Orílẹ́èdè Morocco ń gbaradì láti di ibùdó alágbára lẹ́ka eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Rob Stevens
- Role, BBC Sport Africa
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Orilẹede Morocco ti ṣeto ara rẹ bii ibujokoo ere bọọlu afẹsẹgbẹ fun awọn obinrin ilẹ Africa bayii, ko si sohun meji ti awọn alabojuto rẹ n ṣiṣẹ tọ ju bi wọn yoo ṣe di aṣiwaju lorii papa lọ.
Morocco ni yoo gbalejo idije awọn obinrin, 'Women's Africa Cup of Nations (WAFCON) 2024, bẹrẹ lati lati ọjọ karun-un si ikẹrindinlọgbọn oṣu Keje. Awọn naa ni wọn patẹ aṣekagba rẹ ni 2022, ti wọn si kede pe ti 2026 naa bọ si ọdọ wọn.
Eyi tun kere, bi a ba wo bo ṣe jẹ pe idije awọn ọkunrin ti akọsilẹ wọn wuyi pupọ naa tun n fi si Morocco, ti wọn si n na obitibiti miliọnu dọla lati pese awọn nnkan elo amayedẹrun .
Morocco to wa ni Ariwa Africa, n ni afojusun to le gan-an lori ere bọọlu, bẹrẹ lati ọdọ wọn kari gbogbo agbaye.
Igbesẹ to kan fun wọn bayii ni bi awọn obinrin agbabọọlu wọn, Atlas Lionesses, yoo ṣe rọwọ mu ju ipo keji ti wọn ṣe nilee wọn nibi idije AFCON ọdun kẹta sẹyin.
" Idije WAFCON to n bọ yii yoo tun ya wa lara gaga ju ti tẹlẹ lọ, o le mu ki awọn ọdọbinrin mu bọọlu bi iṣẹ, wọn si le gbabẹ di agbabọọlu to kaju ẹ daadaa ti wọn yoo si di ọkan lara awọn ikọ agbabọọlu apapọ ilẹẹ wa"
Mehdi El Qaichouri, akọnimọọgba FUS Rabat lo ṣalaye bẹẹ fun BBC Sport Africa.
Ìrèti ìgbéga

Oríṣun àwòrán, FUS Rabat
Nibi idije WAFCON ni 2022, eyi to waye ni papa iṣere Prince Moulay Abdellah, ẹgbẹ agbabọọlu FUS Rabat gbiyanju, ero to waa wo ere naa si to ẹgbẹrun lọna aadọta, ṣugbọn South Africa na Morocco, ami ayo meji si ọkan dondo.
Ipo kẹrin ni wọn ṣe ninu idije ife ẹyẹ awọn obinrin Morocco ni saa igbabọọlu to kọja.
Ẹgbẹ agbbọọlu AS FAR lo gba ami ẹyẹ naa. Ẹgbẹ agbabọọlu El Qaichouri naa n reti lati bori lọjọ iwaju.
Goolu FUS, Kawtar Bentaleb, ẹni to ran Morocco lọwọ ninu idije Futsal ọdun yii, ṣalaye pe agbega ti n ba ere bọọlu awọn obinrin.
"Ko sẹni to n ka a si tẹlẹ.
"Gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ti wọn ba n gba lọwọ yii, yala ti ọkunrin abi obinrin ni, ilọsiwaju lo maa mu ba wa.
"Awọn ọdọ asiko yii ni nnkan amayedẹrun ati iranwọ ti wọn nilo lati ro ara wọn lagbara gan-an. Mo rọ wọn lati ṣe amulo gbogbo awọn eto ti wọn ti ṣe kalẹ fun wọn, nitori yoo ran wọn lọwọ gan-an."
Kawtar Bentaleb lo sọ bẹẹ.
Orílẹ̀èdè tí àyípadà ń bá
Idije Ife ẹyẹ Africa Cup of Nations (AFCON) ti ọdun 2025 yii yoo bẹrẹ ni Morocco loṣu Kejila, owo nla ni wọn si n na le nnkan amayedẹrun nibẹ bayii, bi wọn ṣe tun n gbaradi lati kopa ninu gbigba alejo idije Ife ẹyẹ FIFA ni 2030.
