Wo bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àwọn tó ń já fóònù gbà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwa ọdaran jiji foonu gba lọwọ ẹni kii ṣe ohun tuntun mọ kaakiri agbaye.
Bo tilẹ jẹ pe iwa ọdaran ni, pupọ awọn to n ja foonu gba lọwọ eeyan ni Naijiria lo n ṣe bẹẹ lojumọmọ lawọn ilu nla-nla bii Eko, Abuja, Kano, Port Harcourt, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Iroyin ni ọpọ eeyan ni ẹru maa n ba lati maa fi foonu rẹ ṣere lawọn nla wọnyii tabi ki wọn maa tẹ foonu naa laarin popo to ba di alẹ.
Ọpọ lo ti dero ile iwosan lẹyin ti awọn to fẹ fi agidi gba foonu wọn lu wọn tan latari pe won ko fẹ fi irufẹ foonu bẹẹ silẹ.
Lootọ ọlọpaa n ko awọn kọlọrọsi to n ja foonu gba yii, niṣe lo da bii pe wọn ko dinku.
Ọpọ eeyan lawọn to n ja foonu gba ti gbẹmi wọn
Labẹ afara Kano Bridge to wa niluu Kaduna, awọn to n ja foonu gba gun ọmọ ogun kan lọbẹ nitori wọn fẹ gba foonu rẹ.
Nipinlẹ Gombe, awọn ajafoonu gba tun gun olukọ ẹsin Islam kan, Alhaji Ahmadi Aliyu Umar lọbẹ, eyii to yọri si iku rẹ.
Nipinlẹ Eko, ọpọ ni wọn maa n lu niluu bara nigba ti wọn ba n ṣe agidi pẹlu awọn to fẹ ja foonu wọn gba.
Pẹlu awọn iroyin wọnyii, ibere ti ọpọ n bere ni pe bawo ni wọn ṣe le daabo bo ara wọn lọwọ awọn ole ajafoonugba yii.
Bi o ṣe le daabo bo ara rẹ lọwọ awọn to n ja foonu gba

Oríṣun àwòrán, gett
Auwal Bala Durumin Iya, to jẹ onimọ nipa eto abo nipinlẹ ni Kano ṣalaye awọn ọna ti eeyan fi le daabo ara rẹ lọwọ awọn to n ja foonu gba yii, amọ nigba mii o sọ pe da lori iye alafo to wa laarin iwọ ati ẹni to fẹ ja foonu rẹ gba.
- Alafo mita meji – Ti alafo to ba wa larin iwọ ati ẹni to fẹ ja foonu rẹ gba ko ba pọ, o lewu gidi fun iwọ ati ati foonu rẹ.
- Alafo mita mẹrin - Ti alafo ẹyin mejeji ko ba fun ju, o le fun ole naa lanfani lati fi ọwọ kan ọ, o lanfani lati pariwo sita tabi ki o salọ.
- Alafo mita mẹfa – Ti alafo aarin ẹyin mejeji ba to mita mẹfa, pariwo sita tabi ki o wa nnkan ti o le fi daabo bo ara re.
Auwal Bala tun ṣalaye awọn nnkan ti eeyan le ṣe lati jina si awọn to n ja foonu gba lọwọ ẹni.
- Ṣora fun ibi ti ero ba pọ si ju – O rọrun fun ole lati ji foonu rẹ pẹlu ifọkanbalẹ laarin ọpọ ero bii aarin ọja, ode ariya ti olorin ti ṣere, papa iṣere bọọlu, gbagede isọji atawọn ibomii ti ero ba korajọ si. Ṣora ni fifi foonu rẹ ya fọtọ tabi video ni irufẹ agbagbe bẹẹ nitori o lewu.
- Ma ṣe fi foonu rẹ yangan - Ọpọ lo maa n fi ẹrọ ilewọ wọn buga tabi yanga laarin awọn eeyan, o rọrun lati padanu foonu rẹ ti o ba n ṣe bẹẹ. Ti foonu rẹ ba jẹ olowo nla, ṣora ni fifi yanga laarin awọn eeyan, paapaa nibi ti ero pọ si tabi ibi ti o kọ mọ daadaa. Kii ṣe dandan ki awọn eeyan mọ pe iPhone tabi Samsung lo wa lọwọ rẹ.
- Oju ni alakan fi n ṣori – Maa ṣora ni gbogbo igba fun awọn to n yọ foonu lapo ẹni laarin ọja, nibudokọ tabi awọn ibomii. Bẹẹ naa maa ṣọra lawọn akoko kan bii lẹyin aago mẹsan an tabi lẹyin aago mẹwaa alẹ. Ṣora fun gbigba awọn agbegbe too maa n da loru ọganjọ nitori ko si ẹni ti yo fẹ gba ọ silẹ ti o ba n kigbe lawọn agbegbe bẹẹ loru.















