"Orí ló kó wa yọ tí APC ò wọlé l'Osun, ọ̀pọ̀ wa kò bá fiṣẹ́ sílẹ̀ ni"- Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Osun

Awọn oṣiṣẹ ijọba Osun ree lasiko ti wọn lọ si ọfiisi Gomina Ademola Adeleke lọjọ Aje
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 14

Bi awọn eeyan ipinlẹ Osun ṣe n yọ ayọ ijaweolubori Gomina Ademola Adeleke fun saa keji, awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa ko gbẹyin pẹlu.

Tilu-tifọn ni awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Osun tu jade lati pade Gomina Ademola Adeleke lonii ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii, lẹyin aṣeyọri rẹ ninu idibo sipo gomina ipinlẹ naa lẹẹkan si i to waye lọjọ Abamẹta to kọja.

Niṣe ni awọn oṣiṣẹ naa tu yaaya jade lati ba gomina yọ lọfiisi rẹ to wa nile ijọba Abeere, niluu Osogbo.

Awọn oṣiṣẹ naa fi idunnu wọn han lori ija iṣẹgun ti gomina Adeleke ja to si bori rẹ, nibẹ naa ni ọpọlọpọ wọn si ti ni:

"A dupẹ pe APC ko wọle, pupọ wa ko ba fiṣẹ ọba silẹ ni"

Ninu ọrọ ti awọn oṣiṣẹ naa sọ lasiko ti wọn lọ si ọfiisi Gomina Adeleke ni wọn ti ni ori lo ko awọn yọ ti ẹgbẹ oṣelu APC ko jawe olubori ninu eto idibo to kọja naa.

Awọn oṣiṣẹ ijọba naa sọ pe ọpọlọpọ ninu awọn ko ba kọwe fi iṣẹ silẹ bayii ni.

Wọn ni awọn dupẹ lọwọ Ọlọrun to jẹ ki erongba awọn lori gomina Adeleke wa si imusẹ.

Ninu ọrọ Alaga awọn oṣiṣẹ, ẹka ti ipinlẹ Ọsun, Christopher Arapasopo, o ni oun dupẹ pupọ lọwọ awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ọsun ti wọn ko doju ti oun.

Arapasopo sọ pe inu oun dun pe wọn gbọrọ si oun lẹnu, wọn si fi ibo wọn gbe Gomina Adeleke wọle lẹkeji.

O waa bere fun atilẹyin gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọsun, o ni ki wọn fọwọsowọpọ fun Gomina Adeleke ni saa to fẹ bẹrẹ, ki gbogbo nnkan tun le rọ gbogbo oṣiṣẹ lọrun si i.

Bakan naa lo rọ wọn lati ma ṣe ba ẹgbẹ oṣelu kankan ja, o ni adura alaafia ni ki wọn maa gba fun ipinlẹ Ọsun.

Amọ bo tilẹ jẹ pe lati aago meje owurọ ni awọn oṣiṣẹ naa ti peju-pesẹ si ẹnu ọna ọfisi ijọba ipinlẹ Ọsun, ti wọn n reti Gomina Adeleke, Gomina ko de si aarin wọn titi ti aago kan ọsan fi lu, ti akọroyin BBC News Yoruba si fi kuro nibẹ.

Ṣugbọn ko sẹni to koro oju si eyi ninu awọn oṣiṣẹ naa, wọn n fo fun ayọ nitori aṣeyọri Adeleke ni.

Ki lo mu ayọ awọn oṣiṣẹ naa kun to bẹẹ?

Ẹ o ranti pe lasiko ijọba Gomina Rauf Aregbesola gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Osun, awọn oṣiṣẹ ijọba koju iṣoro ai si owo oṣu wọn gba deede.

Fun awọn asiko kan, idaji owo oṣu (Half salary) ni ijọba naa n san fun wọn, eyi ti wọn fi maa n da aṣa laarin ara wọn pe "Afusa'' ni owo oṣu tawọn n gba.

Amọ eyi yipada nigba ti Gomina Ademola Adeleke de, to si bẹrẹ si i sanwo oṣu to pe fun wọn.

