Ṣé lóòótọ́ ni Ogogo ti jáde láyé? Ọmọ rẹ̀ ṣàlàyé

Taiwo Hassan Ogogo wọ Damaasi alawọ aro, o de fila, o lo ilẹkẹ sọrun o si fi aago sọwọ pẹlu ilẹkẹ.

Oríṣun àwòrán, Taiwo Hassan Ogogo/ Instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Lẹyin ti awọn ọmọ gbajumọ oṣere tiata Yoruba nni, Taiwo Hassan (Ogogo) kede pe aisan jẹjẹrẹ ti n ba a finra, adura alaafia ni gbogbo awon ololufẹ rẹ n gba fun un.

Amọ bi eyi ṣe n lọ lọwọ naa ni iroyin kan tun gbode pe oṣere ọmọ Yewa naa ti jade laye.

Lasan kọ ni awuyewuye iku naa gba ori ayelujara lọsan ọjọ Iṣẹgun ti i ṣe ọjọ keji ti Kira ati Lima kede aarẹ to n ṣe baba wọn,.

Lima ọmọ ogogo keji lo sare gbe ọrọ kan to kede iku naa soju opo Instagram rẹ, nigba naa si ni ariwo iku naa gbode.

Bo tilẹ jẹ pe Lima Taiwo ko jẹ ko pẹ rara to fi pa ohun to kọ soju opo naa rẹ, sibẹ, awọn aye ti ri i, wọn si ti bẹrẹ si i pin in ka.

Eyi lo fa a ti ọpọ eeyan fi n wadii otitọ, lati mọ boya oṣere ti ọpọ eeyan fẹran naa ti dagbere faye loootọ ni.

Ki ni ọmọ Ogogo kede?

Ọrọ mẹfa naa ni Lima Taiwo Hassan kọ soju opo naa lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii to fi kede ipapoda baba rẹ.

Ohun to kọ naa ree: Wọn ti pada lọ, sun ire baba.

Ọmọbinrin naa tun fi awọn ami to n ṣafihan ẹkun sibi ikede ọhun, o si fi ami ifẹ pari rẹ.

BBC News Yoruba pe Lima lori aago lẹyin eyi lati fidi atẹjade naa mulẹ, amọ aago rẹ ko lọ.

Bakan naa ni awọn eeyan kan ti bẹrẹ si i sọ pe Lima kọ lo gbe ọrọ naa si oju opo rẹ, wọn ni o ṣee ṣe ko jẹ ọgbọn arekereke ori ayelujara ni awọn kan ṣe lori ikede naa.

Amọ lati fi idi otitọ mulẹ, BBC News Yoruba kan si Olori TAMPAN, Bolaji Amusan (Mr Latin), ẹni to dahun pe oun ko fẹẹ sọ ohunkohun lori rẹ.

Eyi ni a ṣe pe ọlọpaa inu fiimu, Ọgbẹni Owolabi Ajasa to jẹ Gomina fun ẹgbẹ TAMPAN nipinlẹ Ogun, oun si da wa lohun pe:

Ikede iku Ogogo ti ọmọ rẹ obinrin gbe sori ayelujara

Oríṣun àwòrán, limataiwo_/Instagram

Emi ati Olu Ayinde, tii se aburo Ogogo sẹsẹ sọrọ tan laipẹ yii ni, ko si ohun to jọ pe ẹgbọn rẹ ti jade laye - Owolabi Ajasa

Owolabi Ajasa, Gomina TAMPAN Ogun, o wọsọ ọlọpaa alawọ aro o si de fila dudu

Oríṣun àwòrán, Owolabi Ajasa/ Facebook

Àkọlé àwòrán, Owolabi Ajasa

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Owolabi Ajasa ni iroyin naa ko ri bẹẹ rara.

"Emi ati Olu Ayinde, tii se aburo Ogogo sẹsẹ sọrọ tan laipẹ yii ni, ko si ohun to jọ pe ẹgbọn rẹ ti jade laye.

''To ba jẹ pe lootọ ni Ogogo ti dagbere fun aye, aburo wọn ko ba ti sọ fun mi.

"Emi ko si lọdọ Ogogo, n ko si ri i tabi mọ ipo to wa, tori naa, n ko le fidi rẹ mulẹ, amọ loore koore ni emi ati aburo wọn naa n sọrọ nipa ipo ti ilera wọn wa."

Bẹẹ ni Owolabi Ajasa ṣalaye.

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di irọlẹ ọjọ Iṣẹgun naa, Lima Taiwo naa pada sọrọ, o ni iroyin ofege ni pe baba oun ku, ki awọn to n pin in kiri yee ṣe bẹẹ.

Lima sọ pe Ogogo ṣi wa laye, ki ẹnikẹni yee pin iroyin iku rẹ kiri.

Ta ni Taiwo Hassan Ogogo?

Ọjọ kọkanlelọgbọn osu kẹwa ọdun 1959 ni wọn bi Taiwo Hassan, ti ọpọ eeyan mọ si Ogogo.

Ọmọbibi ilu Ilaro, to wa ni agbegbe Yewa nipinlẹ Ogun nii se, to si jẹ ibeji, tori ibeji ni wọn saba maa n bi ninu idile rẹ.

Bakan naa ni baba ati iya rẹ naa jẹ ibeji.

Ogogo pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ nile ẹkọ Christ Church nilu Ilaro, ko to morile ile ẹkọ girama Gazikia College nilu Eko.

Amọ Ogogo ko le pari ile ẹkọ girama naa tori ọda owo, lẹyin naa lo wa lọ sile ẹkọ ẹkọsẹ ọwọ nibi to ti kọ nipa isẹ atọkọse, ti a mọ si Mẹkaliki.

