Mọ̀ nípa rọ́bà ìdáàbò bò tó ti pé igba ọdún tí wọ́n ṣàfihàn rẹ̀ nílé ìkó nǹkan ìṣẹ̀mbáyé sí

Oríṣun àwòrán, Rijksmuseum
Airin jinna lai ri abuke ọkẹrẹ, wọn ti ṣe afihan rọba idaabobo kan eyi ti wọn sọ pe o ti to igba ọdun nile iko nnkan iṣẹmbaye si Rijksmuseum niluu Amsterdam lorilẹede Netherlands.
Awọn onimọ sọ pe lara agutan kan ni wọn ti ri rọba idaabobo naa to si ni aworan alufaa ọkunrin mẹta ati obinrin kan.
Iwadii fi idi rẹ mulẹ pe, ọdun 1830 ni wọn lo rọba idaabobo ọhun, ọdun to kọja ni ile iko nnkan iṣẹmbaye si Rijks si ra a.
Rọba idaabobo yii wa lara nnkan ti wọn fi n ṣe ami iṣẹ aṣẹwo ni nnkan bii ọgọrun un ọdun sẹyin.
Ile iko nnkan iṣẹmbaye sí naa sọ pe rọba idaabobo yii jẹ nnkan kan gboogi t'awọn eeyan mọ nipa rẹ daadaa.
Baagi kan ti wọn fi awọ ọọni ṣe ati awọn igo kekeke lọfinda to tun n run dundun wa lara awọn nnkan iṣẹmbaye ti wọn ri ninu ọkọ oju omi Titanic to ri ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin.
Ni gbogbo igba ni wọn maa n gbe gbọngan ti wọn ko awọn nnkan yii pamọ sí tipa torí iye tí wọn fi ra wọn.
Ohun ti a le sọ ni pe ni ibikan ni Atlanta, Georgia lorilẹede Amẹrika ni wọn tọju awọn nnkan naa si.
Ẹgbẹẹgbẹrun nnkan lo wa níbẹ to fi mọ baluwẹ, oríṣìíríṣìí awo at'awọn nnkan mii.
Aworan to wa lara rọba idaabobo naa ṣafihan ojiṣẹ Ọlọrun obinrin kan to jokoo niwaju alufaa mẹta

Oríṣun àwòrán, Rijksmuseum
BBC lanfaani lati wọ inu ile naa, nibẹ ni BBC ti mọ itan to rọ mọ ọpọ awọn nnkan iṣẹmbaye ti wọn ko pamọ́ sibẹ.
"Rọba idaabobo yii n sọ nipa nnkan to dara ati ẹru to maa n b'awọn eeyan nipa Ibalopọ bii oyun nini lai tii ṣetan ọmọ bibi ati oriṣiriṣii aarun ibalopọ."
Ile iko nnkan iṣẹmbaye si naa tun ṣalaye pe ẹbun ni rọba idaabobo ọhun jẹ lati ile asẹwo kan, ati pe meji rọba idaabobo naa lo si wa di oni.
Aworan to han kete kete lara rọba idaabobo naa ṣafihan ojiṣẹ Ọlọrun obinrin kan to jokoo niwaju alufaa mẹta ti o si ya ẹsẹ rẹ kata kata.
Obinrin naa na ika s'awọn alufaa ọhun ti awọn naa si duro niwaju rẹ.
Nnkan mii ti wọn kọ sara rọba idaabobo ọhun ni "Voilà mon choix," eyi to tumọ si "ohun ti mo yan niyẹn."
Ile iko nnkan iṣẹmbaye si ri nnkan ti wọn kọ sara rọba idaabobo naa bíi ọrọ to ni ṣe pẹlu igbe aye obinrin to pinnu lati ma ni Ibalopọ.
Ile iko nnkan iṣẹmbaye si orilẹede Netherlands ṣalaye pe ko din ni 750,000 aworan, ami ati fọto to wa ninu yara ti wọn n ko awọn nnkan yii si.
Amọ, wọn ni igba akọkọ ree ti wọn yoo ṣafihan nnkan ti wọn kọ sara rọba idaabobo.
Ile iko nnkan iṣẹmbaye si yìí yoo tẹsiwaju lati maa ṣafihan rọba idaabobo naa titi di ipari oṣu Kọkanla ọdun yìí.















