Obìnrin ti torí mi darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ tíátà rí-Ogogo

Oríṣun àwòrán, Taiwo Hassan/ Facebook
Gbajugbaja oṣere tiata ni Alaaji Taiwo Hassan ti awọn eeyan mọ si Ogogo ninu ere Yoruba, odu ti ki i ṣe aimọ fun oloko ni.
Lori eto tẹlifiṣan kan, Oyimọmọ, ni Ogogo ti ṣalaye nipa igbesi aye rẹ laipẹ yii, nipa bi awọn obinrin ṣe maa n du u lasiko kan ati bi obinrin kan ṣe tori tirẹ darapọ mọ iṣẹ ere tiata .
Bakan naa lo sọrọ lori aisan kan to ṣe e lọdun to ti pẹ diẹ sẹyin, eyi to ni oun ro pe yoo gba ẹmi oun ni.
Ogogo ko ṣai ṣalaye nipa idasilẹ ẹgbẹ oṣere Odunfa to gbajumọ .
Nipa bo ṣe koju ọrọ awọn obinrin to fifẹ han si i, gbajumọ oṣere naa sọ pe:
''Iwa to le mu ifuradani si iyawo ile ni mi o ni i hu, mi o si ni ṣe ohun ti wọn fi maa ni ki lo sun ẹ debẹ.
''Obinrin kan ti tori mi darapọ mọ iṣẹ tiata ri, iyẹn ko ni ki n ṣiwa hu.
''Obinrin ọhun ṣi wa laye titi doni yii, to ba n wo mi bayii, a maa rẹrin-in ni .''
Àjọṣepọ̀ òun àti Olóògbé Bimpe Adekola (Ireti)
Oloogbe Bimpe Adekola tawon eeyan mọ si Ireti nigba naa lo saba maa n kopa iyawo Ogogo ninu sinima.
Eyi jẹ ki awuyewuye gbode nigba naa pe awọn mejeeji n fẹ ara wọn loju aye pẹlu.
Nigba to n ṣalaye ajọṣepọ oun ati Ireti, Ogogo sọ pe oun ko tilẹ mọ pe Yoruba ni ireti lọjọ to kọkọ wa lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣere Odunfa.
''Ọmọ Ghana ni mo pe e. Emi ni mo jẹ ko mọ Yinka Quadri, mo fi wọn mọ ara wọn nigba ti Yinka n wa amugbalẹgbẹẹ (P.A).
''Loootọ la jọ n ṣiṣẹ, awọn anti rẹ kan gan-an sọ pe mi o ṣe fẹ ẹ . Emi ni mo sọ pe obinrin to ba ti ni ẹni to n fẹ ko gbọdọ wu mi. Iyawo ọrẹ mi o gbọdọ wu mi''
Àjọṣepọ̀ òun àti Yinka Quadri
Gẹgẹ bi Taiwo Hassan ṣe wi, ọrẹ toun fẹran ju ni Yinka Quadi.
O ni nigba tawọn fẹe da ẹgbẹ oṣere Ọdunfa silẹ, Oloogbe Alade Aromire lo mu aba naa wa.
O fi kun un pe Yinka Quadri ko tilẹ si nibẹ lọjọ toun sọ pe kawọn fi I ṣe olori.
Awọn to wa nibẹ bo ṣe wi ni: Rasak Ajao, Alade Aromire, Lalude, Abiodun Olanrewaju ati Pefuele.
Awọn kan ko faramọ aba naa, ẹnikan ninu wọn si sọ pe oun ko le jẹ ki ẹni toun mọṣẹ ju lọ ṣe ọga oun.
''Awọn eeyan to tako naa ko ba wa da Odunfa silẹ, wọn binu lọ ni. Ṣugbọn Odunfa ṣi wa titi doni, ko figba kankan fọ bi wọn ṣe n gbe e kiri.''
Bẹẹ ni Ogogo wi.
'Ọdun méje ni mo fi wà lórí àisàn, mo rò pé mo máa kú ni'

Oríṣun àwòrán, Taiwo Hassan/ Instagram
Nigba to n sọrọ nipa idaamu rẹ lori aarẹ to ṣe e ṣeyin, Taiwo Hassan, ọmọ ilu Ilaro nipinlẹ Ogun, sọ pe:
'' Oko ere kan ni mo n lọ lọjọ naa lọhun-un, mo kan ri i pe kinni kan mu mi nibi aya mi. Nigba ti yoo fi to iṣẹju marun-un, ara o tu mi mọ.
''Loko ere naa ni mo ti pade Remi Surutu, o si bi mi pe ṣe ohun to n ṣe mi naa n fọ mi lori, ṣe o n dun mi lẹyin, mo ni bẹẹ ni. Lo ba sọ fun mi pe ọgbẹ inu ni.
''Mo wa ninu aawẹ lọjọ naa, aawẹ Ramadan ṣẹṣẹ di mẹrin ni.
''Wọn ni ki n ja a, ibẹru ati ja aawẹ yẹn mu mi. Ṣugbọn nigba to ya, mo gba lati ja a, ni wọn ba tu miliiki sinu omi tutu fun mi, mo mu un, ara si tu mi''
Ogogo tẹsiwaju pe lọjọ keji loun lọ sile iwosan, dokita si jẹ ko ye oun pe ọgbẹ inu to le gan-an lo n da oun laamu, ati pe ọsan wẹwẹ ati oogun kan toun n lo si i lo bi wahala naa.
O ni oun ko mọ pe ohun ti yoo di aarẹ ti oun yoo fi ọdun mẹfa si meje ṣe ni.
''Mo bì débi pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í bi ẹ̀jẹ̀''
Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Ogogo sọ pe aisan naa bẹrẹ si I le debi pe oun maa n bi gan-an ni.
''Bi mo ba jẹ irẹsi ti ko ju ṣibi ounjẹ ọmọde lọ, ma a bi titi ti ko fi ni i ku koro kan ninu mi ni. Ẹkọ ni wọn maa n fọ fun mi mu.
''Mo bi titi mo bẹrẹ si i bi ẹjẹ. Oṣu meje ni mi o fi le duro kirun, ijokoo ni mo ti n kirun.
''Mo tiẹ ro pe mo maa ku ni, mo ro pe ohun gbogbo ti tan. Ọjo kan ni mo yọ eyin Meka ti mo fi owo nla ṣe danu, mo kan sọ ọ nu pẹlu ero pe gbogbo nnkan ti pari ni.''
Nipa bo ṣe pada ri iwosan lẹyin ti aisan naa ti jẹ ko gbẹ gidi ti ko si lara mọ, agba oṣere naa sọ pe Aafaa, Pasitọ, Babalawo, Oṣo ati Ajẹ, gbogbo wọn ni wọn ba oun sọ f'Oluwa pe ko ma ti i pa oun.
Ogogo loun ko ta nnkan ini oun kankan lori aarẹ naa bo ṣe le to, nitori awọn eeyan dide iranwọ, oun si ria aanu gba.
O ni oun toun padanu ko ju ti oko ere toun ko le lọ lasiko naa lọ.