Gbajumọ osere tiata naa si sisẹ bii Mẹkaliki fun ọdun mẹtala gbako nileesẹ to n pese omi, water corporation.

Ogogo bẹrẹ isẹ tiata lọdun 1981 ni kete to bẹrẹ isẹ mẹkaliki, to si kuro lẹnu isẹ mẹkaliki nileesẹ Water Corporation lọdun 1994, ko le gbajumọ isẹ tiata to yan laayo.

Agba osere naa ti gba oniruuru ami ẹyẹ nidi isẹ tiata, to si tun gba ami ẹyẹ ipa to ko ninu ere Anikulapo, tii se Alaafin Oyo.

Àgbà òṣèré, Taiwo Hassan Ogogo ni àìsàn jẹjẹrẹ, a ń wá dókítà òyìnbó tàbí tí ìbílẹ̀ to le wò ó sàn - Àwọn ọmọ rẹ̀ figbe ta

Ogogo àti ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Collage

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gbogbo ẹ̀dá lọ máa ń gbàdúrà fún ìlera pípé láti gbé ilé ayé àmọ́ bí àìsàn bá dé, yóò kó ìpayà àti ìbànújẹ de.

Gbajugbaja ọṣèré tíátà ni èdè Yorùbá, tí ọ̀pọ̀ èèyàn nifẹ rẹ, Taiwo Hassan, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ogogo lọ tí ń ṣàìsàn to lágbára báyìí.

Àìsàn náà sì lo ni ṣe pẹ̀lú àìsàn jẹjẹrẹ.

Ọmọ Ogogo lobinrin, Shakira Taiwo lo fi Ikede yii síta pẹ̀lú ẹkún ńlá nínú fídíò kan tó ṣe láti fi béèrè fún ìrànwọ́.

Fídíò náà sì lo gbé síta lójú òpó Instagram rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí Shakira ṣe ń fi omijé ṣe àlàyé, ó ní àìsàn jẹjẹrẹ ọhun tí de ipele kẹrin.

"Ìdí sì nìyí tí àwọn dókítà ṣe sọ pé pé àwọn kò lè fún ní ìtọ́jú tí àwọn máa ń fún àwọn èèyàn tó bá ní àìsàn jẹjẹrẹ, tí a mọ̀ sí 'Chemotherapy' mọ."

Shakira Taiwo tẹsiwaju nínú ọ̀rọ̀ rẹ pé òun ko se fídíò náà láti fi tọrọ owo lọ́wọ́ ẹnikẹni.

O fikùn pé olùdíje sípò gomina lábẹ́ Asia ẹgbẹ́ òṣèlú APC nipinlẹ Ogun, Senatọ Solomon Adeola, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Yayi, lo tí ń gbọ́ bukata ìnáwó lórí àìsàn baba òun.

O wa dúpẹ́ lọ́wọ́ àgbà oloselu náà fún ọwọ́ àànú to n na si Ogogo.

Shakira wá sísọ lójú rẹ pé "Mo ń wá àwọn onisegun to lè tojú baba mi bayi lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ.

Bóyá àwọn onisegun oyinbo ni tàbí tí ìbílẹ̀.

Ẹ jọ̀ọ́ torí Ọlọ́run, bàbà mi kò fẹ́ kú, kò fẹ́ kú" Ọmọ Ogogo lọ ń fi ẹkún rawọ ẹ̀bẹ̀ sáwọn aráàlú náà."

Bákan náà ni Shakira ni inú ìrora ńlá ni bàbá òun wà báyìí, ẹnikẹ́ni tó bá sì lè wo àìsàn jẹjẹrẹ náà san, kí wọ́n kan sì òun tàbí àbúrò òun.

Bákan náà ni Shakira fi sita pé ó yẹ kí àgbà òṣèré náà tí lọ sí ilẹ̀ india fún ìtọ́jú àmọ́ kò le wọ bàálù torí àìsàn náà tí wọ ọ lára.

Ọmọ Ogogo, Shakira ń wá 3kun mú, ó wọ aṣọ kaba aláwọ̀ búlúù

Oríṣun àwòrán, Kira_Taiwo/Instagram

A kò mọ pé Baba mi ni àìsàn jẹjẹrẹ, ọṣẹ kẹta rèé tí a mọ̀ - Haleemah Taiwo

Bákan náà ni ọmọbìnrin Ogogo miran, Haleemah Taiwo náà ṣe fídíò miran, tí òun náà ń fi omijé sọ̀rọ̀ láti béèrè ìrànwọ́ ọwọ́.

"Baba mi nifẹ lati gbe ile ayé, kò tètè mọ pe oun ni àìsàn jẹjẹrẹ àmọ́ ó ti tàn ka ara rẹ.

Ọ̀sẹ̀ mẹta sẹ́yìn rèé tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ pe o ni àìsàn náà, táwọn dókítà sì lo tí kọjá ìtọ́jú.

A wá ń bẹ ẹnikẹ́ni to bá lè tojú rẹ, láti kan sì wà, a kò fẹ́ kí baba wá kú ó. "

Gbogbo àwọn ọṣèré tíátà bíi Toyin Abraham, Dayo Amusa àtàwọn míì sì lo n se alábàápín àwọn fídíò tí àwọn ọmọ Ogogo náà ṣe.

Wọn wá ń rọ àwọn onímọ̀ oyinbo àtàwọn onisegun ìbílẹ̀ to bá gbowọ, tí wọn lé wo àìsàn jẹjẹrẹ láti kan sì àwọn lórí aago.

Ọmọ Ogogo, Haleemah Taiwo náà ń sunkún láti bẹ̀bẹ̀ fún ìrànwọ́ aráàlú láti wá dókítà fún ìtọ́jú baba rẹ

Oríṣun àwòrán, Limataiwo_