Ilé ẹjọ́ CAS kéde Senegal gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó gba ife ẹ̀yẹ AFCON 2025, Morocco mófo

Oríṣun àwòrán, SEBASTIEN BOZON / AFP via Getty Images
Ile ẹjọ to n gbẹjọ lori awuyewuye to ba jẹyọ ninu ere idaraya iyẹn Court of Arbitration for Sport (CAS) ti gbe ife ẹyẹ AFCON 2025 pada fun Senegal.
Ile ẹjọ CAS yi igbesẹ ajọ CAF danu eyi to fi gbe ife ẹyẹ naa fun Morocco lẹyin tawọn agbabọọlu Teranga Lions kọkọ binu jade lori papa lasiko ti ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba AFCON 2025 n lọ lọwọ niluu Rabat lorilẹede Morocco lonii ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kọkanla.
Gbogbo igbimọ oludajọ lo fẹnu ko wi pe Senegal lo gba ife ẹyẹ naa tori rẹfiri Jean-Jacques Ndala bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ ọhun pada lẹyin aawọ to ṣẹlẹ, ati pe wọn gba ere bọọlu ọhun tan.
Igbimọ oludajọ wa dajọ wi pe Senegal lo gba ife ẹyẹ naa laisi ani ani.
Ile ẹjọ sọ pe rẹfiri lagbara lati bẹrẹ ere bọọlu pada gẹgẹ bi o ti ṣe.
Igbimọ oludajọ tun sọ wi pe ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji lo wọle pada lati tẹsiwaju pẹlu ere bọọlu naa eyi ti Senegal ti jawe olubori.
Lẹsẹ kẹsẹ ni ajọ FSF to n ṣakoso ere bọọlu ni Senegal ti fi aworan ẹgbẹ agbabọọlu Senegal soju opo ayelujara rẹ nibi ti wọn ti gbe ife ẹyẹ AFCON lọwọ.
Ajọ to n ṣakoso ere bọọlu ni Morocco ko tii sọrọ lori idajọ ile ẹjọ CAS naa.
Lẹyin ti idije naa ti waye tan ni CAF kede wi pe Morocco lo gbafe ẹyẹ naa pẹlu goolu mẹta latari bi ẹgbẹ agbabọọlu Senegal ṣe binu jade lori papa.
Amọ, Senegal morile ile ẹjọ CAS nibi ti igbimọ oludajọ ti gbe ife ẹyẹ AFCON wọn fun wọn pada bayii.
Ami ayo kan ni Senegal fi ṣagba Morocco ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije AFCON 2025 naa.
Ki lo ti waye sẹyin?

Oríṣun àwòrán, AFP/VIA GETTY
End of podcast promotion
Igbẹjọ naa bẹrẹ nigba ti awuyewuye su yọ lori asekagba ifẹsẹwọnsẹ ere idaraya AFCON tọdun 2025 to waye ni papa isere idaraya Ọmọọba Moulay Abdellah nilu Rabat nilẹ Morroco lọjọ kẹjidinlogun osu kinni ọdun 2026.
Orilẹede Senegal si lo kọkọ fi ẹyin ilẹ Morocco to n gbalejo idije naa janlẹ pẹlu ami ayo kan si odo lasiko afikun akoko ere bọọlu naa.
Amọ wahala bẹrẹ lasiko ti adari ere bọọlu naa fun ikọ agbabọọlu Morocco ni anfaani lati gba pẹnariti tori agbeyẹwo aworan ohun to waye lori papa lẹyin to fagile ami ayo kan ti ikọ agbabọọlu Senegal gba wọle.
Eyi lo mu ki olukọni lere bọọlu fun ilẹ Senegal, Pape Thiawfa ibinu yọ, to si pasẹ fawọn agbabọọlu rẹ lati kuro lori papa ti wọn ti n gba asekagba idije AFCON 2025 naalọna ati fi ibinu wọn han si ihuwasi adari ayo ọhun.
Eyi si lo mu kawn agbabọọlu ilẹ Senegal fi papa ere bọọlu naa silẹ fun isẹju mẹrinla, ki wọn to wa pada sori papa lati tẹsiwaju ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Amọ se ni Brahim Diaz tii se agbabọọlu fun ilẹ Morocco padanu pẹnarity naa, ti orilẹede Senegal si jawe olubori nibi idije naa lati ipasẹ afikun akoko eyi to mu fun Pape Gueye laaye.
