Gbogbo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìdíje Wafcon 2024 tó bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Backpage Pix
Ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Africa tàwọn obìnrin tọdún 2024 'Women's Africa Cup of Nation (Wafcon) tún ti fẹ́ gbérasọ bí Morocco ṣe ń gba àlejò ìdíje náà fún ìgbà méjì léra.
Ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Keje ni ìdíje náà yóò bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn tí wọ́n sun síwájú fún ọdún kan, tí orílẹ̀ èdè Morocco ti máa kojú Zambia ní pápá ìṣeré Olympic Stadium tó wà ní Rabat ní aago mẹ́sàn-án aago Nàìjíríà.
Àwọn olólùfẹ́ rédíò World Service ní Africa yóò ní àǹfàní láti gbọ́ bí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà bá ṣe ń lọ lórí rédíò wọn ní ọjọ́ àkọ́kọ́, ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàárín Mali àti Tanzania tó fi mọ́ ìpele tó kẹ́yìn sí àṣekágbá àti àṣekágbá fúnra rẹ̀.
Nàìjíríà tó ti gba ife ẹ̀yẹ náà fún ìgbà mẹ́sàn-án yóò kojú Tunisia ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí ní ìsọ̀rí B nígbà tí South Africa yóò máa kojú Ghana ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Keje.
Báwo ni wọ́n ṣe wà ní ìsọ̀rí?
Àwọn ìkọ agbábọ́ọ̀lù méjìlá tí wọ́n pín sí ìsọ̀rí mẹ́ta ni wọ́n ń kópa níbi ìdíje náà pẹ̀lú orílẹ̀ èdè mẹ́rin ní ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan.
Morocco tó ń gbàlejò ìdíje náà wà ní ìsọ̀rí A pẹ̀lú Zambia tó fojú wọn gbolẹ̀ níbi ìdíje Olympic Games 2024.
Bákan náà ni wọ́n máa kojú Senegal àti DR Congo tí wọ́n jọ wà ní ìsọ̀rí kan náà.
Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà, Super Falcons yóò máa kojú Tunisia, Algeria àti Botswana tí wọ́n wà ní ìsàlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde àjọ tó ń rí sí bọ́ọ̀lù ní àgbáyé.
South Africa, Ghana, Mali àti Tanzania ló wà ní ìsọ̀rí C.
Orílẹ̀ èdè méjì tó bá ṣe dada jùlọ ló máa bọ́ sí ipele quarter-finals.
Ìsọ̀rí A: Morocco, Zambia, Senegal, DR Congo.
Ìsọ̀rí B: Nigeria, Tunisia, Algeria, Botswana.
Ìsọ̀rí C: South Africa, Ghana, Mali, Tanzania.
Báwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yóò ṣe wáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹ́yìn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí wọ́n bá fi ṣíde, ó kéré tán ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ méjì ni wọ́n máa ma gbá ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí tí ìsọ̀rí àkọ́kọ́ fi máa tán ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Keje.
Ní aago méjì ọ̀sán, márùn-ún ìrọ̀lẹ́ àti aago mẹ́jọ alẹ́ ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yóò máa wáyé ní abala ìsọ̀rí àkọ́kọ́.
Níbo ni wọ́n ti máa gbá àwọn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀
Aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ àti aago mẹ́jọ alẹ́ ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ yóò wáyé ní àwọn ipele tó kàn tí yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Kejìdínlógún, oṣù Keje.
Wọn kò ní lo àwọn pápá ìṣeré mẹ́ta tí wọ́n lò nígbà tí Morocco gbàlejò Wafcon ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn nítorí àtúnṣe tó ń lọ lọ́wọ́ ní àwọn pápá ìṣeré náà ní ìgbáradì fún ìdíje AFCON 2025 àti ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé 2030.
Pápá ìṣeré mẹ́fà ni wọ́n máa lò ní àwọn ìlú tó ń gbàlejò ìdíje náà pẹ̀lú méjì ní Casablanca.
- Olympic Stadium, Rabat
- El Bachir Stadium, Mohammedia
- Larbi Zaouli Stadium, Casablanca
- Pere Jego Stadium, Casablanca
- Honneur Stadium, Oujda
- Berkane Stadium, Berkane
Àwọn wo ni ààyò?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nínú àwọn orílẹ̀ èdè méjìlá tó ń kópa nínú ìdíje náà, Morocco, Nàìjíríà àti South Africa ni wọ́n ti gba ife ẹ̀ye náà rí.
Akọnimọ̀ọ́gbá Justin Madugwu ló kó ikọ̀ Super Falcos sòdí tí Chiamaka Nnadozie sì ti gba àmì ẹ̀yẹ bí aṣọ́lé tó dára jùlọ ní ẹ̀ẹmèjì léra.
