A ti kẹ́fín pé àwọn Janduku fẹ́ lo ìpinnu wa fi dá wàhálà sílẹ̀-NURTW Oyo

Oríṣun àwòrán, Others
NURTW ti wọ́gilé ìgbésẹ̀ láti padà sí ìbúdòkọ̀ gáréèjì káàkiri ìpínlẹ̀ Oyo
Oni ni gbedeke ọjọ ti awọn ẹgbẹ awakọ NURTW fun ijọba ipinlẹ Oyo lati tẹle igbesẹ ile ẹjọ to so wi pe ki ẹgbẹ naa pada si ẹnu iṣẹ nipinlẹ Oyo.
Lọsẹ to kọja ni Alaga ẹgbẹ naa, Alhaji Abideen Olajide tawọn eeyan mọ si Ejiogbe ati akọwe ẹgbẹ NURTW, Kọmureedi Lekan Alesinloye ni wọn jọ buwọlu atẹjade kan ti wọn si sẹlẹri lati gba awọn idikọ wọn pada nipinlẹ Oyo.
Wọn sọ wi pe ki ijọba ipinlẹ Oyo eleyi ti Gomina Seyi Makinde n dari bọwọ fun ofin tori o kọ lati tẹle idajọ ile ẹjọ Kotẹmilọrun eyi ti wọn lo da awọn lare.
Ṣugbọn bayii awọn ẹgbẹ awakọ NURTW, ninu atẹjade ti wọn filede ṣalaye wi pe awọn ti wogile igbesẹ awọn lati bẹẹrẹ iṣẹ jakejado gbogbo ibudokọ to wa nipinlẹ Oyo.
Alaga ẹgbẹ naa, Alhaji Abideen Olajide ni awọn yọgi lẹsẹ ohun ti awọn fẹ ṣe nitori wi pe awọn kẹfin pe awọn janduku fẹ lo igbesẹ ẹgbẹ awakọ NURTW lati da wahala silẹ nipinlẹ Oyo.
O tẹsiwaju wi pe ohun ti ẹgbẹ naa fẹ ni pe, ijọba ipinlẹ Oyo gbọdọ tẹlẹ ilana idajọ ile ẹjọ to gba ẹgbẹ naa laye lati ṣe iṣẹ wọn jakejado ipinlẹ Oyo.
O rọ awọn Olugbe ipinlẹ Oyo lati lọ si ibi isẹ wọn bo ṣe yẹ lai si ibẹru.
Ninu ibẹrubojo ni awọn Olugbe ilu Ibadan wa loni
Saaju ni Akoroyin ile iṣẹ BBC News Yoruba ti jade lataarọ lọ ba awọn olugbe ilu Ibadan sọrọ.
O ṣalaye wi pe niṣe ni ọkan gbogbo awọn to ni eeyan to fẹ wọ ilu Ibadan loni ọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹta ko aya soke
Wọn si n pe awọn eeyan wọn lati ma ṣe sọkalẹ ni awọn ibudokọ to wa niluu Ibadan.
Ọgbẹni Abayomi Gabriel, ọkan lara olugbe Ilu Ibadan ni, "Mo ni lati pe aburo mi to wa ni ilu Eko lati ma ṣe sọ ni ibudokọ to wa ni agbegbe opopona Iwo Road nitori oṣeeṣe ki wọn bẹẹrẹ ija níbẹ.
Awọn miran ti ibi isẹ wọn gba opopona Iwo Road kọja ni wọn gba ọna ibomiran,
Idi ni pe ki wọn ma baa ṣe kongẹ Ipalara aibamọ ti awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ NURTW ati awọn ti Park Mananagers system ba woya ija laarin ara wọn.
Nibo ni eto aabo gbe duro ni ipinlẹ Oyo?
Lọwọlọwọ bayii, ajọ ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, ikọ Operation Burst eyi to jẹ apapọ ọmọ ile iṣẹ ologun ati ti ajọ NSCDC ni wọn ti n rin jakejado gbogbo awọn agbegbe to ṣeeṣe ki idarudapọ ko wa nipinlẹ Oyo.
O-soju-mi-koro kan ṣalaye fun akoroyin ile iṣẹ BBC News Yoruba wi pe, awọn ibudoko gareeji to wa nilu Ibadan, iyen eyi to wa ni Ojọo, Challenge ati Iwo Road ni awọn oṣiṣẹ ajọ ọlọpaa ati Operation Burst wa.
O ni titi di asiko ti akoroyin BBC News Yoruba nkọ iroyin yii alaafia jọba ninu ilu Ibadan.
Ìjọba Oyo kìlọ̀ lórí gbèdéke ọjọ́ méje tí NURTW fún Makinde pé kó fòpin sí PMS káwọn lè gba gáréèjì

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Ijọba ipinlẹ Oyo ti fesi si gbedeke ọlọjọ meje ti ẹgbẹ awakọ NURTW ẹka ti ipinlẹ Oyo fun Gomina Seyi Makinde lati fopin si ajọ PMS to n ṣakoso ibudokọ nipinlẹ naa kawọn le gba gareeji pada.
