Bí Olubadan ṣe rọ̀ mí lóyè lọ́wọ́ òṣèlú àti ọ̀tẹ̀ nínú - Aborisade

Niyi Aborisade wọ agbada ati fila, Olubadan Ọba Rashidi Ladoja naa wọ agbada olomi buluu pẹlu fila
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọkan lara awọn ti Mogaji ilẹ Ibadan ti Olubadan, Ọba Rashidi Ladoja rọ loye, Amofin Niyi Aborisade ti sọ fun BBC News Yoruba pe ọtẹ ati ọrọ oṣelu wa ninu bi wọn ṣe rọ oun loye.

‎Aborisade ni Olubadan Ọba Lekan Balogun lo fi oun joye, ọ ni lootọ ni oun ṣe ipadepọ pẹlu igbimọ Ijokoo ti Olubadan ṣaaju ki wọn to rọ oun loye .

‎Aborishade ni ọdun 2022 ni Ọba Lekan Balogun fi oun joye, lẹyin ti awọn idile oun ti fa oun kalẹ gẹgẹ bi Mogaji wọn.

O ni nigba ti awuyewuye bẹ silẹ ninu ile awọn,oun ṣalaye fun Olubadan ti ilẹ Ibadan ti Olubadan si ni ohun ti Ọba ba ti fi ontẹ lu ti di aṣẹ, nitori tọba lasẹ.

‎O ni "ọte oṣelu ni wọn ba de ibẹ, ẹ o ri pe orukọ Aborisade nikan ni wọn ní paa,ko wa si ibi ti wọn ti gbe gbogbo ọrọ yii nitori mo wa ninu awọn Oludije ti mọ jẹ igba keji eleniya labẹ asia ADC.

‎"Wọn ṣa sọ pe mo gba Ilẹ onilẹ, ko si nnkan itiju níbẹ, ti irọ ba lọ logun ọdun ọjọ kan ni otootọ yoo ba a".

‎O fikun ọrọ rẹ pe wọn o kọ lẹta si oun ki wọn to rọ loyẹ, ori ayelujara ni oun ti mọ wi pe wọn rọ oun loye.

‎Aborisade ni pẹlu igbesẹ ti aafin Olubadan ti ilẹ Ibadan gbe ,ọ da oun loju wi pe laipẹ yii ootọ ọrọ yoo foju han

Olubadan rọ Mọ́gàjí mọ́kànlá lóyè n'Ibadan, ó ní kùdìẹ̀-kudiẹ wà nínú ìyànsípò wọn

Olubadan ilẹ Ibadan, Oba Rashidi Ladoja, ti rọ awọn mọgaji mọkanla loye, titi kan Amofin Niyi Ajani Aborisade to jẹ Mogaji ile Ajagba, Oke-Offa, lagbegbe Babasale, Ibadan.

Igbimọ Oludamọran fun Olubadan lo sọ eyi di mimọ ninu lẹta kan ti wọn fi ṣọwọ si Aarẹ ẹgbẹ awọn Mogaji ilẹ Ibadan, ti Akọwe wọn, Balogun A.K, buwọlu.

Ki ni lẹta naa wi?

Gẹgẹ bi lẹta naa ṣe wi, Mọgaji mọkanla ni rirọloye naa kan.

Bi won ṣe yọ wọn nipo naa si waye lẹyin iwadii ti wọn lo fi han pe kudiẹ-kudiẹ wa ninu bi wọn ṣe fi wọn jẹ mọgaji.

Igbimọ naa sọ pe bi awọn mọgaji naa ṣe depo n'Ibadan ko tọna.

Wọn fi kun un pe awon panupọ lati gba iwadii yii wọle lẹyin ipade awọn igbimọ ẹka mi-in to waye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa ọdun 2026.

"Awọn ti ọrọ yii kan ko gbọdọ pe ara wọn ni mọgaji mọ"

Aṣẹ to tẹle ikede yii ni pe awọn mọgaji mọkanla ti ọrọ yii kan gbọdọ dẹkun ati maa pe ara wọn ni mọgaji.

Wọn ni ki wọn ko gbogbo ilẹkẹ ati ohun gbogbo to ba n tọka won bii oloye kalẹ.

Wọn ko gbọdọ pe ara wọn ni aṣoju ile ti wọn ti fi wọn jẹ mọgaji mọ lode eto iṣẹmbaye, bẹẹ ni wọn ko gbọdọ pe ara wọn ni mọgaji mọ nita gbangba.

Igbimọ naa fi kun ikilọ rẹ, pe ẹnikẹni to ba tapa sofin yii lara awọn mọgaji ti Olubadan rọ loye yoo foju wina ofin.

Amọ o, wọn ni ipo awọn meji ninu awọn mọgaji yii wa lọwọ idajọ kootu, lati sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ nipa iyọnipo wọn.

Awọn wo ni mọgaji ti wọn rọ loye naa?

Diẹ lara awọn eeyan naa ti iroyin fi orukọ wọn lede ni:

Amofin Niyi Ajani Aborisade

Ishola Ganiyu Olagoke

Ismaila Kunle Shodeinde

Funmilayo Adekunle Oluseyi

Muritala Suara Adeagbo

Yekini Musiliu Olaoye

Akinyemi Samuel Olusegun ati bẹẹ bẹẹ lọ