Ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé cocaine $28m tó ń lọ sí UK, ọwọ́ ba gbajúmọ̀ orí ayélujára kan àti ẹlòmíì

Oríṣun àwòrán, NDLEA
Ajọ NDLEA to n ri si oogun oloro lorilẹede Naijiria ti kede gbigbe ẹsẹ le oogun oloro cocaine ti iye rẹ din diẹ ni miliọnu mejidinlọgbọn owo dọla $27.7m, eyi to jẹ biliọnu mọkandinlọgbọn (39bn) bi a ba ṣẹ ẹ si owo naira.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, orilẹede United Kingdom ni awọn to gbe oogun naa n gbe e lọ ki ọwọ ofin too ba wọn.
Iwọn rẹ bi wọn si ti kede jẹ 184.5kg. Inu apoti alawọ ẹrupẹ pupa ni wọn ṣe awọn oogun oloro naa lọjọ si, ilu Eko ni aṣiri naa si ti tu lọjọ kẹta oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii.
Bi aṣiri ikọ to n gbe cocaine naa lọ ṣe tu ni ọwọ ba awọn afurasi meji ti wọn pe orukọ wọn ni Afolabi Kazeem Micheal ati Lawal Mujab Kehinde.
Bawo ni aṣiri ṣe tu?
Ajọ NDLEA ṣalaye pe ikọ kan to maa n fi oogun oloro ranṣẹ silẹ okeere lati ọdun pipẹ sẹyin, ti wọn si maa gba Naijiria fi ranṣẹ lo tun wa nidii eyi naa.
Wọn ni awọn ilu bii UK, apa kan Europe ati Asia ni wọn maa n fi oogun oloro naa ranṣẹ si.
Ngba ti NDLEA n ṣe iwadii ikọ naa ni ọwọ wọn ba afurasi kan; Afolabi Kazeem Micheal, ẹni ti wọn ni sọrọsọrọ ni lori ayelujara, ati pe o ni to eeyan ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (700,000) ti wọn n tẹle e loju opo Instagram.
Orukọ ti NDLEA sọ pe o n jẹ loju opo naa ni KC Luxury, ẹni ọdun mọkandinlaadọta (49) ni wọn pe e, oun ni wọn lo si jẹ aṣiwaju ikọ oloogun oloro naa.
NDLEA fi kun un pe oniṣowo ni Afolabi n pe ara rẹ lori ayelujara, goolu lo ni oun n ta nibẹ to si maa n sọrọ lorii rẹ.
Amọ ajọ to n ri si oogun oloro yii sọ pe KC Luxury n fi eyi bo oju ni.
Wọn ni cocaine lo n gbe lati America, ti yoo gbe e gba Naijiria ko too taari rẹ si Europe ati Asia.
Ọwọ ba afurasi yii lọjọ kẹtala oṣu Kẹjọ ọdun 2026, niluu Eko, ni papakọ ofurufu Murtala Mohammed International Airport, lasiko to n pete ati kuro ni Naijiria lọ si Paris, to si fẹ wọ baalu ipele awọn awọn oniṣowo (business-class).
Owo ti iye rẹ jẹ €7,750, £2,800 ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira (N100,000) ni NDLEA sọ pe awọn ba lọwọ rẹ nigba tọwọ ba a lẹnu ọna abawọ baaluu.
Alaye NDLEA lori afurasi keji
Afurasi keji ti ajọ NDLEA mu ni Lawal Mujab Kehinde, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn( 33).
Kehinde ni wọn lo jẹ oṣiṣẹ nileeṣẹ kan to maa n fi ẹru ranṣẹ, ileeṣẹ naa ni wọn lo ṣe ọna ti cocaine ọhun fẹẹ gba.
NDLEA sọ pe Kehinde lo di oogun oloro naa, o tẹwọ gba owo rẹ ni kiṣi.
Bakan naa ni ajọ yii sọ pe awọn afurasi yoku ti wọn jọ n ṣiṣẹ yii ni UK naa ti bọ sọwọ ofin, awọn ajọ tibẹ ni wọn lo fi ṣinkun ofin gbe wọn.
Ọga agba ajọ NDLEA, Ọgagun Buba Marwa, ṣalaye pe mimu ti wọn mu awọn eeyan yii n fi aṣeyọri to ṣee ṣe han, nigba ti awọn ajọ bi eyi ba sowọpọ.
Ọgagun Marwa sọ pe NDLEA ko ni i sinmi nipa mimu awọn to n gba ọna egbogi oloro di olowo.
"A maa dọdẹ yin de ẹnu ibode ibi tẹ ẹ ti fẹ sa lọ tọrọ ba gba bẹẹ."