Bakan naa ni owo ijọba ibilẹ to di ariwo, eyi ti Adeleke tun bẹrẹ si i mojuto to si n san deede tun jẹ idi kan ti awọn oṣiṣẹ fi fẹran rẹ, ti wọn si fi n sọ pe Imọlẹ lẹẹkan si i .

Eyi naa lo si fa a ti wọn fi dibo fun un lẹkun-un rẹrẹ, ti wọn si fi ayọ wa si ọfiisi rẹ lati fi idunnu wọn han si aṣeyọri Adeleke lẹẹkan si i.

Wo kókó pàtàkì méje tó gbé Adeleke wọlé sípò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì l'Osun àti àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìbò náà

Gomina Adeleke lo n gbe ọwọ soke lasiko ọkan lara awọn ipolongo idibo to ṣe laipẹ yii nipinlẹ Osun

Oríṣun àwòrán, Gov Ademola Adeleke/X

Àkọlé àwòrán, Ademola Adeleke

Lopin ọsẹ to kọja yii, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni eto idibo gomina waye nipinlẹ Osun, ẹkun Iwọ-Oorun ilẹ Naijiria, nibi ti awọn araalu ti jade lọpọ yanturu lati ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bi ọmọ Naijiria rere.

Oniruuru iṣẹlẹ manigbagbe lo ṣẹlẹ lasiko eto idibo to gbe Ademola Adeleke pada sipo gomina ipinlẹ naa fun saa keji, eyi ti ajọ eleto idibo INEC kede rẹ lọjọ Aiku to kọja.

Idi ree ti BBC News Yoruba ṣe ṣewadi awọn koko meje pataki to gbe Gomina Adeleke wọle sipo naa fun ọdun miran.

Adeleke lo du ipo ọhun pẹlu awọn oludije mẹrinla miran bii Bola Oyebamiji tẹgbẹ oṣelu APC to ṣe ipo keji, ati Najeem Salaam I ẹgbẹ oṣelu ADC to ṣe ipo kẹta.

Ibo to lẹ ni idaji miliọnu kan (511,067) ni Adeleke ni, nigba ti Oyebamiji ni ibọ to le lẹgbẹ lọna irinwo (444,815), leyi to jẹ ki Adeleke bori pẹlu ẹgbẹrun mẹrindinlaadọrin (66,252).

Ki wa ni awọn nnkan to gbe Adeleke pada sipo naa fun saa keji?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ariyanjiyan to n lọ nigboro bayii ni pe gomina to wọle fun saa keji yii, kii ṣe ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣakoso ilẹ Naijiria lati oke, iyẹn All Progressives Congress (APC).

Ẹgbẹ oṣelu Accord ni Adeleke ti jade lati du ipo naa fun igba keji, to si bori.

Ọmọwe Murtala Adogi Mohammed to jẹ ogbontarigi nibi ọrọ oṣelu ati okoowo sọ pe ohun meje pataki lo ṣe iranwọ fun Adeleke lati bori ibo gomina.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, Ọmọwe Mohammeds sọ pe nigba toun n ṣiṣẹ pẹlu ajọ UNICEF laaarin ọdun 2016 si 2021 loun ti ṣe awọn agbeyẹwo kan lori ọrọ eto oṣelu ati ọrọ aje awọn ipinlẹ mẹfa lẹkun Iwọ-Oorun Naijiria.

"Laaarin ọdun 2016 si 2021, nigba ti mo n ṣiṣẹ pẹlu ajọ UNICEF lẹkun Iwọ-Oorun to wa n iluu Akurẹ, mo ṣe awọn agbeyẹwo lori eto oṣelu ati ọrọ aje lẹkun mẹfa to wa ni ẹkun Iwọ-oorun," Ọmọwe Mohammed sọ bẹẹ.

O sọ siwaju pe "Ninu awọn nnkan to ye mi nigba naa, awọn ohun pataki ti mo lero wi pe o kopa nibi eto idibo ipinlẹ Osun to waye ree."

Àánú àwọn aráàlú sí Adeleke

Gẹgẹ bi Murtala ṣe sọ, lilo agbara ijọba apapọ ati oṣelu lasiko ipolongo idibo fi anfaani silẹ lati jẹ ki awọn eeyan ri Gomina Ademola Adeleke ati awọn ara ipinlẹ Osun gẹgẹ bi ẹni to wa labẹ kọlu, ti wọn si n wa iranlọwọ atokewa.

