Balogun Kuku: Akọni to mú Islam wọ ilẹ̀ Ijebu, bẹ̀rẹ̀ ọdún ojúde ọba, aya 65 tó ní kò jẹ́ kó gba ẹ̀sìn Kristẹni

Balogun Kuku Bello

Oríṣun àwòrán, BBC/Kuku Family

    • Author, Adedayo Owolabi and Afolabi Akinlabi
    • Role, Senior Journalist
    • Author, Afolabi Akinlabi
    • Role, Journalist
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ni ilẹ Yoruba, oniruuru awọn akọni jagunjagun lo wa, ti wọn ti se gudugudu meje ati yaaya mẹfa fun ilu ti wọn ti wa.

Ọpọ wọn lo ti gba ilu wọn silẹ lọwọ ogun ni aye atijọ, ti orukọ wọn si jẹ manigbagbe yika ilẹ Yoruba.

Lara awọn akọni jagunjagun yii ni Kosoko ni ilu Eko, Basọrun Ogunmọla ati Balogun Ibikunle nilẹ Ibadan, Sodeke ati Lisabi nilẹ Ẹgba, Sọun Ogunlọla nilẹ Ogbomoso ati Balogun Bello Kuku nilu Ijẹbu Ode.

Odu ni Balogun Kuku nilẹ Ijẹbu, ti ọpọ eeyan si mọ ile awodamiẹnu to kọ silu Ijẹbu Ode, eyi ti ọpọ awọn elere tiata ma n lo fun ere wọn lasiko yii.

Eyi lo gbe BBC Yoruba de ilu Ijebu Ode lati foju gan ni ile Balogun Kuku, ka si mọ nipa itan igbesi aye rẹ.

Balogun Kuku Bello ati aya rẹ

Oríṣun àwòrán, BBC/Kuku Family

"Kuku di 'Millionaire' ko to pe ọmọ ọdun mẹẹdogun nidi okoowo tita eroja ijagun"

BBC Yoruba ba Asiwaju fun idile Balogun Bello Kuku nilu Ijebu Ode, to tun jẹ Ọgbeni Ọja tilẹ Ijebu, Olorogun Ọmọwe Sunny Folorunso Kuku, sọrọ nipa itan aye akọni jagunjagun yii.

Olorogun Kuku, ti i se iran kẹfa si akọni jagunjagun naa ni, apetan orukọ baba nla idile awọn naa ni Bello Odueyungbo ( Ifa ko lọ sinu igbo) Bórogún.

Amọ oriki lasan ni Kuku jẹ fun baba naa eyi to pada di orukọ rẹ ti gbogbo idile rẹ n jẹ.

"Mama to bi baba nla wa yii ku laarin ọjọ mẹta to bi, mama mama rẹ lo tọ ọ dagba, to si kọ Kuku ni ọna okoowo.

Kuku n se okoowo karakata, to si n ta nnkan ijagun nilẹ Yoruba. Eyi lo sọ ọ di olowo tabua, milọnia, ko to pe ọmọ ọdun mẹẹdogun.

Bi ogun ba wa nilẹ Yoruba, ẹni ti Kuku ba se atilẹyin fun pẹlu nnkan ijagun, ni yoo bori ogun naa, to si ni orisirisi ọta ibọn to maa n ta fun ẹni kọọkan.

Awọn oyinbo Pọtugi ni Kuku n ba dowopọ, ti wọn n ko nnkan ijagun fun, to wa n ta a silẹ Yoruba.

Ogbeni Ọja salaye siwaju si pe idi katakara eroja ijagun yii ni Balogun Kuku ti di jagunjagun nitori o ni ibọn ati ọmọ ogun pupọ ti yoo daabo bo awọn to ba kọwọrin pẹlu rẹ.

"Bi ogun ba de, Balogun Kuku lo ma siwaju ogun fun ilẹ Ijẹbu, o lowo lọwọ, onisowo ni, to si maa n doju kọ awọn adigunjale.

Oun si ni Awujalẹ maa n lọ lati jagun bii ogun Kiriji, ohun si ni Olori awọn Parakoyi onisowo to di ẹgbẹ awọn onisowo Chambers of Commerce loni yii."

