Fifa Club World Cup: Báyìí ni ìdíje ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù káàkiri àgbáyé yóò ṣe lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àgbáyé tàwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù yóò bẹ̀rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù méjìlélọ́gbọ̀n tó fi mọ́ Real Madrid, Manchester City àti Chelsea ló ń gbéra lọ sí Amẹ́ríkà láti kópa níbi ìdíje ọlọ́sẹ̀ mẹ́rin náà.
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Al Ahly ti Egypt, Mamelodi Sundowns ti South Africa, Wydad Casablanca ti Morocco àti Esperance ní Tunisia wà lára àwọn tó máa kópa.
Ṣáájú àsìkò yìí, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù méje péré ló máa ń kópa níbi ìdíje ọlọ́dọọdún náà àmọ́ tí wọ́n ti fààyè gba àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù láti ẹkùn mẹ́fà ti FIFA báyìí, tí ìdíje náà yóò sì máa wáyé ní ẹ̀ẹ̀kan láàárín ọdún mẹ́rin.
Àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìdíje náà àtàwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó ń kópa níbẹ̀.
Ìgbà wo ní ìdíje Club World Cup náà wáyé?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹfà ni ìdíje ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Club World Cup náà máa bẹ̀rẹ̀ tó sì máa wá sópin lọ́jọ́ Kẹtàlá, oṣù Keje.
Aago kan òru ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ máa wáyé láàárín ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Inter Miami tí Lionel Messi ń gbá fún àti Al Ahly tó jẹ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Egypt ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium ní Miami.
Ní pápá ìṣeré MetLife Stadium tó wà ní New Jersey ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí wọ́n fi máa káàdí ìdíje náà nílẹ̀ yóò ti wáyé.
Àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù wo ló kópa níbi ìdíje ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Club World Cup?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù méjìlélọ́gbọ̀n, tó fi mọ́ méjì láti Premier League - Manchester City àti Chelsea - ń lọ sí America fún ìdíje ọlọ́sẹ̀ mẹ́rin náà.
Àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ńlá míì tó ń kópa níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà ni Real Madrid, Bayern Munich àti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Paris Saint-Germain, PSG tó gbégbá orókè níbi ìdíje Champions League tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó ń kópa ní ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan:
Ìsọ̀rí A: Palmeiras, FC Porto, Al Ahly, Inter Miami
Ìsọ̀rí B: Paris St-Germain, Atletico Madrid, Botafogo, Seattle Sounders
Ìsọ̀rí C: Bayern Munich, Auckland City, Boca Juniors, Benfica
Ìsọ̀rí D: Flamengo, Esperance Sportive de Tunis, Chelsea, Los Angeles FC
Ìsọ̀rí E: River Plate, Urawa Red Diamonds, Monterrey, Inter Milan
Ìsọ̀rí F: Fluminense, Borussia Dortmund, Ulsan, Mamelodi Sundowns
Ìsọ̀rí G: Manchester City, Wydad, Al Ain, Juventus
Ìsọ̀rí H: Real Madrid, Al Hilal, Pachuca, Salzburg
Àwọn ìgbà tí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ máa wáyé fún Club World Cup
Ipele àkọ́kọ́
Ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹfà
Ìsọ̀rí A: Al Ahly àti Inter Miami ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium, Miami; aago kan òru
Ìsọ̀rí C: Bayern Munich àti Auckland City ní pápá ìṣeré TQL Stadium, Cincinnati; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́
Ìsọ̀rí B: PSG àti Atletico Madrid ní pápá ìṣeré Rose Bowl Stadium, Los Angeles; aago mẹ́jọ alẹ́
Ìsọ̀rí A: Palmeiras àti Porto ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago mọ́kànlá alẹ́
Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Kẹfà
Ìsọ̀rí B: Botafogo àti Seattle Sounders ní pápá ìṣeré Lumen Field, Seattle; aago mẹ́ta òru
Ìsọ̀rí D: Chelsea àti Los Angeles FC ní pápá ìṣeré Mercedes-Benz Stadium, Atlanta; aago mẹ́jọ alẹ́
Ìsọ̀rí C: Boca Juniors àti Benfica ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium, Miami; aago mọ́kànlá alẹ́
Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kẹfà
Ìsọ̀rí D: Flamengo àti Esperance de Tunis ní pápá ìṣeré Lincoln Financial Field, Philadelphia; aago méji òru
Ìsọ̀rí F: Fluminense àti Borussia Dortmund ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́
Ìsọ̀rí E: River Plate àti Urawa Red Diamonds ní pápá ìṣeré Lumen Field, Seattle; aago mẹ́jọ alẹ́
Ìsọ̀rí F: Ulsan HD àti Mamelodi Sundowns ní pápá ìṣeré Inter&Co Stadium, Orlando; aago mọ́kànlá alẹ́
Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Kẹfà
Ìsọ̀rí G: Al Ain àti Juventus ní pápá ìṣeré Audi Field, Washington, D.C; aago méjì òru
Ìsọ̀rí A: Palmeiras àti Al Ahly ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́
Ìsọ̀rí A: Inter Miami àti Porto ní pápá ìṣeré Mercedes-Benz Stadium, Atlanta; aago mẹ́jọ alẹ́
Ìsọ̀rí B: Seattle Sounders àti Atletico Madrid ní pápá ìṣeré Lumen Field, Seattle; aago mẹ́jọ alẹ́
Ìsọ̀rí B: PSG àti Botafogo ní pápá ìṣeré Rose Bowl Stadium, Los Angeles; aago mọ́kànlá alẹ́
Ọjọ́ Ẹtì, ogúnjọ́, oṣù Kẹfà
Ìsọ̀rí C: Benfica àti Auckland City ní pápá ìṣeré Inter&Co Stadium, Orlando; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́
Ìsọ̀rí D: Flamengo àti Chelsea ní pápá ìṣeré Lincoln Financial Field, Philadelphia; aago méje ìrọ̀lẹ́
Ìsọ̀rí D: Los Angeles FC àti Esperance de Tunis ní pápá ìṣeré GEODIS Park, Nashville; ní aago mẹ́wàá alẹ́
Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kẹfà
Ìsọ̀rí C: Bayern Munich vs Boca Juniors ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium, Miami; aago méjì òru
Ìsọ̀rí F: Mamelodi Sundowns vs Bosurissa Dortmund ní pápá ìṣeré TQL Stadium, Cincinnati; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́
Ìsọ̀rí E: Inter Milan vs Urawa Red Diamonds ní pápá ìṣeré Lumen Field, Seattle; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́
