Aráàlú tú sí ìgboro lẹ́yìn tí ẹni tó bú ọ̀gá ọlọ́pàá lójú òpó X kú sí àtìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, Andalou via Getty Images
Ọpọ awọn ajafẹtọọmọniyan niluu Nairobi, lorilẹede Kenya lo ti berẹ ifẹhonuhan bayii lẹyin ti Ọkunrin kan ku si ahamọ ọlọpaa nibẹ.
Iku Albert Omondi Ojwang ti da wahala silẹ lẹyin ti ọga ọlọpaa kan fi ẹsun kan an pe o sọrọ abuku si oun lori ayelujara, ti wọn si fi ṣikun ofin gbe.
Ọlọpaa kọkọ sọ ninu atẹjade kan pe ọkunurn ọhun farapa lẹyin to la ori mọ ogiri ninu ahamọ to wa.
Amọ agbẹjọro mọlẹbi oloogbe ọhun ti sọ pe awọn apẹrẹ to wa lara ori, eti, imu ati oju rẹ fi han pe wọn fọwọ kan an.
Juma tun sọ pe awọn egbo kan wa lọwọ ati ejika rẹ, eyii to n ṣafihan pe kii ṣe pe o kan gba ori mọ ogiri nikan ni.
Ajọ Independent Policing Oversight Authority (IPOA) ti orilẹede Kenya ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Iwaju ile igbokupamọsi kan niluu Nairobi lawọn eeyan ti n ṣewọde tako awọn ọlọpaa pẹlu oniruru akọle lọwọ wọn bii "Ẹ dẹkun ati maa pa wa."
Lẹyin ti wọn kuro nibẹ ni wọn tun korajọ siwaju ọọfisi ọlọpaa ti wọn ti ologbe naa mọ ṣaaju iku rẹ.
Ọjọ Ẹti to kọja ni ọlọpaa mu Ojwang ni Homa Bay to wa lagbege iwọ oorun Kenya lẹyin to sọrọ kobakungbe si igbakeji ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ naa, Eliud Lagat, loju opo X rẹ.
Lati ibẹ ni wọn ti gbe lọ si olu ọọfisi ọlọpaa niluu Nairobi, eyii to jẹ nnkan bii igba ati ogun maili si ibi ti wọn ti wọn ti mu.
Gbogbo eyii lo waye lẹyin ti ọga ọlọpaa naa sọ pe afurasi ọhun "ba orukọ oun jẹ."
Wayi o, iroyin ni ọrọ naa ti ṣi mọ awọn ọlọpaa kan lori ni agọ ọlọpaa ti wọn tii mọ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Kenya, Michael Muchiri, sọ fun BBC pe awọn ọlọpaa ti ọrọ naa kan ko ni le ṣe awọn iṣẹ kan mọ, bẹẹ ni wọn n ko ni gba idaji lara owo oṣu wọn titi ti iwadii yoo fi pari lori ọrọ naa.
Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Kenya, Kanja ti ni oun yoo fun awọn oluwadii lanfani lati ṣe iṣẹ wọn lai si idiwọ kankan lori iṣẹlẹ naa.
Ẹwẹ, ajọ ajafẹtọọmọniyan Amnesty International ti sọ fun BBC pe ejo lọwọ ninu iku oloogbe ọhun.
Afurasí kú sí àhámọ́ lẹ́yìn tí wọ́n mú u fún ohun tó kọ s'ójú opo X rẹ

Oríṣun àwòrán, X
Iwadii ti bẹrẹ bayii lori iku to pa ọkunrin kan, Albert Ojwang, ẹni to ku si atimọle lorilẹede Kenya, lẹyin ti wọn fi ọwọ ofin mu un lori ohun to kọ si oju opo ayelujara X rẹ.
Gẹgẹ bi atẹjade awọn ọlọpaa Kenya ṣe wi, ohun ti wọn mu Oloogbe Albert fun ni pe o kọ nnkan ti ki i ṣe otitọ si oju opo ayelujara naa.
Baba Oloogbe, Meshack Opiyo, ṣalaye pe ilu Homa Bay ni wọn ti fọwọ ofin mu ọmọ oun, wọn si gbe e lọ si Nairobi ti i ṣe Olu ilu Kenya.
Irinajo igba ati ogun maili (220 miles) ni eyi gẹgẹ bo ṣe sọ.
"Nigba to wa ni ahamọ, afurasi naa fori gba ogiri yara to wa, o si ṣèṣe. Wọn sare gbe e lọ sileewosan, wọn si jẹ ko ye wọn pe o ti ku bi wọn ṣe gbe e de."
Bẹẹ ni atẹjade ọlọpaa ṣalaye nipa iku Albert ti wọn ni olukọ ati awọn to maa n gbe iroyin jade (blogger) lori ayelujara ni.
Adari ẹgbẹ Amnesty International to n ja fun ẹtọ ọmọniyan, ẹka ti Kenya, Irungu Houghton, sọ fun BBC pe iku to pa Ojwang yii mu ifura dani gidi.
Ẹgbẹ naa ṣalaye ninu atẹjade wọn, pe iku to yẹ ki iwadii bẹrẹ lorii rẹ kia leyi, iwadii kikun si ni pẹlu.
Ẹka iroyin Star newspaper, royin pe ọga ọlọpaa,
Stephen Okal, sọ foun pe igbiyanju lati pa ara ẹni lo pa Oloogbe Albert Ojwang.
Kí ni Olóògbé kọ sójú òpó X rẹ̀ gan-an?
Ẹsun kikọ ohun ti ko ri bẹẹ jade, "false publication", ni wọn tori ẹ mu Ojwang ti mọle, ṣugbọn ohun pato ti ko ri bẹẹ naa ni wọn ko ti i fidi ẹ mulẹ.
Ṣugbọn baba ọkunrin to ku si ahamọ yii, ṣalaye fun ẹka iroyin Online news site Citizen Digital, pe ọlọpaa to mu Albert sọ pe o fi abuku kan eeyan nla kan loju opo X ni.
Nigba to n sọrọ nipa bi wọn ṣe mu Albert, Adari ẹgbẹ Amnesty International ni Kenya, sọ pe ijọloju gidi lo jẹ.
O ni iyalẹnu lo jẹ pe wọn ko fi Oloogbe naa si ahamọ nit teṣan itosi, ti wọn waa n gbe e kiri ọna to jin to bẹẹ.
Adari ẹgbẹ naa kesi awọn oluwadii ti ko ṣiṣẹ fun ijọba, o ni ki wọn beere ohun to ṣẹlẹ nibudo iku Ojwang ni Nairobi.
Ṣugbọn awọn ọlọpaa sọ pe ọna to ba ofin mu ni awọn gba mu Ojwang.
Iṣẹlẹ iku Ojawang yii tun ti mu ọpọ eeyan ni Kenya lati maa sọ pe wọn n fi oju awọn to ba tako ijọba han eemọ bayii.
Ọsẹ to kọja ni wọn fi ọwọ ofin mu obinrin onikọmputa kan, Rose Njeri.
Njeri lo gbe ẹka kan kalẹ ti araalu le fi tako bi ijọba ṣe n nawo ilu.
Wọn fi ẹsun kan an pe o lufin to de lilo ayelujara ati ẹrọ kọmputa.














