Ṣé lóòótọ́ ni àjọ NIS, NSCDC àti NCS ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbanisíṣẹ́?

Awọn oṣiṣẹ Nigeria Immigration Service

Oríṣun àwòrán, Nigeria Immigration Service

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba apapọ ti sọrọ lori awọn iroyin kan to n lọ nigboro pe o ti bẹrẹ eto igbanisiṣẹ labẹ ileeṣẹ to n ri si orọ abẹle ni Naijiria.

Ajọ to n ri si ọrọ ileeṣẹ abo araẹni labo ilu, ileeṣẹ ọgba ẹwọn at ileeṣẹ panapana, CDCFIB, sọ ninu atẹjade kan pe oun ti ri lẹta ti awọn eeyan n pin kiri nipa eto igbanisiṣẹ lawọn ileeṣẹ naa amọ to jẹ iroyin ẹlẹjẹ.

Akọwe ajọ ọhun, Abdulmalik Jibril ninu atẹjade naa ni "O ṣe pataki lati jẹ ki awọn araalu mọ pe Aarẹ gbọdọ mọ si ki a to gba eeyan siṣẹ lawọn ileeṣẹ mẹrẹrin, oniruru ilana ni a si gbọdọ tẹle ki a to bẹrẹ eto igbanisiṣẹ kankan.

"Ajọ yii fẹ jẹ ki araalu mọ pe ki a to maa gba eeyan siṣẹ, a maa ṣe ipolongo ninu awọn iwe iroyin, ko ni si magomago kankan ninu eto naa, bẹẹ ni a ko ni gba owo lọwọ araalu.

"Nitori naa, ki awọn araalu ṣora gidi fun awọn to n lo anfani awọn to n wa iṣe lati fi ọna ẹburu gba owo lọwọ wọn."

Ṣaaju ni lẹta kan ti kọkọ gba ori ayelujara kan ninu eyii ti ijọba ti sọ pe ki eto igbanisiṣẹ naa bẹrẹ.

Amọ ajọ CDCFIB ti sọ pe ko tii si ohun to jọ bẹẹ lọwọ yii ati pe iṣẹ ọwọ awọn kọlọsọri ẹda ni.

Yatọ si lẹta to wa lori ayelujara yii, awọn kọlọrọsi kan tun ti n ṣe ipolowo loju opo Facebook nipa bi eeyan ṣe le ri iṣẹ si ajọ to n ri si iwọlewọde ni Naijiria, NIS.

Wayi o, kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn kọlọrọsi kan yoo kede eto igbanisiṣẹ ijọba apapọ bo tilẹ jẹ ijọba ko kede irufẹ eto bẹẹ.

Afojusun awọn kọlọrọsi naa lọpọ igba ni lati ji awọn iroyin kan nipa eeyan bii nọmba ẹrọ ibaraẹnisọrọ, email, ọjọ ibi tabi awọn nnkan mii nipa ẹni ti wọn ba fẹ lu jibiti.