodunni ti wọn n pe ni Primeboy lare pe wọn ko lọwọ ninu iku oloogbe naa.

Adajọ Ejiro Kubenje, ni awọn afurasi naa ko ni ẹjọ kankan lati jẹ lori iku Mohbad.

Iwe kan to kun fun amọran ofin eyi ti Babajide Martins tọwọbọ tẹ awọn akọroyin lọjọ Isẹgun, to si ṣafihan pe Mohbad ti wọgile ipe fun ẹjọ lọjọ kọkanla oṣu kẹwaa ọdun 2022, to si jẹ ko di mimọ pe awọn ti yanju awọ to wa laarin wọn, ti ko si ba ofin mu mọ pe ki awọn olujẹjọ si ma jẹjọ lori ohun to sẹlẹ labẹ ofin.

"A ko le gbe igbesẹ lori ohun ti oloogbe sọ nipa Naira Marley ni ileeṣẹ ọlọpaa to wa Ilasan lori ohun ti oju rẹ ni Ọjọ kẹjọ oṣu kẹwaa, ti eeyan si tun wọgile ipe rẹ ni Ọjọ kọkanla oṣu kẹwaa ọdun 2022, to si jẹ ko di mimọ pe awọn ti yanju awọ to wa laarin wọn."

Ilé-ẹjọ́ dájọ́ lórí ipa ti Naira Marley, Primeboy àti Sam Larry kó nínú ikú Mohbad

Sam Larry, Mohbad ati Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Others

Ile ẹjọ majisireeti to wa ni agbegbe Yaba nipinlẹ Eko, ti gbe idajọ kalẹ lori ipa ti Naira Marley, Sam Larry ati Primeboy, ko ninu iku Mohbad.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ni Onidajọ Ejiro Kubenje gbe idajọ naa kalẹ "ni ibamu pẹlu imọran ati alakalẹ lati ẹka eto idajọ nipinlẹ Eko.

Onidajo Kubenje sọ pe gbajugbaja akọrin takasufe, Abdulazeez Fashola, ti ọpọ mọ si Naira Marley, ko lọwọ si iku to pa Aloba IleriOluwa, ti awọn eeyan tun mọ si Mohbad, ti ko si ni ẹjọ lati jẹ lori iṣẹlẹ ọhun.

Yatọ si Naira Marley, ile ẹjọ tun da Balogun Samson eletu, ti ọpọ si Sam Larry, Owodunni Ibrahim, to tun n jẹ Primeboy, to fi mọ mọnija Mohbad nigba kan, Opere Babatunde, silẹ.

Ṣugbọn ṣa, ile ẹjọ ni wọn yoo foju nọọsi to tọju Mohbad, Feyisayo Ogedengbe, ati ẹnikan lara awọn ọrẹ Mohbad, Ayobami Sadiq, fun ẹsun ailakasi ati fifi ọwọ yẹpẹrẹ mu nnkan.

O ni eyi wa ni ibamu pẹlu abala 251 (e) ofin iwa ọdaran ti wọn gbe kalẹ nipinlẹ Eko lọdun 2015.

Ki lo ṣẹlẹ sẹyin?

Mohbad

Oríṣun àwòrán, Other

Lati ọdun 2023 ni Naira Marley, Sam Larry, ati awọn yooku ti n koju iwadii nitori ẹsun pe wọn fi iya jẹ oloogbe Mohbad nigba aye rẹ.

Mohbad ku ni ọjọ kejila, oṣu Kẹsan an , ọdun 2023 ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.

Iku ọdọmọde olorin naa ni o dun awọn ọmọ Naijiria gan an eleyii ti wọn si ti n pe fun idajọ ododo lori ohun to ṣe iku pa a.

Ọpọ lo si ti pe fun Naira Marley lati wi tẹnu rẹ latari wi pe ileeṣẹ rẹ Marlian records ni Mohbad wa tẹlẹ.

Latigba ti esi ayẹwo lati mọ iru iku to pa gbajugbaja olorin takasufee nni to ku lasiko ti ogo rẹ n buyọ, Ilerioluwa Alọba ti jade ni oriṣiriṣi awuyewuye ti n lọ kaakiri ori ikanni ayelujara.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ejo lọwọ ninu, bẹẹ lawọn miran n sọ pe boya nitori ti wọn ti tete sin oku naa ni esi ayẹwo ko ṣe iru iku to pa Ilerioluwa ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Mohbad.

Oriṣiriṣi awuyewuye to n lọ nigboro yii lo mu ki BBC YORUBA kan si baba oloogbe naa, Ọgbẹni Joseph Alọba lati mọ boya esi ayẹwo ọhun tẹẹ lọrun tabi ko tẹẹ lọrun.

Ṣugbọn nigba to n ṣalaye, Ọgbẹni Joseph Alọba jẹ ko di mimọ pe oun ko nigbagbọ kankan ninu esi ayẹwo naa ti wọn gbe jade. Eyi si lo mu ki ẹbi oloogbe ṣe ayẹwo miran.

Ta a ni Naira Marley jẹ gan an?

Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Other

Azeez Fashola ti inagijẹ rẹ lori itage n jẹ Naira Marley jẹ olorin Naijiria to ṣẹṣẹ n goke.

Naira Marley kii sii jina si ibi ti awuyewuye ba ti n ṣẹlẹ.

Ọpọ ni ko mọ orukọ abisọ rẹ tootọ.

Diẹ lara ohun ti ẹ le ma mọ nipa olorin to tun ti n di gbaju gbaja latari ẹsun ti wọn fi kan an niyii.

Ojọ kẹwaa, oṣu Karun un, ọdun 1991 ni wọn bi i to si dagba ni agbegbe Agege ni ipinlẹ Eko.

Ni ọmọ ọdun mọkanla lo ko lọ si ilẹ UK lati maa gbe nibẹ

O ti di ọmọ ilu ọba to ni iwe igbe'lu labẹ ofin bayii bẹẹ lo si tun jẹ ọmọ Naijiria nipa ìbí.

Iṣẹ atọkun ariya tabi ayẹyẹ (MC) lo n ṣe tẹlẹ ko to bẹrẹ orin kikọ.

Ohun si lo ni ileeṣẹ to n gbe orin Mohbad jade ki wahala to o ṣẹlẹ laarin wọn.