Kọmiṣọna fun eto iroyin nipinlẹ Oyo, Ọmọba Dotun Oyelade, sọ fun BBC News Yoruba wi pe ijọba Makinde ṣetan lati tẹle ofin.
Ọmọba Oyelade ni ijọba ipinlẹ Oyo ko lodi si igbesẹ ti ẹgbẹ NURTW ba fẹ gbe, niwọn igba ti igbesẹ naa ba ti ba ofin mu.
Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ijọba ipinlẹ Oyo ko lodi sofin ri, ko si ni lodi sofin lasiko yii bakan naa.
Lori gbedeke ti NURTW fun Gomina Makinde lati ko ajọ PMS nilẹ kawọn le gba gareeji pada, Kọmiṣọna fun eto iroyin sọ pe ''ijọba maa kawọ gbera, a o si fọwọ lẹran ni.
Ki wọn lọ wadii rẹ wo bo ba jẹ pe NURTW le fọwọ lalẹ ki wọn si da gbedeke ọjọ fun ijọba.
To ba tọna bẹẹ, ofin lo maa yanju rẹ, ti ko ba si tọna naa, ofin lo maa ṣe atọna rẹ.
Ṣugbọn o ṣe pataki ki alaafia jọba ni ipinlẹ Oyo gẹgẹ bi a ṣe n ba a bọ.
Ijọba ipinlẹ Oyo yoo lodi si nnkan ti ẹnikẹni ba ṣe lati da ilu ru.''
Oti to gẹẹ! A ṣetan lati tẹle idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun - NURTW Oyo
End of podcast promotion
Ṣaaju ni ẹgbẹ onimọto NURTW ẹka ti ipinlẹ Oyo fun Gomina Seyi Makinde ni gbedeke ọjọ meje lati fopin si ajọ PMS to n ṣakoso gareeji nipinlẹ Oyo, kawọn le pada sawọn gareeji.
Ẹgbẹ naa fun ijọba di ọjọ kẹtalelogun oṣu Kọkanla lati ṣe bẹẹ.
Ẹgbẹ NURTW fidii ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ naa, Alhaji Abideen Olajide tawọn eeyan mọ si Ejiogbe ati akọwe, Kọmureedi Lekan Alesinloye jọ buwọlu.
Wọn sọ ninu atẹjade naa wi pe ijọba Makinde ko bọwọ fun ofin tori o kọ lati tẹle idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun eyi ti wọn lo dawọn lare.
Awọn oloye ẹgbẹ naa sọ pe lọpọ igba lawọn ti rawọ ẹbẹ si ijọba lati da NURTW pada tori ẹgbẹ ti idasilẹ rẹ wa ni ibamu pẹlu iwe ofin Naijiria ni, ṣugbọn eti ikun ni ijọba kọ si ẹbẹ awọn.
Ẹgbẹ NURTW ni ijọba si n tẹsiwaju lati maa ṣakoso ajọ PMS, bo tilẹ jẹ pe ileẹjọ ti dawọn lare lori ọrọ naa.
Ẹgbẹ NURTW sọ pe awọn ti sọ fun ijọba apapọ, ileeṣẹ ọmogun Naijiria, ajọ DSS, Kọmiṣọna ọlọpaa ati ẹgbẹ oṣiṣẹ pe awọn ṣetan lati tẹle idajọ ileẹjọ.
Awọn oloye NURTW sọ ninu atẹjade ti wọn fi sita wi pe ''a ṣetan lati tẹle idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun, o ti to gẹẹ bayii.
Ijọba Makinde ti fiya jẹ wa, ko si ọkankan ninu idajọ ti a gba lati ẹyin wa ti ijọba ipinlẹ Oyo tẹle.''
Ẹgbẹ naa ni ọna aitọ ni Makinde fi fofin de ẹgbẹ NURTW, wọn ni eyi si ti fa ebi ati iku ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto naa.
Alhaji Jelili Oyere nikan si loun mọ gẹgẹ bi olori ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Oyo - MC Oluomo
Ẹwẹ, aarẹ ẹgbẹ awakọ NURTW ni Naijiria, Alhaji Musiliu Ayinde Akinsanya (MC Oluomo), ti kilọ fun alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Oyo wi pe ko gbọdọ da wahala silẹ.
Alhaji Akinsanya ni oun ti gbiyanju lati kan si Ejiogbe ṣugbọn oun ko tii lanfaani lati ba a sọrọ.
Aarẹ ẹgbẹ NURTW sọ pe ijọba ti da Ejoigbe duro, ko si gbọdọ lo orukọ ẹgbẹ NURTW lati da omi alaafia ru nipinlẹ Oyo.
MC Oluomo sọ pe Alhaji Jelili Oyere nikan si loun mọ gẹgẹ bi olori ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Oyo.
Alhaji Akinsanya ni alaafia ni ẹgbẹ NURTW maa n le pa nibi gbogbo.



