Bẹẹ ni ọga agba NDLEA sọ.
Àlàyé NDLEA rèé tó ṣe dáná sun òògùn olóró tí iye rẹ̀ tó ₦301bn l'Eko

Oríṣun àwòrán, NDLEA/X
Awọn eeyan to n ti inu gbigbe oogun oloro ati tita rẹ di ọlọ́rọ̀ niluu Eko ti padanu obitibiti Cocaine, Heroin, atawọn mi-in si ọwọ ajọ NDLEA to n gbogun ti oogun oloro.
Niṣe ni NDLEA dana sun awọn nnkan mimu naa ti owo rẹ to ₦301bn.
Ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni wọn dana sun awọn nnkan naa niluu Eko.
Ìwọ̀n awọn oogun oloro naa ati ibi ti NDLEA ti dana sun wọn
Gẹgẹ bi NDLEA ṣe pe onka awọn oogun oloro ti wọn dana sun naa loju opo X wọn, wọn ni o ju iwọn 329,865 lọ, owo rẹ si to biliọnu ookan le ni ọọdunrun naira (₦301 billion).
Ita gbangba ni wọn ti dana sun awọn oogun oloro ti wọn ti gbẹsẹ le tẹlẹ naa, Navy Town lagbegbe Ojo, nipinlẹ Eko ni wọn ti sọna si i.
NDLEA ṣalaye pe ile ẹjọ lo paṣẹ pe kawọn yanju awọn nnkan to n ṣe ara ni ijamba tawon ti gba lọwọ awọn to n huwa ọdaran naa.
Lara awọn oogun oloro ti wọn dana sun naa ni ọkan ti wọn fi oriṣi mẹfa po pọ.
Awọn yoku ni Cocaine, Heroin, Methamphetamine, Ephedrine, ewe Khat, Tramadol ati Codeine to wa fun itọju ara riro nla, amọ tawọn eeyan ti sọ di oogun oloro nipa amuju rẹ.
Bakan naa ni awọn oriṣi igbo mimu ọlọkan-o-jọkan wa nibẹ, awọn bii eyi ti wọn n pe Loud ati Skunk.
Láàárín 2025 si 2026 ni NDLEA gbẹsẹ le awọn oogun oloro naa
NDLEA ṣalaye pe laaarin oṣu Kẹrin ọdun 2025 si oṣu Karun-un ọdun 2026 ni awọn gbẹsẹ le awon nnkan wọnyi niluu Eko.
Ajọ naa sọ pe o to iwọn 246,864.535 nnkan oloro ti oun dana sun.
Wọn fi kun un pe afikun ogun oloro ti iwọn rẹ to 83,001.05 naa wa lara eyi tawọn ẹka pataki kan l'Eko gba, titi kan awọn eyi ti wọn gba ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed International Airport (MMIA), ati Tincan .
Alaga NDLEA to tun jẹ ọga agba ajọ naa, Ajagunfẹyinti Ọgagun Mohamed Buba Marwa, ṣapejuwe awọn oogun oloro rẹpẹtẹ ti wọn dana sun yii bii ọna kan lati da aabo bo awọn ọmọ Naijiria, ati igbogunti imukumu tawọn kan fi n ṣe okoowo.
"Ibi yowu ki o sa si, ẹni yowu to n ṣe onigbọwọ fun ọ, bo si tilẹ wu ki imọ igbalode yin le to, ọwọ ofin yoo tẹ ọ"
Ọgagun Marwa lo kilọ bẹẹ.
"Awọn bandiiti, ajinigbe, adigunjale, agbesunmọmi ati bẹẹ bẹẹ lo n lo awọn oogun oloro wọnyi bii eemi ti wọn n mi simu"
Bakan naa ni ọga agba ajọ Aṣọbode ilẹ Naijiria, Bashir Adewale Adeniyi, nigba to n sọrọ lori igbesẹ NDLEA yii, sọ pe:
"Awọn bandiiti, ajinigbe, adigunjale, agbesunmọmi ati bẹẹ bẹẹ lọ n lo awọn nnkan wọnyi bii eemi ti wọn n mi simu.
" Ba a ṣe dana sun wọn yii n tọka si pe awọn to n ṣowo oogun oloro ti jẹ gbese owo to to biliọnu naira, a si tun dena iwa ọdaran."
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti Akọwe ijọba ipinlẹ Eko, Abilekọ Bimbola Salu-Hundeyin, ṣoju fun nibi eto naa, sọ pe iranti ni eyi jẹ, pe ewu gidi lo n bẹ ninu oogun oloro lilo.




























