Yoruba Movie: Wumi Toriọla ṣàlàyé òun tó mú tírélà gbà àárín òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀

Láti bi ọjọ́ mẹ́ta sẹyìn lọ̀rọ̀ ti n ṣe bi eré, bi ìjà láàrín àwọn òṣèré tíàtà Nollywood Yorùbá ti kò si yé ọ̀pọ̀ èèyàn ǹkan tó bẹ̀rẹ̀ ṣẹlẹ̀ ni pàtó.
Ṣùgbọ́n lópin ssẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kógbá wọlé yìí ni ìná jó dórí kókó, nígbà ti ọ̀kan nínú wọn Wumi Toriola bọ́ si ojú pópó ìkíraẹni Instagram láti sọ̀kò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ si ẹni to n bá jà.
Ọ̀pọ̀ àwọn olólufẹ àwọn òṣèré méjèèjì yìí ló tí n fúnra láti àsìkò díẹ̀ sẹyin ṣùgbọ́n ti wọn kò le fi idí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ ni pàtó pé ìjà wà láàrín wọn.
- Wo ojú àwọn òṣèré yìí láì lo "Make-up" orí ìtàgé bó ṣe rí gẹ́lẹ́
- Àwọn olóṣèlú Nàìjíríà márùn ùn tó sọ̀rọ̀ tí ará ìlú fà ìbínú yọ
- Agúnbẹ kan gún èèyàn mẹ́ta pa ní ilé ìjọsìn Notre Dame basilica
- Ọmọ ọdún mọ́kànlá tó bá wọn fọ́ àgọ́ ọlọ́pàá, wọ gàù ọlọ́pàá ní Edo
- Báyìí ni 50 Kobo ṣe dá ìfẹ̀hónú "Ali Must go" sílẹ̀ tó mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí akẹ́kọ̀ọ́ lọ
Gbogbo ènìyàn lo mọ pé ọ̀rẹ́ kìí y'ọ̀rẹ́ ni Wumi Toriola àti Seyi Edun to jẹ́ ìyàwó Adeniyi Johnson ṣùgbọ́n lásìkò ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Seyi Edun, Awọn kan ni Wumi Toriola kọ lati ki Seyi ku ayẹyẹ ọjọ ìbí àti ìgbà yìí si ni wọn ti n bèrè ǹkan to fa èdè àìyedè láàrin wọn.

Oríṣun àwòrán, I_am-shai/Instagram
Bákan náà ni Seyi ko ki Wumi Toriola lọ́jọ́ ibi rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi wọ́n ṣe máa n ṣe lojú òpó ìkàsíraẹni Instagram.

Oríṣun àwòrán, Wumi Toriola/Twitter

Oríṣun àwòrán, Wumi Toriola/Instagram
Ṣùgbọ́n lówúrọ̀ ọjọ́ Ẹti ni Wumi Toriola tún bọ́ sọjú òpó instagram rẹ̀ láti sọ pé,
"Bí èèyàn bá ṣe aburú fún ọ, má rẹ́rin ti kò dénú pẹ̀lú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bi o bá gáání wọ́n. Jẹ́ kí ó mọ̀ ibi ti ó dúro si, ko si àpọ́nle kankan nínú ìgbé ayé àgàbàgebè"
Lẹ́yìn náà lo fi ọ̀rọ̀ míràn gba lẹ́yìn pé gbogbo ǹkan ni òun le gbà sùgbọ́n ti ọ̀rọ̀ bá ti kan ti ọmọ òun pàápàá jùlọ to ba ti di ọ̀rọ̀ ìjà òun ko le fara dàá, "Bí ẹ ba ri ẹnikẹ́nì tí ó ní ìkóròrí sí ọmọdé, apànìyàn ni irú ẹni bẹ́ẹ̀, wọ́n le fún ènìyàn ni iwọ jẹ"

Oríṣun àwòrán, Wumi Toriola/Instagram
Bótilẹ̀ jẹ́ pé, bí àwọn kan ṣe n yín Wumi Toriola bí o ṣe sọ́rọ́ síta, bẹ́ẹ̀ ni àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ míràn sọ fún pé, kò bá ojúmu tó láti má a pé ọmọlakeji rẹ̀ ni àgàn.

Oríṣun àwòrán, Wumi Toriola
Ẹ̀wẹ̀, Seyi Edun nítirẹ sọ lójú òpó tirẹ̀ pé, nínú ohun gbogbo kí a ṣáà maa dúpẹ́ ni, nítrori idí èyí ni ọ̀ps àwọn olúlufẹ́ tirẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni ni pẹ̀tu síi lọ́kàn láti kí eti ikún si ohun gbogbo ti Wumi Toriola ń ṣọ

Oríṣun àwòrán, i-am-shai/Instagram
Báyìí ni ọ̀rọ̀ ìyànjú tí àwọn olúlùfẹ́ Seyi náà ṣe lọ

Títí di àsìkò yìí, àwọn ọ̀rẹ́ méjì yiìí kò tí sàlàyé ǹkan to fa ìdí ìjà wọn













