Bàbá ẹni odun 68 torí fóònù kó sí kọ̀ǹga ní Ibadan

Nibi ti wọn ti n gbe baba naa jade.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ panapana ni ipinlẹ Ọyọ ti doola ẹmi baba agba ẹni ọdun mejidinlaadọrin kan to bẹ sinu kọnga lati yọ ẹrọ ibanisọrọ rẹ.

Iṣẹlẹ yii waye lagbegbe mọṣalaṣi Mobọlọrunduro ni Mọlefalaafia, Oke Ado nilu Ibadan.

Gẹgẹbi atẹjade kan ti alaga ati olubadamọran fun gomina lori atunto ileeṣẹ panapana ni ipinlẹ Ọyọ, Họnọrebu Moroof Adebayọ Akinwande fi sita, igbiyanju arakunrin naa lati ṣe awari foonu rẹ lo sọ ọ di ẹni to n ko sinu kọnga naa.

Amọṣa, ijafafa awọn oṣiṣẹ panapana lo ṣokunfa didoola ẹmi arakunrin naa.

Arakunrin naa ṣi wa laaye lasiko tiwọn doola ẹmi rẹ, ni kete ti wọn si faa kuro ninu kọnga naa ni wọn fa a le awọn mọlẹbi rẹ lọwọ.