Ọkùnrin tó mu oògùn olóró 'Colorado' yó lọ́jọ́ ọdún Ileya kó sí kànga ní Kwara

Ilorin

Oríṣun àwòrán, KSFS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ panpana ipinlẹ Kwara ti yọ oku ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogoji kan to ko sinu kanga lẹyin ọdun Ileya.

Agbegbe Edun, ni ijọba ibilẹ iwọ oorun Ilorin ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Iroyin ni ọkunrin ọhun ti kọkọ mu oogun oloro Synthetic Cannabinoids ti ọpọ mọ si 'Colorado' yo ko to ko sinu kanga naa.

A gbọ pe laipẹ lẹyin to ti ibi adura Eid-el-Kabir de lọjọ Ẹti lo wu iwa laabi naa.

Hassan Adekunle, to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara to fidi iroyin naa mulẹ sọ pe awọn ti yọ oku oloogbe ọhun ninu kanga naa.

Atẹjade naa sọ pe "A gba ipe pajawiri ni nnkan bii aago mẹwaa abọ pe ọkunrin kan ko sinu kanga.

"Ọkunrin ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Kazeem ni a gbọ pe o ti mu oogun oloro Colorado yo lẹyin to pada de lati Eid.

"A ti fa oku rẹ le ọwọ Inspector Babatunde Amos ni ẹka C Division ileeṣẹ ọlọpaa ilu Ilorin lọwọ."

Adekunle sọ pe ileeṣẹ naa ti n reti ki awọn mọlẹbi rẹ wa farahan lati wa gbe oku rẹ.

Adari ileeṣẹ panapana ipinlẹ naa, Falade Olumuyiwa, ti ba inu jẹ lori iṣẹlẹ ọhun.

O wa fi akoko naa kilọ fun awọn ọdọ lato ṣọra fun oogun oloro nitori atubọtan rẹ.

Ẹwẹ, titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, ko tii si ẹni to tii le sọ eredi ti oloogbe naa fi ko sinu kanga yatọ si oogun oloro ti a gbọ pe o mu.