Ahmadu Ali Must Go Protest: Àfikún owó oúnjẹ akẹ́kọ̀ọ́ ní Fáṣítì fa ẹ̀hónú tó mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lọ

Oríṣun àwòrán, Archive
Yoruba ni arise ni arika, arika si ni baba iregun, ohun ta ba ṣe lonii, yoo di itan bo di ọla.
Kii ṣe iwọde EndSARS nigba akọkọ tawọn ọdọ Naijiria yoo kọju oro si ijọba nitori idi kan tabi omiran, eyi ti yoo si mu ẹmi lọ, o ti waye saaju.
Okan lara awọn iṣẹlẹ ifẹhonuhan ọdọ to waye tipẹ tipẹ, to si jẹ Manigbagbe, ta maa ranti laelae ni ẹhonu awọn akẹkọọ to waye ni odun mejilelogoji sẹyin ti wọn pe ni 'Ali Must Go'.
Ni bayii ti ọwọja eruku rogbodiyan to gbode nitori iwọde ENDSARS ko tii lọ silẹ, o yẹ ka ran ara wa leti nigba iwọde alagbara naa ati bi ologun ṣe kọlu awọn akẹkọọ.
- Ẹ gbọ́ Ohun tí Desmond Elliot àti Mojisola Alli-Macaulay sọ lórí ayélujára táwọn ọmọ Nàìjíríà fi ìbínú
- Ìrànwọ́ ikú fàwọn tó bá wà lórí àkéte àìsan tó leè já sí ikú ti di òfin tuntun tí wọ́n fẹ́ fọwọ́ sí!
- Ẹ má gbìyànjú láti bo àṣírí ìpànìyàn tó wáyé ní Lekki, á ní ẹ̀rí tó dájú - Amnesty International
- Wo ojú àwọn òṣèré yìí láì lo "Make-up" orí ìtàgé bó ṣe rí gẹ́lẹ́

Oríṣun àwòrán, Archive
Ki lo fa ifẹhonuhan akẹkọọ Ali Must Go?
Ni bí ogoji ọdun sẹyin, awọn alakoso ọgba ile ẹkọ fasiti kọọkan lo maa n pese oúnjẹ fáwọn akẹkọọ wọn pẹlu owo perete, tijọba yoo si fi owo kun.
Awọn oúnjẹ to sara loore ni wọn maa n fáwọn akẹkọọ yii jẹ, ninu eyi ti odidi abi idaji ẹran adìẹ wa.
Akẹkọọ to ba si san owo oúnjẹ yii fun saa eto ẹkọ kan, tii ṣe naira kan ati aadọta kọbọ (N1.50k), ni wọn yoo fun ni paali tikẹẹti lati maa mu lọ fi jẹun ni buka oúnjẹ ile ẹkọ wọn.
Nigba to di oṣù kẹrin ọdun 1978, ni Minisita feto ẹkọ nigba naa, Ahmadu Ali, to ṣiṣẹ laye ijọba ologun Olusegun Obasanjo, kede afikun owo oúnjẹ ti akẹkọọ kọọkan yoo maa san.
Ali kede pe ijọba ologun igba naa ti mu ele ba owo oúnjẹ akẹkọọ lati naira kan ati aadọta kọbọ (N1.50k) si naira meji (N2:00k), ti afikun aadọta kọbọ (50k) si gun owo oúnjẹ naa.
Nigba ta n sọrọ rẹ yii, owo ribiribi ni aadọta kọbọ, koda, owo osu oṣiṣẹ ọba mii ko to aadọta kọbọ nigba naa.
"Ere ni, awada ni, ko jẹ ri bẹẹ, a ko ni gba, ẹ daa pada" ni ọpọ idahun táwọn akẹkọọ fi n fesi si ikede ele owo oúnjẹ naa.
Olori ẹgbẹ akẹkọọ nigba naa, Segun Okeowo, (to ti di oloogbe bayii lẹni aadorin ọdun) pe oniruuru ipade awọn akẹkọọ yika Naijiria lori ọrọ yii, ti wọn si fi ipinnu wọn ransẹ sijọba.
Bi ifẹhonuhan Ali Must Go ṣe waye ree:
Awọn akẹkọọ naa, to ṣe ipade nilu Maiduguri, Ilorin ati Calabar gbọnmu lori ele owo oúnjẹ naa, ti wọn si sọ fun ijọba lati yi ipinnu rẹ pada.
Amọ nigba ti ijọba ko da awọn akẹkọọ naa lohun, ni wọn ba gun le iwọde alagbara eyi to waye nile ẹkọ fasiti kọọkan yika Naijiria.
Ilu gbona, awọn akẹkọọ ti awọn opopona pa, rogbodiyan gbode, ijọba yari, ko yi ipinnu rẹ pada, awọn akẹkọọ naa si gbọnmu pe awọn ko ni gba.
Asiko iwọde yii si ni awọn akẹkọọ naa n polongo pe ki Minisita feto ẹkọ, Ahmadu Ali kuro nipo naa, eyi ti wọn fi ede oyinbo beere pe "Ali Must Go".

Oríṣun àwòrán, Archive
Bi ọlọpaa ati ologun ṣe kọlu awọn akẹkọọ lasiko iwọde:
Ọjọ akọkọ ti iwọde naa bẹrẹ, ni awọn ọlọpaa ti kọlu awọn akẹkọọ naa, ti wọn si ta ọkan ninu wọn ni ìbọn ni ẹsẹ.
Ọgba fasiti Eko, University of Lagos, Unilag si ni iṣẹlẹ naa ti waye, bẹẹ ni awọn ile iwosan ijọba kọ lati tọju oju ọgbẹ naa, eyi to mu ki ẹjẹ da lara akẹkọọ ọhun, titi to fi gbe ẹmi mi.
Iṣẹlẹ ẹmi akẹkọọ to bọ naa, mu káwọn akẹẹgbẹ rẹ tutọ soke, fi oju gbaa, ti wọn si ransẹ síra wọn yika awọn fasiti ilẹ wa pe rogbodiyan ya.
Iku akẹẹgbẹ wọn naa bu epo bẹtiroolu si iṣẹlẹ yii, odidi ọsẹ kan gbako si lawọn akẹkọọ yii fi n wọ sokoto kan naa pẹlu awọn ọlọpaa ati ologun.
Ariwo Ali Must Go lo gba ilẹ kan, ti ilu ko si fararọ rara lasiko ifẹhonuhan awọn akẹkọọ naa.
Nigba ti ọsẹ kan yoo fi pari, awọn ologun tun ti ran akẹkọọ mẹjọ miran sọrun ọsan gangan nilu Zaria, ti bilisi si so.
Kia ni ijọba ologun Obasanjo kede pe oun ti gbe ilẹkun awọn ile ẹkọ fasiti gbogbo nilẹ wa tipa, to si paṣẹ fáwọn akẹkọọ lati gba ile obi wọn lọ.
Iṣẹlẹ Ali Must Go yii si lo tan jakejado agbaye, a si le e ri bii ibẹrẹ ifẹhonuhan abi ijijagbara awọn ọdọ lorile-ede Naijiria.