Morocco n gbero lati jẹ ki papakọ ofurufu rẹ gbooro si i, lati 38 million to wa nipari 2024, si eyi to le gba ero miliọnu lọna ọgọrin ( 80 million) . Wọn fẹẹ ṣe eyi laaarin ọdun mẹrin aabọ si asiko yii.
Bakan naa ni wọn n ṣiṣẹ lori ọkọ oju irin ayara bi aṣa wọn. Wọn fẹ ko de Marrakech ko si tẹsiwaju de Agadir.
Apapọ papa iṣere marundinlaadọta (45 stadiums) ati ibudo igbẹkọ ere idaraya ni wọn n ṣe atunṣe rẹ lọwọ bayii, ti wọn si n jẹ ko gbooro si i.. Olubori rẹ ni ti Stade Hassan II, to wa nitosi Casablanca, o gba to 115,000 eeyan.
"Morocco ti yatọ si bo ṣe wa tẹlẹ, o n dagba gidi bayii ni," Bẹẹ ni alejo kan to ṣabẹwo si Rabat souk ṣalaye fun BBC.
"Wọn ti n ṣiṣẹ lori ọpọ ibudo tipẹ, wọn si n ri i daju pe awọn nnkan eelo ti wọn nilo nibẹ ti wa nikalẹ. Nisinyi ti wọn ti n kọ gbogbo ẹ kia yii, pẹlu aṣẹ Ọlọrun, gbogbo ẹ yoo ti pari nigba ti wọn yoo ba fi maa ṣe idije AFCON."
Bakan naa ni awọn olotẹẹli naa yoo jere ọja latari awọn eto idije yii.
" O maa wu wa lati gbalejo awọn eeyan kaakiri agbaye, awọn ti ko si mọ Morocco tẹlẹ yoo lo anfaani yii lati mọbẹ"
David Azuelos, ọnile itura kan ni olu ilu Morocco lo ṣalaye bẹẹ.
"A lero pe ti awọn obinrin yii naa yoo nipa to ga bii tawọn ọkunrin."
Bẹẹ ni ọkunrin naa wi.
Tibi-tire

Oríṣun àwòrán, Populous/Getty Images
Lati kọ papa iṣere Stade Hassan II yii lasan, owo to to $500m ni a gbọ pe yoo na wọn.
Owo ori gọbọi: Owo ti wọn n san lori iye ti wọn n pa lọdun to ju180,000 dirhams ($19,700) lọ, ida 37% eeyan n ṣeranwọ lati fi kun owo ile kikọ naa.
Gẹgẹ bi Amnesty International ṣe wi, Morocco ko fi aaye gba araalu lati sọrọ bi wọn ṣe fé, titi to fi kan pe wọn ko gbọdọ sọrọ tako ẹsin Islam, oriade to n jọba nibẹ ati awọn ileeṣẹ ijọba.
Nigba ti BBC rin irinajo lọ si Rabat nibẹrẹ ọdun yii, ko sẹni to ṣetan lati sọrọ lorii bi wọn ṣe n na owo ilu.
Eyi ri bẹẹ nitori wọn ni Ọba Mohammed VI, fẹran ere bọọlu afẹsẹgba, wọn si fẹ ki Ife ẹyẹ agbaye pada si Africa fun igba akọkọ lẹyin ogun ọdun.
Ṣugbọn loṣu Keji, oṣiṣẹ ajọ awọn olokowo kan bu ẹnu atẹ lu awọn ero ijọba yii, fun bi wọn ṣe jẹ ki iyatọ to gbooro wa laaarin olowo ati talika lẹka ọrọ aje, to bẹẹ ti ikaniyan ti wọn ṣe laipẹ fi han pe airiṣẹ ṣe laaarin awọn eeyan pọ, ida 21.3% ni.











