Ẹ wo bí ìgbáradì ṣe ń lọ ní Ijebu Ode fún ọdún Ojude Oba 2025

Gbogbo eto ni o ti to bayii fun ọdun Ojude Oba ti ọdun 2025 yii lati gberasọ niluu Ijebu Ode nipinlẹ Ogun lọjọ Aiku ọjọ kẹjọ oṣu kẹfa yii.
BBC Yoruba wa niluu Ijebu Ode lati tọpinpin bi ọdun naa yoo ṣe lọ.
Akiyesi wa ni pe lati ọjọ Ẹti ọjọ kẹfa oṣu Kẹfa ti i ṣe ọjọ ọdun Ileya lawọn araalu ilu Ijebu Ode ti n pa ẹran titi di oni ọjọ Abamẹta ti ọdun Ojude Oba ku ọla.
Pipa ẹran lojule de ojule niluu Ijebu Ode tumọ si pe ọdun Ileya maa n darapọ mọ ọdun Ojude Oba lọdọọdun.
BBC Yoruba tun ṣakiyesi ẹṣin kaakiri ilu Ijebu Ode, bawọn kan ṣe n wẹ fun ẹṣin wọn lawọn mii n ṣe tiwọn lọṣọọ.
Awọn ti wọn ko wẹ fun ẹṣin tiwọn so o mọlẹ nibi ti wọn ti n jẹ koriko ṣaaju Ojude Oba ti yoo waye lọla.

Ọpọ eeyan ni a ṣakiyesi wi pe wọn yawọ ilu Ijebu Ode lati ọjọ Ẹti ti BBC Yoruba ti de si ilu naa.
Ọpọ ni a gbọ pe wọn rinrin ajo wa lati awọn orilẹede ilẹ okeere ati kaakiri gbogbo agbaye.
Ọkunrin kan ti ẹ ba BBC Yoruba sọrọ wi pe lati orilẹede Mexico loun ti wale fun ọdun Ojude Oba.
O sọ pe bi oun ṣe maa n wale lọdọọdun niyẹn fun ọdun Ojude Ọba.




Gbagede ti wọn maa n lo fun ọdun Ojude Oba lọdọọdun naa ti dun un wo loju bayii, lẹyin ti wọn ti ṣe oriṣiiriṣii ọṣọ sibẹ.
Gbagbede naa ti n tan yinrin yinrin ṣaaju ọdun Ọjude Oba ti yoo gberasọ lọla Aiku.





