Akọ́nimọ̀ọ́gbá Banyana Banyana South Africa, Desiree Ellis sì ní ìrètí pé àwọn yóò tún gba ife ẹ̀yẹ náà lọ́tẹ̀ yìí bíi ti ọdún kẹta sẹ́yìn.
Morocco ti dókoòwò gidi sídìí eré bọ́ọ̀lù àmọ́ àwọn obìnrin rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ máa ṣe dada gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin.
Zambia ló gba ipò kẹta níbi ìdíje tó kọjá tí wọ́n sì ń gbèrò láti tún fakọyọ lásìkò yìí
Bí ìdíje náà ṣe máa lọ

Oríṣun àwòrán, Backpage Pix
Aago GMT ni awọn wọ̀nyí wà
Ọjọ́ Karùn-ún oṣù Keje
Group A: Morocco vs Zambia, Olympic Stadium, Rabat (20:00) -
Ọjọ́ Kẹfà oṣù Keje
Ìsọ̀rí A: Senegal vs Ivory Coast, El Bachir Stadium, Mohammedia (14:00)
Ìsọ̀rí B: Nigeria vs Tunisia, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca (16:00)
Ìsọ̀rí B: Algeria vs Botswana, Pere Jego Stadium, Casablanca (19:00)
Ọjọ́ Keje oṣù Keje
Ìsọ̀rí C: South Africa vs Ghana, Honneur Stadium, Oujda (16:00)
Ìsọ̀rí C: Mali vs Tanzania, Berkane Stadium, Berkane (19:00)
Ọjọ́ Kẹsàn-án oṣù Keje
Ìsọ̀rí A: Zambia vs Senegal, Mohammedia (16:00)
Ìsọ̀rí A: DR Congo vs Morocco, Rabat (19:00)
Ọjọ́ Kẹwàá oṣù Keje
Ìsọ̀rí B: Botswana vs Nigeria, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca (16:00)
Ìsọ̀rí B: Tunisia vs Algeria, Pere Jego Stadium, Casablanca (19:00)
Ọjọ́ Kọkànlá oṣù Keje
Ìsọ̀rí C: Ghana vs Mali, Berkane (16:00)
Ìsọ̀rí C: Tanzania vs South Africa, Oujda (19:00)
Ọjọ́ Kejìlá oṣù Keje
Ìsọ̀rí A: Morocco vs Senegal, Rabat (19:00)
Ìsọ̀rí A: Zambia vs DR Congo, Mohammedia (19:00)
Ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Keje
Ìsọ̀rí B: Nigeria vs Algeria, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca (19:00)
Ìsọ̀rí B: Tunisia vs Botswana, Pere Jego Stadium, Casablanca (19:00)
Ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Keje
Ìsọ̀rí C: South Africa vs Mali, Oujda (19:00)
Ìsọ̀rí C: Ghana vs Tanzania, Berkane (19:00)
Ipele quarter-final
Ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Keje
QF1: Ẹni tó bá gbégbá orókè ní ìsọ̀rí A àti ẹni tó bá gbégbá orókè ní ìsọ̀rí, Rabat (19:00)
QF2: Ẹni tó bá gbégbá orókè ní ìsọ̀rí B àti ẹni tó bá gbégbá orókè ní ìsọ̀rí A kejì, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca (16:00)
Ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Keje
QF3: Ẹni tó bá gbégbá orókè ní ìsọ̀rí C àti ẹni tó bá wà ní ipò kẹta ní ìsọ̀rí A/B, Oujda (19:00)
QF4: Ẹni tó bá wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí B àtiẸni tó bá wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí C, Berkane (16:00)
Semi-finals

Oríṣun àwòrán, Backpage Pix
Tuesday 22 July
SF1: Ẹni tó bá gbégbá orókè ní QF1 àti Ẹni tó bá gbégbá orókè ní QF4, Rabat (19:00)
SF2: Ẹni tó bá gbégbá orókè ní QF2 àti Ẹni tó bá gbégbá orókè ní QF3, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca (16:00)
Ipò kẹta
Ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n oṣù Keje
Ikọ̀ tó bá pàdánù SF1 àti ikọ̀ tó bá pàdánù SF2, Larbi Zaouli Stadium, Casablanca (19:00)
Àṣekágbá
Ọjọ́ Kínlọ́gbọ̀n oṣù Keje
Ikọ̀ tó bá jáwé olúborí SF1 àti ikọ̀ tó bá jáwé olúborí SF2, Olympic Stadium, Rabat (20:00)












