Agbábọ́ọ̀lù Naijiria jábọ́ lórí àjàkẹ́ta ilé ní Uganda, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí nípa ikú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Vipers Sports Club, Uganda
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Uganda ti bẹrẹ iwadii lori iku to pa Abubakar Lawal, agbabọọlu ọmọ Naijiria ti wọn lo jabọ lati ori ajakẹta ile itaja Voicemall Shopping Arcade, ni Uganda.
Ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji ọdun 2025 ni Abubakar, ọmọ ipinlẹ Sokoto, jade laye gẹgẹ bi ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, Vipers Sports Club, Uganda, ṣe kede.
Gẹgẹ bi atẹjade awọn ọlọpaa Uganda ṣe wi, wọn ni Oloogbe Abubakar de si ile itaja naa laaarọ ọjọ Aje pẹlu ọkọ rẹ.
Ọrẹ rẹ obinrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Omary Naima, ọmọ orilẹede Tanzania ti wọn lo ti gba yara sibẹ ni wọn ni o wa lọ sibi to ti kagbako iku.
Ogunjọ oṣu Keji yii ni a gbọ pe obinrin naa ti wa nibi to de si ọhun.
Báwo ni Abubakar ṣe jábọ́ tó gbabẹ̀ kú?

Oríṣun àwòrán, Vipers Sports Club, Uganda
Gẹgẹ bi Naima ṣe wi, o ni oun fi Abubakar sinu yaara nigba to n po tii lọwọ ni, oun si lọ sibudo ere idaraya kan ninu ile itaja naa.
O ni nigba to di nnkan bii aago mẹjọ owurọ ni oun gbọ pe Abubakar Lawal ṣubu lati ori oke ile.
Wọn sare gbe e lọ sile iwosan Entebbe Referral, ibẹ ni wọn si ti fidi rẹ mulẹ pe agbabọọlu ọmo Naijiria naa ti ku.
Bi awọn ọlọpaa ṣe wi, igbiyanju ti bẹrẹ lati ri fọn-an-ran iṣẹlẹ iku ọhun, wọn si lawọn yoo maa fi to aye leti bo ba ṣe n lọ.
Ta a ni Oloogbe Abubakar Lawal?

Oríṣun àwòrán, Vipers Sports Club, Uganda
Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹsan-an ọdun 1995 ni wọn bi Abubakar Lawal, ọmọ ipinlẹ Sokoto ni.
Agbabọọlu to n ṣe daadaa latigba to ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu AS Kigali, ni Rwanda.
O ti figba kan ba ẹgbẹ agbabọọlu Kano Pillars, ni Naijiria naa gba bọọlu ri.
Ẹgbẹ agbabọọlu Vipers Sports Club ni Uganda lo wa ti ọlọjọ fi de.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ agbabọọlu naa fi kede iku rẹ ni wọn ti sọ pe wọn ti ṣe oku rẹ lọjọ si ile igbokusi fun ayẹwo nipa ohun to pa a.
Bẹẹ ni wọn kede pe awọn yoo maa sọ bi eto isinku agbabọọlu naa yoo ṣe lọ.