Iṣẹlẹ naa, ninu ero ọkan rẹ, sọ pe o mu ki awọn eeyan bẹrẹ sii kaanu rẹ, to si tun ro igboya ipinẹ naa lagbara.

Kaka ki awọn adojukọ naa ko irẹwẹsi ọkan ba Adeleke, "niṣe lo sọ eto idibo naa di ijakadi lati daabo bo iyi ipinlẹ naa, ati ominira fun gbogbo eeyan ipinlẹ Osun," Ọmọwe Murtala sọ bẹẹ.

Ipa àti akitiyan Davido

Gbajugbaja olorin takasufee nni, David Adeleke tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Davido ko ipa ribiribi lati mu imugbooro ba eto ipolongo idibo to gbe Ademola Adeleke wọle sipo gomina.

Murtala sọ pe okiki ati ipa lati ko ọpọ awọn eeyan jọ, eyi ti olorin naa ni, ṣe iranlọwọ to pọ fun iyasipo ẹlẹẹkeji fun Gomina Adeleke.

Davido ni awọn eeyan ri, to n lọ kaakiri lati polongo ibo fun Adeleke, to fi jẹ pe bo ṣe n farahan, naa lo tun n lo awọn ikanni ayelujara rẹ lati fi ṣe ipolongo.

Koda, bi eto idibo ọhun tun ṣe sunmọ to, Davido tun kọwe ranṣẹ si aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump fun iranlọwọ, loju opo 'X' rẹ.

Igboya tí àwọn aráàlù ni

Ohun miran ti Ọmọwe Murtala lo tun ko ipa to jọju ni igboya ti awọn ara ipinlẹ Osun ni.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o sọ pe awọn oludibo fi igboya ati ọkan akikanju wọn han lati dojukọ oniruuru iṣoro idunkooko to le de ba wọn lọjọ idibo.

Ṣugbọn ṣa, o sọ pe awọn araalu duro ṣinṣin lati rii pe awọn dibo, ati pe awọn yoo duro ti ibo wọn, titi digba ti awọn yoo fi ṣe aṣeyọri.

Ìlànà ètò ìpolonogo ìdìbò tí wọ́n pilẹ̀ rẹ dàadàa

Akọṣẹmọṣẹ nipa ijọba naa sọ pe awọn araalu lo oniruuru ọna bii orin, aṣamọ, ewi at'awọn mi-in lati lati fi atẹjiṣẹ ọrọ oṣelu ati ẹhonu wọn han.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ọgbọn naa lo tun fun awon alatilẹyin Adeleke lagbara sii, to si ko irẹwẹsi ba ipolongo awọn ẹgbẹ alatako.

Àwọn iṣẹ́ àkànṣe orí ilẹ̀

Murtala tọka aṣeyọri Adeleke si iṣakoso rẹ to gbajumọ oniruuru awọn iṣẹ akanṣe to ṣee foju ri, ṣaaju eto idibo to waye.

Ninu ero rẹ, awọn iṣẹ akanṣe tuntun ti gomina tun dawọ le, lo fun un ni anfaani lati le ṣalaye awọn aṣeyọri ijọba rẹ, to si tun jẹ ko di mimọ pe ọpọlọpọ iru rẹ ṣi n bọ.

EYi gan an lo fun awọn araalu ni igboya lati ronu jinlẹ.

Ìgbaradì fún ìtakùrọ̀sọ

Ohun pataki miran to tun tọka si ni bi igbimọ rẹ ṣe gbaradi fun itakurọsọ awọn oludije, eyi to waye.

O ni awọn igbimọ oludamọnran rẹ ṣe atungbekalẹ awọn ọrọ ti Adeleke yoo sọ, ti wọn si ti mura silẹ fun oniruuru awọn ibeere to ṣee ṣe ko jẹyọ, nigba to ba farahan nibi itarukọsọ.

Gẹgẹ bi Ọmọwe Murtala ṣe sọ, o ni bi Adeleke ṣe sọrọ nibi itakurọsọ to waye tun fi fojusun ati erongba rere sọkan awọn araalu, eyi lo si jẹ ki awọn to n ṣiye meji tẹlẹ nipa ipo adari ati ipa rẹ tun ero wọn pa.

Ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí mọ̀lẹ́bí Adeleke

Murtala sọ siwaju pe aṣeyọri Adeleke ko wa lati ọdọ rẹ nikan, bi ko ṣe pe itan ti idile rẹ ti ni lati ẹyin wa nipa ifẹ si awọn araalu lo tubọ ṣe iranlọwọ nla.

O ni ifẹ yii lo jẹ orirun to ti wa nilẹ tẹlẹ, ko to di pe Ademola Adeleke jade sita, to si n tẹsiwaju lati iran kan de iran miran.

Àwọn ẹ̀kọ́ ti a ri kọ nipa idibo gomina ipinlẹ Osun

Ni akotan, Ọmọwe Murtala sọ pe ẹko pataki ti eto idibo naa ṣafihan rẹ ni pe agbara oṣelu nikan ko to lati bori eto idibo.

Gẹgẹ bo ṣe sọ ninu ọrọ rẹ, o ni aṣeyọri le wa lati igbagbọ ti awọn eeyan ni ninu ẹni, ibaṣepọ oludije si awọn oludibo, ipalẹmọ rere, awọn igbesẹ to ṣee foju ri, ati ifarajin awọn araalu lati daabo bo ifẹ ọkan wọn.

Àwọn ìdí míràn

Yatọ si awọn idi pataki ti ỌMọwe Murtala ṣagbekalẹ yii, awọn miran tun sọ pe oniruuru nnkan miran lo tun ṣiṣẹ fun aṣeyọri Adeleke.

Lara wọn ni iroyin to n lọ nigboro wi pe gomina ni agbara lati san owo oṣu awọn oṣiṣẹ ati igbayegbadun wọn.

Wọn tun gbe oriyin fun akitiyan INEC, paapaa lilo ẹrọ BVAS lati fi ṣakojọpọ esi idibo, leyi ti wọn lo ṣe iranlọwọ lati ṣe adinku ba jibiti idibo

Èrò àwọn èèyàn ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí bí Ademola Adeleke ṣe wọlé ṣáá kejì sípò gómìnà Osun

Gomina Ademola Adeleke lo mu ẹrọ gbohungbohun dani, o si n sọrọ pẹlu igo dudu loju rẹ

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/Others

Àkọlé àwòrán, Gomina ipinlẹ Osun

INEC sọ pe Adeleke bori pẹlu ibo to le ni ẹẹdẹgbẹta (511,067), eyi to fi bori awọn alatako rẹ ti wọn jọ du ipo ọhun.

Kaakiri ijọba ibilẹ ọgbọn ti eto idibo ọhun ti waye, Adeleke bori ni ijọba ibilẹ mọkandinlogun, nigba ti Bola Oyebamiji to ṣe ipo keji bori lawọn ijọba ibilẹ mọkanla.

Giwa agba fasiti apapọ to wa niluu Oye Ekiti, Ọjọgbọn Joshua Ogunwole to jẹ alakoso eto idibo ọhun lo kede Adeleke ni deedee agogo meje kọja iṣẹju mẹrinlelogun ọjọ Aiku, lẹyin akojọpọ gbogob idibo ti awọn araalu di kaakiri.

Awọn ijọba ibilẹ bii Ariwa Ede, Guusu Ede, Ejigbo, Iwo, Egbedore, Ariwa Ife, Ila-Oorun Ife, Aarin-Gbungbun Ife, Oriade, Ifelodun, Orolu, Ayedaade, Ayedire, Odo Otin, Boluwaduro, Iwọ-Oorun Ilesa, Ifedayo, Osogbo ati Ayedire ni Adeleke ti jawe olubori.

Oyebamiji, lo gbegba oroke lawọn ijọba ibilẹ bii Irewole, Isokan, Olorunda, Ila-Oorun Atakumosa, Iwọ-Oorun Atakumosa, Ila-Oorun Ilesa, Boripe, Irepodun ati Obokun.

Alakoso eto idibo naa, Ogunwole ninu ọrọ rẹ sọ pe: "Wi pe lẹyin ti Ademola Nurudeen-Jackson Adeleke ti ṣe awọn ohun amuyẹ labẹ ofin, mo wa kede rẹ gẹgẹ bi oludije to jawe olubori nibi eto idibo gomina to waye lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, to si pada sipo naa fun saa keji."

