Kí ló fa ikú obìnrin tí wọn bá òkú rẹ̀ ní ọgbà Ṣọ́ọ̀ṣì l‘Osun, ta ló gé ìka ọwọ́ rẹ̀ lọ?

Ẹsẹ oku kan ti wọn gbe sile igbokusi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oku obinrin kan ni wọn ti ri ninu ọgba ile ijọsin kan to wa ni adugbo Obelawo nilu Osogbo, tii se olu ilu ipinlẹ Osun.

Koda, wọn ti ge ẹya ara obinrin naa lọ, to si han gbangba pe ọrun ọwọ alaafia obinrin naa ni wọn ti ge lọ.

Atẹjade kan ti alukoro ileesẹ ọlọpaanilẹ wa, Ani Iniedu, fisita lo sisọ loju isẹlẹ yii pẹlu afikun pe awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti lọ se ayẹwo si oku obinrin naa ni kete ti wọn gbọ nipa rẹ.

Atẹjade naa fikun pe iwadii awọn ọlọpaa fihan pe wọn mọọmọ pa obinrin naa ni, tawọn eeyan to pa a si ge ọrun ọwọ rẹ osi lọ.

"A ti gbe oku obinrin naa kuro nibi ti wọn ju si, ti a si ti gbe lọ sile iwosan fun ayẹwo to yẹ"

Bakan naa ni wọn fikun pe ileesẹ ọlọpaa ko tii le sọ nipa ohun to wa nidi isẹlẹ naa ati idi ti wọn se gbẹmi obinrin naa.

Amọ iwadii ti bẹrẹ lati se awari awọn eeyan to wa nidi isẹlẹ yii ati idi ti wọn se pa obinrin naa.

Atejade naa ni "A ti gbe oku obinrin naa kuro nibi ti wọn ju si, ti a si ti gbe lọ sile iwosan fun ayẹwo to yẹ.

Lẹyin naa la gbe sile iseokupamọ lọjọ si fun awọn ayẹwo gbogbo, ti ẹka ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ nileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun si ti iwadii nipa isẹlẹ yii."

Afurasí tó gún ₦56.4m owó Hajj tó gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn lọ́bẹ n'Ibadan fojú ba ilé ẹjọ́

Ajọ EFCC to n gbogunti iwa jibiti lorilẹede Naijiria ti fi oju ọkunrin kan, Lawal Babale Musa, ba ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo, lori ẹsun gbigba N56.4m lọwọ awọn eeyan kan gẹgẹ bii owo irinna fun iṣẹ Hajj, lorilẹede Saudi Arabia.

Ọjọbọ, ọjọ kẹtala oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni Musa jẹjọ lori ẹsun mẹtadinlọgọta (57) to ni i ṣe pẹlu ole jija ati iwe yiyi.

Gẹgẹ bi EFCC ṣe ṣalaye, awọn ti olujẹjọ lu ni jibiti owo naa ni: Jibril Adamu, Suleiman Aminatu, Musa Haruna, Suleiman N. Abdullahi, Audu Bello, Yusuf Umaru, Saidu Musa, Idris Suleiman, Musa Yunusa ati Usman Haruna.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ gan-an?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi ẹsun ti ajọ EFCC fi kan Lawal Babale Musa, ṣe wi, wọn ni o gba N56,491,000 lọwọ awọn eeyan naa laaarin ọjọ keji oṣu Kọkanla ọdun 2022, si ọjọ kejilelogun oṣu Keje ọdun 2024.

Ohun ti wọn lo sọ fun wọn ni pe oṣiṣẹ ajọ to n ri si irinajo Mecca nipinlẹ Kaduna, ((Kaduna State Pilgrims Welfare Agency) ni oun.

EFCC sọ pe Musa gba owo naa lati fi ba wọn ṣeto irin ajo Hajj ọdun 2023, eyi to ni ipasẹ ajọ to n ri si irinajo Mecca nipinlẹ Kaduna loun yoo fi ko wọn lọ.

Wọn fi kun un pe Musa tun yi iwe ẹri owo sisan ajọ to n ri si irinajo Mecaa nipinlẹ Kaduna.

EFCC sọ pe o yi iwe naa ti nọmba rẹ jẹ 0013041, orukọ ti wọn lo si wa nibẹ ni Jibril Adamu.

Iwe ẹri owo sisan keji ti wọn lo tun yi ni 012654, o si mu un fun Adamu gẹgẹ bii ojulowo.

Awọn eeyan ti EFCC sọ pe Musa lu ni jibiti yii jẹ darandaran lagbegbe Oke Ogun, ipinlẹ Oyo bi wọn ṣe sọ.

Amọ ko si eyi to ri Mecca naa lọ ninu wọn lẹyin ti Musa gba owo lọwọ wọn gẹgẹ bi alaye EFCC.

Musa loun ko jẹbi awọn ẹsun yii.

Oju afurasi Lawal Musa

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

Aṣẹ ile ẹjọ

Lẹyin ti olujẹjọ ni oun ko jẹbi, agbẹnusọ fun EFCC, Bashir Shamsuddeen, rọ kootu lati fi i pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn titi digba ti igbẹjọ yoo tun fi waye.

Amọ agbẹjọrọ rẹ, Kehinde Adegbola, ni ki kootu fi aaye gbigba oniduuro rẹ silẹ, nitori oun ti gbe igbesẹ lati ri i pe adajọ fi aaye beeli silẹ fun un.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Adajọ Olusola Adetujoye, paṣẹ pe ki wọn fi Musa pamọ si ọgba ẹwọn Agodi.

O sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹjọ yii.