Ìsọ̀rí F: Fluminense vs Ulsan HD ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago mọ́kànlá alẹ́
Ìsọ̀rí E: River Plate vs Monterrey ní pápá ìṣeré Rose Bowl Stadium, Los Angeles; aago mọ́kànlá alẹ́
Ìsọ̀rí A: Porto àti Al Ahly ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago méjì òru
Ìsọ̀rí C: Auckland City àti Boca Juniors ní pápá ìṣeré GEODIS Park, Nashville; aago méje ìrọ̀lẹ́
Ìsọ̀rí C: Benfica àti Bayern Munich ní pápá ìṣeré Bank of America Stadium, Charlotte; aago mẹ́jọ alẹ́
Ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà
Ìsọ̀rí D: Los Angeles FC àti Flamengo ní pápá ìṣeré Camping World Stadium, Orlando; aago méjì òru
Ìsọ̀rí D: Esperance de Tunis àti Chelsea ní pápá ìṣeré Lincoln Financial Field, Philadelphia; aago méjì òru
Ìsọ̀rí F: Borussia Dortmund àti Ulsan HD ní pápá ìṣeré TQL Stadium, Cincinnati; aago mẹ́jọ alẹ́
Ìsọ̀rí F: Mamelodi Sundowns àti Fluminense ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium, Miami; aago mẹ́jọ alẹ́
Ìsọ̀rí E: Inter Milan àti River Plate ní pápá ìṣeré Lumen Field, Seattle; aago mọ́kànlá alẹ́
Ìsọ̀rí E: Urawa Red Diamonds àti Monterrey ní pápá ìṣeré Rose Bowl Stadium, Los Angeles; aago mọ́kànlá alẹ́
Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà
Ìsọ̀rí G: Juventus àti Man City ní pápá ìṣeré Camping World Stadium, Orlando; aago mẹ́jọ alẹ́
Ìsọ̀rí G: Wydad AC àti Al Ain ní pápá ìṣeré Audi Field, Washington, D.C; aago mẹ́jọ alẹ́
Ìsọ̀rí H: Al Hilal àti CF Pachuca ní pápá ìṣeré GEODIS Park, Nashville; aago kan òru
Ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà
Ìsọ̀rí H: FC Salzberg àti Real Madrid ní pápá ìṣeré Lincoln Financial Field, Philadelphia; kick off 1am
Ìsọ̀rí H: Al Hilal vs CF Pachuca ní pápá ìṣeré GEODIS Park, Nashville; aago kan òru
Round of 16
Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 49:Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí A àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí B ní pápá ìṣeré Lincoln Financial Field, Philadelphia; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 50: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí C àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí D ní pápá ìṣeré Bank of America Stadium, Charlotte; aago mẹ́sàn-án alẹ́
Ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 51: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí B àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí A ní pápá ìṣeré Mercedes-Benz Stadium, Atlanta; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 52: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí D àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí C ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium, Miami; aago mẹ́sàn-án alẹ́
Ọjọ́ Ajé ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kẹfà
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 53: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí E àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí F ní pápá ìṣeré Bank of America Stadium, Charlotte; aago mẹ́jọ alẹ́
Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kìíní, oṣù Keje
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 54: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí G àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí H ní pápá ìṣeré Camping World Stadium, Orlando; aago méjì òru
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 55: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí H àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí G ní pápá ìṣeré Hard Rock Stadium, Miami; aago mẹ́jọ alẹ́
Ọjọ́rú, ọjọ́ Kejì, oṣù Keje
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 56: Ẹni tó wà ní ipò kìíní ní ìsọ̀rí F àti ẹni tó wà ní ipò kejì ní ìsọ̀rí E ní pápá ìṣeré Mercedes-Benz Stadium, Atlanta; aago méji òru
Quarter-final fixtures
Ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Keje
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 57: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 53 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 54 ní pápá ìṣeré Camping World Stadium, Orlando; aago mẹ́jọ alẹ́
Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Keje
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 58: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 49 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 50 ní pápá ìṣeré Lincoln Financial Field, Philadelphia; aago méjì òru
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 59: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 51 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 52 ní pápá ìṣeré Mercedes-Benz Stadium, Atlanta; aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 60: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 55 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 56 ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago mẹ́sàn-án alẹ́
Semi-final
Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Keje
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 61: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 57 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 58 ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago mẹ́jọ alẹ́
Ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Keje
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 62: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 59 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 60 ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago mẹ́jọ alẹ́
Àṣekágbá
Ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Keje
Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 63: Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 61 àti Ẹgbẹ́ tó bá jáwé olúborí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ 62 ní pápá ìṣeré MetLife Stadium, New York New Jersey; aago mẹ́jọ alẹ́














