Makinde, Olubadan fèsì lórí ẹ̀sùn Fayose pé ìjọba Oyo fẹ́ rọ Olubadan Ladoja lóyè

Gomina Seyi Makinde lapa osi, Olubadan Rashidi Ladoja lo wa laaarin, nigba ti Ayo Fayose wa lapa ọtun.

Oríṣun àwòrán, Gov. Seyi Makinde/ Facebook/Olubadan Rashidi Ladoja/ Facebook/ Ayo Fayose/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina tẹ́lẹ̀ ni ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayoṣe, ke sita nirọlẹ ọjọ Aiku ana, pe Gomina Makinde n pete ati yọ Olubadan Rashidi Ladoja kuro nipo ọba.

Oju opo ayelujara X rẹ ni Fayose ti ke gbajare naa sita lánàá.

Fayose ni oun ri i gbọ nibi to ti dájú ṣáká, pe Gomina Seyi Makinde n pete ati yọ Olubadan kuro nipo ọba ninu ọsẹ yii.

Fayose kọ ọ sibẹ pe ẹsun ti Makinde fẹ fi kan Olubadan Ladoja ni pe ọba naa ko yọju sibi ti Gomina ti fi awọn oloye Ibadan mẹta jọba lọsẹ to lọ.

"Ń wo maa wo Ṣigidi Seyi Makinde to fẹ ṣere ẹtẹ niran"

O ni awon ẹsun miran tun ti wa nilẹ ti Makinde fẹ ni ki Olubadan dahun si, ti yoo si gbabẹ yọ ọ danu bii jìgá kuro lori àpèèrè ọba.

Gomina Ekiti tẹlẹ naa sọ pe oun yoo maa wo Ṣigidi Seyi Makinde to fẹ ṣere ẹtẹ niran.

Bi Fayose ṣe sọrọ naa ni oriṣiiriṣii ero ti n jade nipa rẹ lori ayelujara.

Ọpọ eeyan lo fi oju adarugudu silẹ wo o, wọn ni ohun ti ko ri bẹẹ ni Fayose n gbe kiri.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Gomina Makinde fèsì

Ko pẹ rara ti Gomina Seyi Makinde ti Fayose fẹsun kan fi dahun, ọjọ ti Ayodele sọrọ naa ni ijọba ipinlẹ Oyo da esi rẹ pada fun un.

Kọmiṣanna eto Iroyin ati Ọgbọn inu nipinlẹ Oyo, Ọmọọba Dotun Oyelade, ṣalaye pe ijọba ko gbiyanju rẹ, sọ ọ tabi gbe igbesẹ iyọnipo lori Ladoja ri.

Oyelade sọ pe:

" Ni bayii, awọn eeyan Naijiria naa mọ ẹni, ati iru ohun ti wọn le gbagbọ, paapaa nigba ti ikede ba ti ibi kan pato wa.

"Ijọba ipinlẹ Oyo ko gbiyanju rẹ, ba ẹnikẹni sọ ọ tabi gbe igbesẹ lori iru nnkan bẹẹ ri.

"O gbọdọ ni idi otitọ kan ti ijọba fi n gbe igbesẹ kọọkan ti wọn ba n gbe, niṣe lo si yẹ ki eyi to n ti ọdọ agbẹnusọ alatako ẹgbẹ wa ti ofin ko mọ wa yii tete bọ si ààtàn to ti wa."

Bẹẹ ni Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Oyo naa wi lori ibosi Fayose.

O ni oṣelu to ba ti kun fun akitiyan bii eyi lo maa n bi irọ ati agbelẹrọ, to si maa n sọ ijọba awaarawa di awẹ́wa.

Ahesọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni, yoo buru jai bi ko ba jẹ ahesọ - Olubadan

Nigba to n fesi si ọrọ to ti gbilẹ lori ayelujara naa, Akọwe iroyin fun Ọba Ladoja; Adeola Oloko, ṣapejuwe ohun ti Fayose sọ naa bii ahesọ ọrọ ti ko lẹsẹ nilẹ rara.

Oloko ṣalaye lọjọ Aiku naa, pe ko si ija kankan laaarin Gomina Makinde ati Olubadan Ladoja, to le fa ohun ti Fayose sọ yii.

"Yoo ti lọ buru ju bi ki i ba ṣe ahesọ.

"Emi o ri idi kankan ti aigbọra ẹni ye yoo fi wa laaarin Gomina Makinde ati Olubadan ilẹ Ibadan."

Bẹẹ ni Oluranlọwọ Olubadan lori ikede naa wi.

Bi awọn igun mejeeji ti ọrọ yii kan ti ṣe sọrọ ni ọpọ eeyan ti n sọ pe Ayo Fayose ki yoo le wi nnkan kan mọ bayii.

Wọn ni ero rẹ ko ni i ṣẹ mọ pẹlu.

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to lọ ni Gomina Makinde sọ awọn agba oye Ibadan mẹta di ọba alaye nipinlẹ Oyo, bo tilẹ jẹ pe awọn to sọ di ọba naa ko yọju sibi ayẹyẹ naa rara.

Awọn ọba naa sọ pe awon 'busy' nigba naa ni

Olubadan Ladoja to yẹ ko wa nibẹ pẹlu ko yọju sibi ayẹyẹ to waye ni Gbọngan Mapo niluu Ibadan naa.

Eyi to fa a ti iroyin fi jade nigba naa, pe aarin Olubadan Ladoja ati Gomina Seyi Makinde ti daru.

Ṣugbọn awon mejeeji sọrọ nigba naa pe ko sija kankan laaarin awọn.

Lẹyin rẹ ni Ayo Fayose jade bayii, pe Makinde fẹ yọ Olubadan Ladoja nipo nitori ọba naa ko yọju sibi ayẹyẹ igbade oloye mẹta.