Lagos Abeokuta Accident: Àwọn ọ̀dọ́ dáná sun tírélà Dangote tó sọ èèyàn méje dèrò ọ̀run

Aworan ọkọ Dangote ti wọn dana sun

Oríṣun àwòrán, Google

Ijamba ọkọ tirela Dangote kan ati awọn ọkọ akero meji to waye ni opopona maroṣẹ Eko si Abeoukuta ti mu ẹmi eniyan meje lọ, ti eniyan mewa si farapa.

Fun idi eyi,awọn aradugbọ towa lẹgbẹ ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye iyẹn Old Toll Gate ni Ọta ti dana sun ọkọ tirela Dangote naa.

Ọkunrin agbalagba meji,obinrin mẹta, ọmọdekunrin kan ati ọmọdebinrin kan lawọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ BBC ri gba lọdọ ọga ajọ ẹsọ oju popo nipinlẹ Ogun, Clement Oladele,ijamba ọkọ naa waye ni ọjọAbamẹta ni nkan bi ago mọkanla aabọ owurọ.

Oladele ṣalaye pe are asaju lo ṣokunfa ijamba naa ati pe ọpọ ẹmi lo ti lọ ni agbegbe ibi ti ijamba naa ti waye .

aaaa

Oríṣun àwòrán, FRSC

Aworan awọn agbofinro nibi ijamba ọkọ ti o waye

Oríṣun àwòrán, FRSC

O ni laarin ọdun marun un tokọja, o to eeyan ogoji to ti ko agbako iku nitori ijamba ọkọ ni ibẹ.

O rọ awọn ọlọkọ nla lati ṣe pẹlẹ ki wọn yago lati ma sare apaajude ki iruijamba bayi ma ba waye.