Tinubu buwọ́lu ₦250m fún ẹbí àwọn èèyàn tó kú sómi nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi ní Bayelsa

Aare Bola Tinubu
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lati jẹ ọna iranlọwọ ati ibanikẹdun, Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu owo ti iye rẹ to ẹgbẹrun lọna igba le laadọta naira (₦250 million), fun ẹbi awọn eeyan mọkandinlọgbọn (29) to padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ oju omi to danu nipinlẹ Bayelsa.

Ijamba naa waye nijọba ibilẹ Ijaw.

Igbakeji aarẹ Naijiria, Kashim Shettima, lo kede owo naa lasiko to ṣabẹwo si Bayelsa, lẹyin ti ọkọ oju omi ọhun danu logunjọ oṣu Kọkanla ọdun 2026, lagbegbe Oweikorogha, Bayelsa.

Ọfọ to kan gbogbo orilẹede wa ni iṣẹlẹ yii-Shettima

Nigba to n ṣapejuwe ijamba naa nile ijọba Bayelsa, Shettima sọ pe oun ṣabẹwo sibẹ pẹlu aṣẹ Aarẹ Tinubu, lati ba awọn eeyan tọrọ kan kẹdun, koun si tun wo bi nnkan ṣe n lọ.

O ṣapejuwe iṣẹlẹ ijamba naa bii ọfọ to kan gbogbo orilẹede Naijiria, pẹlu alaye pe o ṣe pataki lati ba awọn ẹbi to padanu eeyan wọn yii kẹdun.

Bakan naa lo ni Tinubu ti paṣẹ pe kawọn ẹka ijọba apapọ to ba yẹ lati ri si iṣẹlẹ yii, ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba Bayelsa lati pese iranwọ fun ẹbi awọn to di oloogbe.

Ijọba ti paṣẹ fun ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria (NEMA) lati pese awọn nnkan to le mu aye dẹrun fawọn ti ọrọ kan, ki ẹka to n ri si irinajo oju omi naa si pese aabo to yẹ fun awọn eeyan to n lo oju omi rin irinajo.

Ṣaaju ni Gomina ipinlẹ Bayelsa, Douye Diri, ti fidi ẹ mulẹ pe iye eeyan to ba ijamba naa lọ ti wọ mọkandinlọgbọn, ti eeyan to le ni mọkanlelaadọta (51) si moribọ.

O ni iṣẹ idoola ẹmi ṣi n lọ lọwọ, o si ṣee ṣe kawọn mi-in ṣi wa ninu ọkọ to danu naa.

Gomina Diri sọ pe ijamba to ṣee dena lo ṣẹlẹ yii, o ni ọkọ oju omi naa ko lagbara to lati fi ko ero, ibi to si ti ko ero paapaa lodi sofin bi Gomina Diri ṣe sọ.

O fi kun un pe ijọba ti ṣetan lati sanwo itọju ati owo ounjẹ awọn eeyan tori ko yọ ninu ijamba naa.

Ẹ o ranti pe ọkọ naa n ko awọn eeyan lati ilu Ayam lọ si Ukubie fun eto isinku kan ni ki o too danu.

Ọkọ̀ ojú omi tó ń kó àwọn èèyàn lọ ètò ìsìnkú dànù ní Bayelsa, ọmọdé méjì àtàwọn míì kú

Awọn to n doola awọn to danu ninu ọkọ oju omi

O kere tan, eeyan mẹrin lo jade laye – ti ọmọde meji wa ninu wọn – lẹyin ti ọkọ oju omi akero kan danu ni ijọba ibilẹ Ijaw, nipinlẹ Bayelsa.

Wọn ṣi n wa awọn kan ninu awọn ero ọkọ naa lasiko ti a n ko iroyin yii jọ amọ awọn adoola ti n wa awọn mii, ti awọn adoola ẹmi naa ṣi n ba iṣẹ lọ.

Ọkan ninu awọn ti ori ko yọ nibẹ sọ pe ọkọ oju omi naa ti wọn fi igi gbẹ ti ọpọ mọ si "love boat" ti wọn wa ninu rẹ ni ọpọ ero ati dukia wọn wa, ti ẹru naa si pọ ju fun ọkọ ọhun ko to danu.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, lasiko to n fidi iroyin naa mulẹ sọ pe ilu Ayama ni ọkọ naa ti n rinrinajo lọ si Ukubie fun eto isinku kan ko to danu loju ọna.

Ọlọpaa ni iwadii awọn fi han pe ṣe ni ọkọ ọhun ṣadede kọṣe lasiko to n ri lọ lori omi.

Awọn asiko ti ọkọ ti danu ni Naijiria ni 2026

Lọdun 2026 yii nikan ṣoṣo, ọpọ igba ni ọkọ oju omi ti danu to si gba ọpọ ẹmi, eyii to mu ki awọn onwoye maa kọminu lori aabo irinajo ori omi ni Naijiria.

Lọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2026, eeyan mẹrinlelogun lo ku ninu ijamba ọkọ to waye ni abule Adiyani to wa ni, Guri, nipinlẹ Jigawa.

Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, eeyan mẹrinla ku, ti wọn jẹ obinrin mẹtala ati ọmọde kan lẹyin ti ọkọ oju omi to ko eeyan to le ni ọgọrun danu nipinlẹ Kebbi lẹyin ayẹyẹ igbeyawo kan.

Nigba ti yoo di inu oṣu Kẹfa, eeyan mẹfa lo jade laye nigba ti wọn doola mẹẹdogun mii lẹyin ti ọkọ to ko ogoji eeyan danu ni Jigawa.

Ninu oṣu Kẹjọ, ọkọ mii tun danu ni Jigawa, nibi ti eeyan mẹrindinlaadọta ti ba omi lọ ti awọn mẹrindinlogun mii si di awati.