Latigba naa ni oniruuru ọrọ ti n jade lori bi Adeleke ṣe wọle sipo gomina lẹẹkeji, to fi jẹ pe nigba ti awọn kan n kii ku oriire, awọn miran n pe fun iwadii lẹkunrẹrẹ lori eto idibo ọhun.

Idi ree ti BBC News Yoruba ṣe ṣe akojọpọ ero awọn araalu nipa abajade eto idibo naa.

Àwọn aráàlú fi ìbo wọn sọ̀rọ̀ - Atiku

Igbakeji aarẹ tẹlẹ nilẹ Naijiria, Atiku Abubakar ti gbe oṣuba kare fun Gomina Ademola Adelele lori aṣeyọri to ṣe nibi eto idibo to waye lọjọ Abamẹta to kọja.

Atiku Abubakar to jẹ oludije sipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC lo fi ọrọ ikini yii ranṣẹ lẹyin ti ajọ eleto idibo INEC kede Adeleke gẹgẹ bi oludije to jawe olubori.

Ninu ọrọ rẹ to fi soju opo 'X' laaarọ oni, Atiku sọ pe "Mo ki Gomina Ademola Adeleke ku oriire lori iyansipo lẹẹkeji gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Osun. Aṣeyọri rẹ lo ṣafihan ẹni ti awọn araalu n fẹ nipa idibo wọn.

Bakan naa lo tun gbe oriyin fawọn araalu lori bi wọn ṣe gba alaafia ati iṣọkan laaye lasiko eto idibo naa.

"Mo gbe oṣuba kare fun awọn eeyan lori ọkan akikanju ati itara ifẹ lati kopa. Mo rọ Gomina Adeleke lati tẹsiwaju awọn aṣeyọri to ti bẹrẹ lati maa sin awọn araalu," Atiku sọ bẹẹ.

Obi, Kwankwaso, Saraki kí Adeleke

Oludije sipo aarẹ Naijiria, Peter Obi ninu ọrọ to fi soju opo 'X' rẹ lọjọ Aiku fi imọ riri han si eto idibo to waye ọhun, to si ni aṣeyọri nla lo jẹ fun Adeleke to pada sipo gomina lẹẹkeji.

O ni eto idibo naa ṣafihan wi pe awọn araalu ni agbara lati yan olori wọn.

"Mo ki Gomina Ademola Adeleke lori eto idibo to gbe e pada sipo lẹẹkeji, bẹẹ ni mo ki awọn ara ipinlẹ Osun fun aṣeyọri eto iṣejọba awa-ara-wa naa," Obi sọ bẹẹ.

Bẹẹ lo sọ pe "Awọn ara ipinlẹ Osun ti sọrọ pẹlu igboya ati idaniloju, ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe agbara lati yan awọn adari wa lọwọ awọn araalu.

"Ẹkọ ti eto idibo Osun mu wa ni pe: iṣejọba awa-ara-wa lagbara nigba ti awọn araalu ba ṣe ojuṣe wọn, ti wọn si fi ibo yan ẹni ti wọn fẹ ko dari wọn.

"Gbogbo idibo ni a gbọdọ bọwọ fun, ati pe gbogbo iyansipo ni a gbọdọ daabo bo."

Aarẹ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ nilẹ Naijiria, Bukola Saraki, ninu ọrọ toun naa kọ soju opo 'X' rẹ sọ pe idibo igboya lo waye nipinlẹ Osun.

"Mo ki arakunrin mi ati ọrẹ mi, Gomina Ademola Adeleke lori iyasipo pada lẹẹkeji.

"Awọn ara ipinlẹ Osun ti sọrọ, wọn si ti sọrọ to ṣoju-ṣaara. Wọn ti ni ọdun mẹrin lati ṣe idajọ iṣejọba to dara, ati lati ṣagbeyẹwo awọn ileri ati iṣẹ akanṣe to pe ye, wọn si ti sọ pe ko maa tẹsiwaju."

Bakan naa, Gomina tẹlẹ nipinlẹ Kano, Rabiu Kwankwaso ninu ọrọ tiẹ naa loju opo 'X' fi idunnu han si ẹni to pe gẹgẹ bi ọrẹ rẹ, Ademola Adeleke lori aṣeyọri eto idibo to waye l'Osun.