Oloye Sunny Folorunso Kuku, Ogbeni Oja tilẹ Ijebu ati Olori idile Kuku ni ilu Ijebu Ode
Àkọlé àwòrán, Oloye Sunny Kuku salaye itan igbesi aye babanla rẹ, Balogun Kuku Bello, fun BBC Yoruba

"Ọ̀tẹ̀ dìde sí Balogun Kuku, wọ́n jó ilé rẹ̀ kejì, ó kó lọ sílùú Ibadan, ó sì dá àdúgbò Ìsàlẹ̀ Ìjẹ̀bú sílẹ̀, nibẹ lo ti jẹ oye Balogun"

Ile awodamiẹnu ti Balogun Kuku kọ silu Ijebu Ode

Oríṣun àwòrán, BBC/Kuku Family

Nigba to n salaye awọn idojukọ ti Balogun Kuku Bello ri nigba aye rẹ, Oloye Sunny Kuku mẹnuba pe ọkan pataki ninu ipenija naa ni bi ilu Ijẹbu Ode se dide ọtẹ si baba nla awọn naa.

O ni ilu korira Kuku, wọn sọtẹ rẹ nilu Ijẹbu Ode, nitori naa si lo se ko kuro lọ silu Oru Ijebu, amọ ko pẹ nibẹ, to fi gba ilu Ibadan lọ.

Ogbeni ọja salaye pe wọn jo ile Kuku meji nilu Ijẹbu Ode amọ ile kẹta to kọ lo di awomaleelọ yii, se ile ọba to jo, ẹwa lo bu kun.

"Balogun Kuku lo tẹ agbegbe Isalẹ Ijẹbu do nilu Ibadan, to si jẹ ọrẹ timọ timọ fun Baalẹ to wa nipo nilu Ibadan nigba naa.

Baalẹ ọhun si lo fi Kuku jẹ Balogun, oye naa si lo gbe wa silu Ijẹbu Ode nigba to ya."

"Balogun Kuku kọ ile akọkọ ti wọn fi biriki mọ nilẹ Ijẹbu pẹlu eroja igbalode, o yọ yara pamọ sara ogiri, to n fi ẹru pamọ si lai si ẹni to le mọ"

Awọn ẹsọ ile ti Balogun Kuku fi se ile ni ọṣọ
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹni to ba de ile Balogun Kuku nilu Ijẹbu Ode yoo ki aje ku ikalẹ bi o tilẹ jẹ pe ọdun 1900 ni wọn pari ile naa, eyi to ti le ni ọgọfa ọdun ti wọn ti kọ.

Idi ni pe gbogbo eroja ti a n lo fun ile kikọ lode oni ni wọn fi kọ ile naa, to si tun duro sẹpẹ, lai si ibi to yinjẹ ninu rẹ.

Amọ ko si ẹni ti yoo de inu ile Kuku ti ko ni ki aje ku ikalẹ, to si han gbangba pe ile olowo ni ile naa, tori oun lo lowo julọ nilẹ Ijebu nigba naa.

Lara awọn eroja to n se ile lọṣọ ti a ri ninu ile naa ni ina Chandelier to n lo epo eebo Karosini, aga ijoko to ti lo ọgọfa ọdun, beba to se ara ogiri lọsọ ati awọn awo ti wọn fi n to ile.

Nigba to n salaye bi Balogun Kuku se kọ ile awosifila to wa nilu Ijebu Ode lẹyin to pada de lati Ibadan, eyi ti gbogbo eeyan n pe wa wo naa.

Sunny Kuku ni baba nla oun naa ko lo ewe lati kọ ile kẹta nitori bo se rọrun fawọn araalu nitori ikorira lati jo ile meji akọkọ to fi ewe kọ.

"Balogun Kuku gba awọn oyinbo lati orilẹede Brazil, lati lo biriki fun kikọ ile rẹ kẹta yii, ile naa si ni ile biriki akọkọ nilẹ Ijebu.

Biriki naa ko si ṣe e jo nina, to si fi eroja paanu aluminiọnu se orule rẹ, to si kọ ile naa ko maa ba rọrun fun araalu lati jo ile ọhun.

Odo Jọ̀lọ̀ ni wọn ti n mọ biriki naa, Jọlọ ni awọn oyinbo Potogi n pe biriki lede wọn.

Bi eeyan ba duro sori oke patapata ile yii, gbogbo ilu Ijebu Ode ni yoo maa wo."

