Wo orílẹ̀èdè méjìlá tí Trump fòfin dè pé wọn kò gbọdọ̀ wọ Amẹrika mọ́

Aarẹ Amẹrika, Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Donald Trump

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti fofin de orilẹede mejila pe awọn ọmọ ilẹ rẹ ko gbọdọ wọ Amẹrika mọ.

Gẹgẹ bii atẹjade kan lati ile ijọba, White House, eredi igbesẹ naa ko ṣẹyin eto abo.

Yatọ si awọn orilẹede mejila wọnyii, ijọba Amẹrika tun kede orilẹede meje mii ti wọn ko ni le wọ Amẹrika fun akoko diẹ.

Trump sọ pe oun le ṣafikun awọn orilẹede toun fofin de, bẹẹ ni ijọba oun tun le yọ orukọ awọn orilẹede kan kuro lara awọn ti wọn fofin de amọ o da lori iwa ti awọn eeyan orilẹede naa ba wu.

Skip Ṣé ó wù ọ́ láti ka ìròyìn nípa ìlera rẹ? Darapọ̀ mọ́ wa ní Whatsapp Channel and continue readingṢé ó wù ọ́ láti ka ìròyìn nípa ìlera rẹ? Darapọ̀ mọ́ wa ní Whatsapp Channel

End of Ṣé ó wù ọ́ láti ka ìròyìn nípa ìlera rẹ? Darapọ̀ mọ́ wa ní Whatsapp Channel

Igba keji ree ti Aarẹ ọhun yoo fofin de awọn orilẹede kan.

Igba akọkọ ni igba to fofin de awọn orilẹede kan lọdun 2017 to n ṣejọba fun igba akọkọ.

Awọn orilẹede wo ni Trumpo fofin de?

Awọn orilẹede mejila wọnyii ni Trump sọ pe awọn eeyan rẹ ko gbọdọ wọ Amẹrika mọ.

  • Afghanistan
  • Myanmar
  • Chad
  • Congo-Brazzaville
  • Equatorial Guinea
  • Eritrea
  • Haiti
  • Iran
  • Libya
  • Somalia
  • Sudan
  • Yemen

Awọn orilẹede ti Trump fofin de fun igba diẹ

Iwọnyii ni awọn orilẹede meje ti awọn eeyan rẹ ko ni le wọ Amẹrika fun igba diẹ.

  • Burundi
  • Cuba
  • Laos
  • Sierra Leone
  • Togo
  • Turkmenistan
  • Venezuela

Lati aago mejila kọja iṣẹju kan oru ọjọ Aje to n bọ ni ofin tuntun naa yoo bẹrẹ si n mulẹ amọ ijọba Amẹrika ko kede igba ti yoo dopin.

Ki lo ṣokunfa ofin tuntun yii?

Gẹgẹ bii ohun ti White House sọ, ofin naa ṣe pataki lati daabo bo awọn ọmọ ilẹ Amẹrika lọwọ awọn atọhunrinwa to n gbogun ti Amẹrika.

Ninu fidio kan ti Trump fi lede laipẹ yii, o ni iṣẹlẹ igbesunmọmi to waye lẹnu lọlọ yii ni Colorado n tumọ si pe o yẹ ki wọn maa ṣayẹwo awọn eeyan to n wọ Amẹrika lati ilẹ okere daadaa ki wọn to wọle.

Eeyan meji lo farapa ni Colorado lọjọ Aiku nigba ti ẹnikan ju ina si aarin awọn to n ṣewọde lati ṣatilẹyin fun awọn ti wọn ko ni igbekun ni Israel.

Iwadii ti fi han pe ọmọ orilẹede Egypt ni ọkunrin to kọlu awọn eeyan naa amọ orilẹede Egypt ko si lara awọn orilẹede ti Trump fofin de.

Awọn wo ni ofin ti wọn ti fo de awọn orilẹede yii ko kan?

  • Awọn elere idaraya bii awọn ti yoo kopa ninu idije 2026 World Cup tabi 2028 Olympics
  • Awọn eeyan kereje to ni fisa gẹgẹ bii awọn ti wọn n gbogun nitori ẹya tabi ẹsin ni Iran
  • Awọn ọmọ orilẹede Afghanistan to ni iwe irinna ti wọn n pe 'Special Immigrant Visas'
  • Awọn ti wọn ti ni iwe igbelu ilẹ Amẹrika
  • Awọn ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika amọ ti wọn tun jẹ ọmọ ilẹ mii

Wayi o,