Èèyàn márùn ún kú lábẹ́ ilé tó dàwó l'Abuja, ẹnìkan wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run

Awọn to farapa nibi ile to dawo l'Abuja

Oríṣun àwòrán, NEMA

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Eeyan marun un ti jade laye lẹyin ti ile kan dawo lagbegbe Durumi 3, ti ko fi bẹẹ jina si ọja Gudu, niluu Abuja.

Lara awọn ti wọn ri yọ jade laaye labẹ ile alaja mẹta naa ni ọkunrin kan to ti lo wakati mẹsan an labe ile ọhun.

Nnkan bii aago mẹsan an owurọ ọjọ Abamẹta ni iṣẹlẹ naa waye.

Akọwe ileeṣẹ to n ri si eto ilera nilu Abuja, Adedolapo Fasawe, to sọrọ lorukọ awọn adoola ẹmi sọ pe eeyan marundinlogun ni wọn yọ jade labẹ ile naa lẹyin to dawo tan.

Fasawe sọ pe mẹsan an ninu awọn ti wọn yọ jade lo ṣi wa laaye, marun un ti jẹ ipe Eledua, nigba ti ẹnikan wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

O fi kun pe iwadii ajọ Standards Organisation of Nigeria (SON) fi han pe niṣe ni agbaṣẹṣe to n kọ ile naa mọọmọ din simẹnti ti wọn lo n ku lasiko ti iṣẹ ile ọhun n lọ lọwọ.

Lẹyin naa lo rọ awọn agbaṣẹṣe ki wọn kọkọ maa gbaṣẹ lọwọ ijọba ki wọn to bẹrẹ si n kọ ile.

Wike paṣẹ iwosan ọfe fun gbogbo awọn ti ọrọ naa kan

Ẹwẹ, minisita fun FCT, Nyesom Wike ti paṣẹ ki wọn ṣe iwosan ọfẹ fun gbogbo awọn to farapa nibi ile alaja mẹta naa to dawo.

Fasawe lo sọ eyii di mimọ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nibẹ.

O ni iṣẹ idoola ẹmi ṣi n lọ lọwọ lati yọ awọn yoku to ba ṣeeṣe ki wọn ṣi wa labẹ ile ọhun.

Lasiko ti wọn n ṣiṣẹ idoola ẹmi lọwọ ni wọn yọ ọkunrin kan to ti lo odidi wakati mẹsan an labẹ ile ọhun laaye.

A gbọ pe wọn ṣi n kọ ile ọhun lọwọ ko dawo.

Awọn alaṣẹ ni awọn to n ru kọnkere lo pọ juloọ ninu awọn to ha sabẹ rẹ.

Lara awọn to ṣiṣẹ idoola ẹmi nibẹ ni ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, National Emergency Management Agency, ileeṣẹ panapana ilu Abuja, ileeṣẹ ọlọpaa, ileeṣẹ ọmọ ogun ati ajọ to n ri si irinkerindo ọkọ loju popo, FRSC.