Ogbeni Oja fikun pe ninu ile naa, Balogun Kuku ni awọn yara to n fi awọn ẹru rẹ pamọ si nitori onisowo ẹru tun ni.

O ni lara ogiri ni awọn yara kan wa, to n fi eeyan pamọ si, ko sisi ẹni to le mọ lai jẹ pe wọn sọ fun.

"Balogun Kuku gba lati di Krisitẹni amọ pasan lawọn aya rẹ fi na Pasitọ jade tori o ni iyawo kan ni Kuku gbọdọ mu laarin iyawo marundinlaadọrin to fẹ"

Awọn ibọn ti Balogun Kuku fi n jagun

Nigba ti Oloye Sunny Kuku n salaye ipa ti Balogun Kuku ko ninu awọn ẹsin igbalode ti igbagbọ ati Musulumi nilẹ Ijebu, ọrọ pọ ninu iwe kọbọ.

Lara ohun to pa ni lẹrin ni itan bi Balogun Kuku se gba lati di ọmọlẹyin Kristi amọ ti akude wọ igbesẹ rẹ naa.

Gẹgẹ bi Sunny Kuku ti wi, awọn Krisitẹni lo wọ ilu Ijẹbu Ode wa, ti wọn si wa waasu fun Balogun Kuku lati di ọmọlẹyin Kristi tori o ni ero pupọ.

"Balogun Kuku lo ni ilu, o si fẹran ẹsin Krisitẹni naa , to si gba lati di ọmọlẹyin Kristi amọ Pasitọ sọ fun pe yoo mu ọkan soso ninu iyawo marundinlaadọrin to ni.

Kuku wa sọ fun Pasitọ pe ko wa lọjọ kan lati wa se iribọmi fun oun, ti yoo si tun ba oun mu iyawo kansoso ninu awọn iyawo oun, ti yoo sẹku sinu ile.

Kuku pe awọn iyawo rẹ, to si salaye isẹlẹ yii fun wọn, awọn iyawo duro de Pasitọ, bo si se de, wọn ko pankẹrẹ bo Pasitọ, ti wọn si lu jade kuro ninu ile wọn."

Ogbeni Oja ni idi ree ti Balogun Kuku ko se di ọmọlẹyin Kristi mọ, se o kuku mọọmọ da ete fun Pasitọ ni, to fẹ ba le gbogbo iyawo rẹ danu."

"Balogun Kuku gba ẹsin Islam, ida aadọrun eeyan Ijebu Ode si tẹle lati di Musulumi, o si bẹrẹ ọdun Ojude Ọba"

Yara to wa ni abẹ ilẹ ninu ile Kuku, to maa n ko ẹru tuntun pamọ si

Oloye Sunny Kuku tẹsiwaju pe lẹyin ti Kuku ko di Krisitẹni mọ, wọn wa fi ẹsin Islam lọ ọ, to si tẹwọgba nitori ẹsin naa fun ni anfaani lati ni ọpọlọpọ iyawo.

"Bi Kuku se di Musulumi ni ida aadọrun eeyan ilu Ijebu Ode naa yipada di Musulumi, to si we lawani fun gbogbo wọn.

Awọn ẹlẹsin ibilẹ maa n lọ ki ọba Awujalẹ lasiko ọdun wọn ni ọdọọdun amọ bi Kuku ati awọn eeyan Ijebu Ode ṣe di Musulumi, ni wọn yi ikini naa pada si abẹwo si ọdọ ọba ni ọjọ kẹta ọdun Ileya.

Abẹwo asiko ọdun Ileya yii ni wọn pe ni Ojude Oba, ti Balogun Kuku yoo si lewaju awọn araalu lati lọ ki Awujalẹ.

Ẹsin Islam di itẹwọgba nilẹ Ijẹbu nitori Balogun Kuku, o lowo, o lọla, to si ni ero rẹpẹtẹ lẹyin."

Oloye Sunny Kuku fikun pe ti ọba igberiko ba yaju si Awujalẹ, Balogun Kuku ni wọn yoo ran lọ lati lọ koju rẹ.

Koda, akoko kan wa ti awọn oyinbo ni ko wa jẹ Awujalẹ amọ to kọ lati jẹ ọba nitori o ni iran oun kii jẹ ọba.

Awujalẹ wa fi Balogun Kuku jẹ oye Olorogun, to tumọ si Olori ogun, eyi ti idile Kuku n jẹ titi di oni oloni.