Maryam Abacha: Ọkọ mi kò jí owò Nàìjíríà, ẹ yéé ba orúkọ rẹ̀ jẹ́

Maryam ati ọkọ rẹ, Oloogbe Sani Abacha

Oríṣun àwòrán, Maryam/ Getty image

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bi olori Naijiria tẹlẹ kan ba wa ti gbogbo araalu gbagbọ pe o ji owo orilẹede yii ko pamọ si awọn ilu oke okun, OloogbeỌgagun Sani Abacha ni.

Ṣugbọn iyawo rẹ, Maryam Abacha, ti ni ọrọ ko ri bẹẹ, o ni ki wọn yee ba orukọ ọkọ oun jẹ kiri.

Nibi ifọrọwanilẹnuwo kan ti wọn ṣe fun Abilẹkọ Abacha lori tẹlifiṣan TVC lọjọ Aiku, ni obinrin naa ti fi ibinu sọrọ yii.

Ifọrọwanilẹnu ọhun waye lati sami ọdun kẹtadinlọgbọn, (27) ti Abacha ti dagbere faye ni.

Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa ọdun 1998 ni Oloogbe Sani Abacha dagbere faye, lẹyin to ṣejọba ologun orilẹ ede yii lati 1993 si 1998.

Ọpọ ninu awọn to ṣejọba lẹyin rẹ ni wọn si ti ri owo nla gba lorukọ Abacha, eyi ti Oloogbe naa ṣe lọjọ si awọn banki ilẹ okeere ni US, UK, Switzerland ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ẹlẹ́rìí wo ló wà níbẹ̀ tó lè sọ pe ọkọ mi jí owó Naijiria?

Ni itẹsiwaju awijare Iyawo Abacha, iya naa sọ pe iṣuna ọkọ oun lasiko to ṣe ijọba ko ye awọn to n sọ pe o ji owo Naijiria pamọ si oke okun.

O ni ki awọn to n dunrun mọ ọkọ oun mu ẹri to daju wa to ba jẹ pe Abacha jale tabi fi owo ilu pamọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ẹlẹrii wo lo ṣoju ẹ nigba to n fi owo pamọ si oke okun?

"Ṣe ẹ ri ibuwọlu tabi ẹri owo kankan to tọju pamọ silẹ okeere? Owo ti ọkọ mi fi pamọ fun Naijiria, laaarin oṣu diẹ lo poora. Awọn eeyan ko sọ nipa iyẹn."

"Ki lo de ti awọn eeyan n naka abuku si i? Ṣe iṣoro ẹlẹyamẹya niyẹn ni abi ti ẹsin, abi ki ni iṣoro awọn ọmọ Naijiria gan-an?"

Iyawo Abacha lo beere bẹẹ.

"Mo gbadura fun awọn ọmọ Naijiria, mo gbadura fun gbogbo wa. Mo bẹ Ọlọun ko jẹ ka le ni ero daadaa lọkan wa, ka yee parọ mọ awọn eeyan, ka si yee yee di ẹbi ru wọn. "

" Obinrin akọkọ ni Naijiria laaarin 1993 si 1998 ti ọkọ rẹ ku naa, tẹsiwaju pe iwa awọn eeyan Naijiria ko daa sira wọn.

O ni ki lo de ti ikorira yoo wa bi ẹni kan ba jẹ ara Ariwa, ti ikeji jẹ ara Guusu, tabi nitori ẹnikan jẹ Musulumi ti ikeji si jẹ Kristẹni.

Iyawo Abacha ni ko daa bẹẹ rara.

Maryam fi kun un pe ko yẹ kawọn ọmọ Naijiria maa gba gbogbo nnkan gbọ.

O ni bi wọn ṣe n ro pe awọn ijọba to de lẹyin ọkọ oun ri owo to ko pamọ gba ko yẹ ko ri bẹẹ.

Bakan naa lo ni Babangida, Abiola tabi ẹnikẹni ko le da Naijiria to, Abacha si kọ lo fagile ibo June 12, gẹgẹ bi iyawo rẹ ṣe sọ.

O ni ki gbogbo aye yee fi oju ẹni ibi wo Sani Abacha.

Ìgbé ayé olóògbé Sani Abacha

Ogunjọ, oṣu Kẹsàn-án, ọdun 1943 ni wọn bi Sani Abacha n'ilu Kano.

O lọ si ile ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ ati girama n'ilu Kano.

Lẹyin naa lo lọ si ile ẹkọ awọn ológun n'ilu Kaduna lọdun 1962 si 1963 ko too lọ si ile ẹ̀kọ́ ológun Aldershot Military Training College ni England lọdun 1963.

Bakan naa lo tun kẹ́kọ̀ọ́ ni Warminster National Military Training College ni UK lọdun 1966.

Ni 1971, o kẹ́kọ̀ọ́ ni Jaji Military College niluu Kaduna.

Lẹyin naa lo tun kẹ́kọ̀ọ́ ni Kuru College of Policy and Management niluu Jo's, lọdun 1981.

O tun kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ nipa eto aabo ni orile-ede Canada ati America lọdun 1982.

Ojiji ni iku Sani Abacha ba gbogbo ọmọ Naijiria, paapaa nitori pe ko ṣe àìsàn kankan ko to kú lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfà, ọdun 1998.

Iyawo rẹ, Maryam Abacha sọ pe igbe aye ọkọ oun gẹgẹ bi ológun, yàtọ̀ si igbeaye to gbe pẹlu ẹbí rẹ̀.

O ni oloogbe fẹ́ràn lati maa ṣeré ati àwàdà pẹlu ẹbi rẹ, ti ki i si fi adura ṣeré rara.