"Gẹgẹ bi olori ẹgbẹ alatako, ati ẹni to to farajin ninu eto oṣelu awa-ara-wa, mo gbe oṣuba kare fun awọn eeyan ipinlẹ Osun lati ṣe ojuṣe wọn, ati ṣiṣe afihan agbara araalu.

Kwankwaso sọ pe abajade eto idibo naa lo ṣafihan pataki kikopa ninu eto idibo, paapaa lati jẹ ki ohun araalu jade sita.

"Aṣeyọri yii lo ran wa leti wi pe awọn araalu ni ojuṣe ti wọn gbọdọ farajin fun, lati jẹ ki ohun wọn jade sita lati gbọ. Ifẹ araalu gbọdọ jọba," Kwankwaso sọ bẹẹ.

Mo ṣì n retí Oyebamiji láti kí mi kú oríire

Nigba to n fi idunnu rẹ han, Adeleke loun dupẹ gidigidi lọwọ Ọlọrun ati awọn ara ipinlẹ Osun lori aṣeyọri naa.

Gomina naa sọ pe oun ṣi n reti alatako rẹ, Bola Oyebamiji lati pe oun lori foonu, ko si ki oun ku oriire lẹyin aṣeyọri eto idibo to waye.

O ni aṣeyọri naa lo waye gẹgẹ bii igbiyanju si eto iṣejọba awa-ara-wa, ati ẹbun fun awọn ara ipinlẹ Osun fun aṣeyọri iṣakoso rẹ.

"Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun alagbara. O jẹ aṣeyọri fun eto iṣejọba awa-ara-wa. Aṣeyọri fun eto idibo ipinlẹ Osun," Adeleke sọ bẹẹ lẹyin ikede naa.

"Aṣeyọri yii lo jẹ ọna ti awọn ara ipinlẹ Osun fi san an pada fun mi lẹyin idagbasoke lẹka iṣẹ akanṣe, eto ilera, eto aabo ati awọn miran ti mo ti fifun awọn eeyan mi."

"Mo n reti oludije lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Oyebamiji lati pe mi, ko si ki mi ku oriire. Mo ni Ọlọrun ti kii kuna."

Bakan naa lo dupẹ lọwọ Aarẹ Bola Tinubu, to fi mọ gbogbo awọn alatilẹyin rẹ kaakiri agbaye lori eto idibo to waye naa.

Àjọ SERAP rọ INEC, EFCC, ICPC àtàwọn míìn láti ṣe ìwádìí màgàmágó tó ṣẹlẹ̀ lásìkò ètò ìdìbò Osun

Ajọ kan to n ri sọrọ ẹtọ araalu ati ilana iṣẹ akanṣe, SERAP ti rọ ajọ INEC, EFCC, ICPC lati tọpinpin awọn iṣẹlẹ ti ko bofin mu, eyi to ṣẹlẹ lasiko eto idibo ọhun.

SERAP lo sọ eyi ninu atẹjade ti wọn fi soju opo ayelujara wọn lọjọ Aiku, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe oniruuru iwa fifi owo ra ibo, ṣiṣe idunkooko ati iwa ipa lo ṣẹlẹ lasiko eto idibo gomina ipinlẹ Osun.

"A n rọ awọn ajọ yii lati tọpinpin, ṣe iwadii awọn iroyin nipa fifi owo ra ibo, fifi owo lọ awọn eeyan, ṣiṣagbatẹru eto idibo pẹlu owo, idunkooko, iwa ipa, aṣilo ohun ini ijọba ati awọn iwa miran to tako eto idibo, eyi to ṣẹẹ nibi eto idibo gomina ipinlẹ Osun," SERAP sọ bẹẹ.

Bakan naa ni wọn tun rọ awọn ajọ naa lati "pe awọn oniṣẹ iwadii ati ajọ iṣọkan ilẹ Africa bii AU, ECOWAS, ACHPR atawọn miran fun iranlọwọ ninu iṣẹ iwadii ti ko ni kọlọfin ninu."

SERAP sọ pe awọn ajọ yii ni lati mọ ipilẹ awọn to n fi owo ra ibo, awọn to n ṣe idunkooko ati awọn iwa miran to tako ofin ati ilana eto idibo.