Igbimọ to n fiyajẹni labẹ ajọ CAF kede ijiya to yẹ fun ikọ agbabọọlu Senegal ati Morocco
Amọ ajọ to n se kokari ere bọọlu nilẹ Morocco gbe ẹsun lọ siwaju ajọ elere bọọlu nilẹ Afirika ati ni agbaye, CAF ati FIFA, to si n fapa janu pe bi ikọ agbabọọlu Senegal se kuro lori papa ti wọn ti n gba bọọlu naa lo dabaru bi ifẹsẹwọnsẹ naa se yẹ ko lọ.
Igbimọ to n diyajẹni labẹ ajọ CAF kọkọ gba pe ki abajade asekagba idije AFCON naa w abo se wa, to si kede ijiya to yẹ fun ikọ agbabọọlu Senegal ati Morocco lori awọn isẹlẹ to waye lasiko ifẹsẹwọnsẹ naa to jẹ asekagba idije ọhun.
Amọ inu ilẹ Morocco ko dun rara si igbesẹ naa, eyi si lo mu ko kọwe ẹsun nipa isẹlẹ ọhun.
Lọjọ Kẹtadinlogun osu kẹta, igbimọ to n gbọ ẹjọ kotẹmilọrun labẹ ajọ CAF, fara mọ awọn ẹsun tilẹ Morocco mẹnuba, to si yi idajọ ti igbimọ adiyajẹni kọkọ gbe kalẹ.
O wa kede pe ikọ agbabọọlu Senegal ti padanu lati tẹsiwaju ninu kikopa nibi ifẹsẹwọnsẹ asekagba idije naa tori bo se tapa si ofin to de ere bọọlu AFCON ori kejilelọgọrin ati ikẹrinlelọgọrin.
Ibujoko ajọ CAF nilu Lausanne, nilẹ Switzerland, ni wọn ti gbọ ẹjọ naa lọjọ kẹjọ osu kẹwa ọdun 2026
Idi si ree ti igbimọ to n gbọ ẹjọ kotẹmilọrun naa se fun ikọ agbabọọlu Senegal ni ami ayo mẹta, to si fun Senegal ni odo eyi to mu ki ilẹ Morocco jẹ ikọ agbabọọlu to gba ife ẹyẹ AFCON 2025 naa.
Ikede yii lo bi ariwisi lorisirisi jakejado ilẹ Afirika, tilẹ Senegal si se apejuwe idajọ naa bii eyi to fi sibikan, to si ki oun ko fara mọ idajọ naa rara.
Lẹyin naa ni Senegal wa kede pe oun yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun niwaju ajọ CAF lori idajọ naa.
Ọjọ Kẹẹdọgbọn osu kẹta si ni Senegal gbe ẹsun rẹ siwaju ajọ CAF, to si n fẹ ko yi idajọ ti igbimọ to n gbọ ẹjọ kotẹmilọrun gbe kalẹ naa, ko si kede pe oun lo lo moke ninu ididje AFCON naa pẹlu ami ayo kan si odo.
Ibujoko ajọ CAF nilu Lausanne, nilẹ Switzerland, ni wọn ti gbọ ẹjọ naa lọjọ kẹjọ osu kẹwa nibi tawọn asoju lati inu ajọ CAF pẹlu ilẹ Senegal ati Morocco peju si, ti wọn s iwi awijare wọn nibi ipade bonkẹlẹ naa.
Bi o tilẹ jẹ pe ajọ to n gbọ ẹhonu ninu ajọ CAF ni wọn yoo gbe idajọ kalẹ lẹyin ọjọ diẹ amọ o kede nigba to ya pe oun yoo gbe ipinnu kalẹ losu kọkanla ọdun yii.
Idajọ ti yoo waye loni naa si ni yoo sọ boya idajọ ti igbimọ to n gbọ ẹjọ kotẹmilọrun labẹ ajọ CAF gbe kalẹ, eyi to n kede Morocco bii ẹni to jawe olubori tọna abi bẹẹ kọ.
Idajọ naa si ni yoo fopin si awuyewuye to tii buru julọ ti yoo waye ri ninu itan ife ẹyẹ Afirika.



























