Àgbàrá òjò gbé èèyàn mọ́kànlá lọ l'Ámérika, ọ̀pọ̀ di àwátì

Oríṣun àwòrán, KENS 5 - CBS
O kere tan, eeyan mọkanla lo ti jade laye ti ọpọ si di awati lẹyin agbara omiyale to kọlu agbegbe San Antonio, ni Texas, lorilẹede Amẹrika.
Ileeṣẹ iroyin CBS jabọ pe iji lile to milẹ titi lọjọbọ ati ọjọ Ẹti gbe ọpọlọpọ ọkọ ayọkẹlẹ kuro loju popo, koda iji naa gbe awọn ọkọ kan lọ inu ira.
Ileeṣẹ panapana agbegbe San Antonio ni eeyan mẹrin lawọn ṣi n wa bayii lẹyin ti agbara gbe wọn lọ.
Awọn alaṣẹ ni iye eeyan to ku le pọ ju awọn ti awọn ti ri lọ, yoo si gba awọn ni akoko diẹ ki wọn to doola gbogbo awọn ti ọrọ naa kan tan.
Ileeṣẹ naa tun ni oun ti da awọn aja afimufinlẹ K9 si igboro lati maa wa awọn ti wọn ti dawati, bẹẹ lo tun bẹ awọn ileeṣẹ mii lọwẹ lati ṣe iranwọ fun oun.
O le ni ọgọta eeyan ti wọn yọ jade ninu omi lọsan ọjọ Abamẹta gẹgẹ bii ohun ti awọn alaṣẹ ipinlẹ Texas sọ.
CBS ni mẹrin ninu awọn ti wọn ri yọ ni wọn ti gbe digbadigba lọ sile iwosan bayii.
Awọn eeyan mẹta lara awọn ti ẹmi wọn sọnu sinu iṣẹlẹ naa, gẹgẹ bii ni alaye CBS ni Martha De La Torre Rangel, Matthew Angel Tufono, ati Victor Manuel Macias Castro.
A gbọ pe ṣe ni awọn eeyan ọhun ha sinu ọkọ ayọkẹlẹ wọn lagbegbe Perrin Beitel.
Obinrn kan, Angel Richards sọ fun ileeṣẹ iroyin KENS 5 pe ibiṣẹ ni ọkọ oun, Stevie n lọ ko to pe oun pe oun ti ha sinu agbara ojo naa.
Adari agbegbe San Antonio, Ron Nirenberg ti ba gbogbo awọn ti ọrọ naa kan kẹdun.
O ni "Ọkan wa wa pẹlu awọn mọlẹbi awọn ti a padanu ninu agbara omi ọsẹ yii tofi mọ awọn to ṣi n wa awọn mọlẹbi wọn."
Joaquin Castro, to jẹ ọmọ ile aṣofin lati agbegbe San Antonio ti juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii ajalu nla.















